Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Wọ́n Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Ọmọ Mi?

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Wọ́n Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Ọmọ Mi?

 Tí ọmọ ẹ bá sọ fún ẹ pé wọ́n ń halẹ̀ mọ́ òun níléèwé, kí lo lè ṣe? Ṣé wàá sọ fún ọ̀gá iléèwé pé kí wọ́n fìyà jẹ onítọ̀hún ni? Àbí wàá kọ́ ọmọ ẹ bó ṣe máa ṣe tiẹ̀ pa dà? Kó o tó pinnu ohun tó o máa ṣe, ó yẹ kó o mo àwọn ohun tó jẹ mọ́ híhalẹ̀ mọ́ni. a

 Kí ló yẹ kí n mọ̀ nípa híhalẹ̀ mọ́ni?

 Kí ló túmọ̀ sí tí wọ́n bá ń halẹ̀ mọ́ ẹnì kan? Tí wọ́n bá ń halẹ̀ mọ́ ẹnì kan, ṣe làwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ mọ̀ọ́mọ̀ fìyà jẹ onítọ̀hún láìjáwọ́, ó lè jẹ́ lójúkojú tàbí nínú ìwà. Torí ẹ̀ ló ṣe jẹ́ pé, ti pé wọ́n tàbùkù ẹnì kan tàbí pé wọ́n hùwà ìkà sí i kò túmọ̀ sí pé wọ́n ń halẹ̀ mọ́ ọn.

 Ìdí tọ́rọ̀ yìí fi ṣe pàtàkì: Ohun táwọn kan gbà ni pé tí wọ́n bá hùwà èyíkéyìí tó bí èèyàn nínú, bó ti wù kó kéré tó, ṣe ni wọ́n ń halẹ̀ mọ́ onítọ̀hún. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé gbogbo ọ̀rọ̀ kéékèèké tó bá ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ẹ lo máa ń sọ di bàbàrà, o ò ní jẹ́ kí ọmọ ẹ mọ bí wọ́n ṣe ń yanjú ìṣòro, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ohun tó gbọ́dọ̀ kọ́ bó ṣe ń dàgbà sí i ni.

 Ìlànà Bíbélì: “Má ṣe máa yára bínú.”​—Oníwàásù 7:9.

 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Ìgbà míì wà lóòótọ́ tó yẹ kó o bá ọmọ ẹ dá sí àwọn ọ̀rọ̀ kan, àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ míì wà tó jẹ́ pé tó bá kojú ẹ̀ fúnra ẹ̀, á lè kọ́ béèyàn ṣe ń yanjú ìṣòro àti béèyàn ṣe ń bá àwọn ẹlòmíì lò.​—Kólósè 3:13.

 Àmọ́ kí lo lè ṣe tí ọmọ ẹ bá sọ fún ẹ pé àwọn kan ò yéé mọ̀ọ́mọ̀ máa yọ òun lẹ́nu?

 Ìrànlọ́wọ́ wo ni mo lè ṣe?

  •   Fara balẹ̀ tẹ́tí sí ọmọ rẹ. Gbìyànjú láti mọ (1) ohun tó ń ṣẹlẹ̀ àti (2) ìdí tí wọ́n fi dájú sọ ọ́. Kọ́kọ́ rí i pé o rí àrídájú ọ̀rọ̀ kó o tó parí èrò síbì kan. Bi ara ẹ pé, ‘Àbí nǹkan míì wà tí mi ò tíì mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí?’ Kó o lè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an, ó lè gba pé kó o lọ rí olùkọ́ ọmọ ẹ tàbí òbí ọmọ tó ń halẹ̀ mọ́ ọmọ ẹ.

     Ìlànà Bíbélì: “Tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀rọ̀ láì tíì gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀, ìwà òmùgọ̀ ni, ó sì ń kó ìtìjú báni.”​—Òwe 18:13.

