Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÈ | ỌMỌ TÍTỌ́

Àwọn Ọmọdé àti Ìkànnì Àjọlò—Apá 2: Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò

Àwọn Ọmọdé àti Ìkànnì Àjọlò—Apá 2: Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò

 Àwọn òbí kan kì í gbà káwọn ọmọ wọn lo ìkànnì àjọlò torí ewu tó wà níbẹ̀. Àmọ́, tó o bá gbà kí àwọn ọmọ rẹ máa lo ìkànnì àjọlò, báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè yẹra fún àwọn ewu tó wà níbẹ̀, kí wọ́n sì mọ bí wọ́n ṣe lè fọgbọ́n lò ó?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa

 Ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí ọmọ rẹ

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀: Torí pé ó rọrùn láti lo ọ̀pọ̀ àkókò nídìí ìkànnì àjọlò kéèyàn tó mọ̀, ó yẹ kó o ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè mọ iye àkókò tó yẹ kó lò nídìí rẹ̀.

 Ìlànà Bíbélì: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.

 Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé ọmọ rẹ kì í lo ìkànnì àjọlò lásìkò tó yẹ kó máa sùn, tó yẹ kó máa ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá tàbí tó yẹ kí ìdílé yín jọ wà pa pọ̀? Ìwádìí fi hàn pé ó yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ máa sun oorun wákàtí mẹ́sàn-án lálẹ́, àmọ́ ó ṣeé ṣe káwọn tó ń lo ọ̀pọ̀ àkókò nídìí ìkànnì àjọlò má sùn tó wákàtí méje.

 Ohun tó o lè ṣe: Bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀, kó o jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn ohun kan wà tó ṣe pàtàkì. Yàtọ̀ síyẹn, á dáa kó o sọ ìdí tó fi yẹ kó dín iye àkókò tó ń lò nídìí ìkànnì àjọlò kù. O lè fọgbọ́n ṣe àwọn òfin kan, bíi kó o sọ pé ọmọ rẹ kò gbọ́dọ̀ mú fóònù wọ yàrá tó bá fẹ́ lọ sùn lálẹ́. Ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì sí ẹ ni bí o ṣe máa ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè ní ìkóra-ẹni-níjàánu, torí ànímọ́ yìí máa ràn án lọ́wọ́ bó ṣe ń dàgbà.—1 Kọ́ríńtì 9:25.

 Àkóbá tó lè ṣe fún ọmọ rẹ

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀: Táwọn ọ̀dọ́ bá ń wo fọ́tò táwọn ọ̀rẹ́ wọn ti fi kọ̀ǹpútà dọ́gbọ́n sí tàbí fọ́tò ibi táwọn míì tí lọ gbádùn ara wọn, ó lè máa ṣe wọ́n bíi pe wọ́n dá wà, kí ìrònú bá wọn tàbí kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì.

 Ìlànà Bíbélì: “Jáwọ́ nínú . . . owú.”—1 Pétérù 2:1.

 Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé ìkànnì àjọlò ti ń jẹ́ kí ọmọ rẹ máa fi ara ẹ̀ wé àwọn míì, bóyá kó máa ronú pé ìrísí àwọn kan dáa ju tòun lọ? Ṣé ọmọ rẹ ń ronú pé àwọn míì ń jayé orí wọn bí wọ́n ṣe fẹ́ àmọ́ tí tóun ò rí bẹ́ẹ̀?

 Ohun tó o lè ṣe: Bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ewu tó wà nínú kó máa fi ara rẹ̀ we àwọn míì. Àmọ́ fi sọ́kàn pé ọ̀rọ̀ yìí kan àwọn ọmọbìnrin ju ọmọkùnrin lọ, torí pé ọ̀rọ̀ ìfẹ́sọ́nà àti ìrísí máa ń gba àwọn ọmọbìnrin lọ́kàn gan-an. O tún lè dábàá fún ọmọ rẹ pé kó ní àwọn ìgbà kan tí kò ní máa lo ìkànnì àjọlò. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jacob sọ pé: “Mo yọ ètò ìṣiṣẹ́ ìkànnì àjọlò kúrò lórí fóònù mi fáwọn àkókò kan. Ìyẹn sì jẹ́ kí ń lè ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì, kí ń sì máa fojú tó tọ́ wo ara mi àtàwọn míì.”

 Ohun táá máa ṣe lórí ìkànnì àjọlò

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀: Téèyàn bá wà lórí ìkànnì àjọlò, ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń gbé láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn. Kò sí bí èdèkòyédè àti ìjà kò ṣe ní máa wáyé.

 Ìlànà Bíbélì: “Ẹ mú gbogbo inú burúkú, ìbínú, ìrunú, ariwo àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín . . . Ẹ jẹ́ onínúure sí ara yín.”—Éfésù 4:31, 32.

 Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé ìkànnì àjọlò ti jẹ́ kí ọmọ mi máa ṣòfófó, kó máa jà tàbí kó máa sọ̀rọ̀ tí ò dáa?

 Ohun tó o lè ṣe: Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ àwọn ìlànà táá jẹ́ kó lè máa hùwà tó bójú mu lórí ìkànnì. Ìwé Digital Kids sọ pé: “Ojúṣe àwọn òbí ni láti kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kò dáa kí wọ́n máa hùwà ìkà bóyá lórí ìkànnì tàbí lójú kojú.”

 Fi sọ́kàn pé kò pọndandan kéèyàn ní ìkànnì àjọlò àti pé kì í ṣe gbogbo òbí ló ń jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn lò ó. Kó o tó gbà kí ọmọ ẹ lo ìkànnì àjọlò, rí i dájú pé ó ti lè pinnu iye àkókò tó máa lò níbẹ̀, ó lè yan ọ̀rẹ́ gidi, kó má sì wo ìwòkuwò.