  •   Tí ẹnì kan bá ń halẹ̀ mọ́ ọmọ ẹ, jẹ́ kó mọ̀ pé ohun tó bá ṣe tàbí tó sọ sí onítọ̀hún lè mú kí nǹkan sàn tàbí kó burú sí i. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀, àmọ́ ọ̀rọ̀ líle ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Ká sòótọ́, tí ọmọ ẹ bá ṣe tiẹ̀ pa dà, ó lè mú kí nǹkan burú sí i, kí wọ́n wá túbọ̀ fúngun mọ́ ọn dípò kí wọ́n jáwọ́.

     Ìlànà Bíbélì: “Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, ẹ má sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù san ọ̀rọ̀ àbùkù.”​—1 Pétérù 3:9.

  •   Jẹ́ kí ọmọ ẹ mọ̀ pé tí kò bá ṣe tiẹ̀ pa dà, kò sọ ọ́ di ojo. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń fi hàn pé akin lòun, torí kò jẹ́ kí ohun tí ẹni náà ń ṣe nípa lórí òun, bíi pé onítọ̀hún ló ń darí rẹ̀. Bí kò ṣe ṣe tiẹ̀ pa dà yẹn, ṣe ló ń kápá onítọ̀hún, kò sì jẹ́ kó sọ òun da bó ṣe dà.

     Ó ṣe pàtàkì gan-an kí ọmọ ẹ fi kókó yìí sọ́kàn tó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n ń halẹ̀ mọ́ ọn lórí íńtánẹ́ẹ̀tì. Tóun náà bá lọ ń fọ̀rọ̀ burúkú ránṣẹ́ sí wọn pa dà, àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ ọn ò ní jáwọ́, kódà àwọn míì lè wá fẹ̀sùn kan ọmọ ẹ pé ó ń halẹ̀ mọ́ àwọn míì! Torí ẹ̀ ló ṣe jẹ́ pé, nígbà míì, ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn má sọ nǹkan kan, èyí lè mú kí ẹni tó ń halẹ̀ mọ́ ọmọ ẹ jáwọ́, tó bá sì rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ọmọ ẹ ti kápá ẹ̀ nìyẹn.

     Ìlànà Bíbélì: “Níbi tí kò bá sí igi, iná á kú.”​—Òwe 26:20.

  •   Láwọn ìgbà míì, ọmọ ẹ lè yẹra fún àwọn tó ṣeé ṣe kó halẹ̀ mọ́ ọn àtàwọn ibi tí wọ́n ti lè ṣe é. Bí àpẹẹrẹ, tó bá mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan tàbí àwọn kan wà níbì kan pàtó, ó lè gba ibòmíì kó má bàa sí wàhálà.

     Ìlànà Bíbélì: “Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pa mọ́, àmọ́ aláìmọ̀kan kọrí síbẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.”​—Òwe 22:3.

Ó lè gba pé kó o lọ rí olùkọ́ ọmọ ẹ tàbí òbí ọmọ tó ń halẹ̀ mọ́ ọmọ ẹ

 GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Jẹ́ kí ọmọ ẹ ro ohun tó fẹ́ ṣe dáadáa, kó rò ó síwá àti sẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ:

  •  Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tí ò bá dá ẹni tó ń halẹ̀ mọ́ ọn lóhùn?

  •  Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá fìgboyà sọ fún onítọ̀hún pé ó tó?

  •  Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá lọ fi ẹjọ́ onítọ̀hún sun ọ̀gá iléèwé?

  •  Ṣé ó lè fi àwàdà paná wàhálà tí ẹni yẹn ń bá a fà?

 Ohun kan ni pé, ipò kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra, ì báà jẹ́ ojúkojú ni wọ́n ń halẹ̀ mọ́ ọmọ ẹ àbí lórí íńtánẹ́ẹ̀tì. Torí náà, kí ìwọ àti ọmọ ẹ jọ forí korí, kẹ́ ẹ lè mọ ohun tó dáa jù tó lè ṣe. Jẹ́ kó mọ̀ pé gbágbáágbá lo wà lẹ́yìn ẹ̀ tẹ́ ẹ fi máa rẹ́yìn ọ̀rọ̀ náà.

 Ìlànà Bíbélì: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”​—Òwe 17:17.

a Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àwọn ọmọkùnrin la máa fi ṣe àlàyé nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn ìlànà tá a máa jíròrò wúlò fún àwọn ọmọbìnrin náà.