Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Ò Ní Ba Ayé Yìí Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe?

Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Ò Ní Ba Ayé Yìí Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe?

“Ìran kan ń lọ, ìran kan sì ń bọ̀; ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé dúró àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—SÓLÓMỌ́NÌ ỌBA, ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KỌKÀNLÁ ṢÁÁJÚ SÀNMÁNÌ KRISTẸNI. *

Ẹni tó sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí mọ̀ pé ọjọ́ orí àwa èèyàn kéré gan-an tá a bá fi wéra pẹ̀lú ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún tí ayé yìí ti wà. Tá a bá sì wò ó lóòótọ́, a máa rí i pé láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tí ayé yìí ti wà, àìmọye ni ìran èèyàn tó ti wá tí wọ́n sì ti lọ. Síbẹ̀, ayé dúró digbí, mìmì kan ò sì mì í. Àmọ́ ó ṣeé ṣe kí nǹkan yí pa dà láìpẹ́.

Látìgbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ti jà ni ìyípadà tó bùáyà ti bá ayé yìí. Bí àpẹẹrẹ, ìtẹ̀síwájú tó gadabú ti dé bá ètò ìrìn àjò, ètò ìbánisọ̀rọ̀ àtàwọn ohun èlò ìgbàlódé míì, èyí sì ti mú kí ọrọ̀ ajé gbèrú sí i. Àwọn nǹkan yìí sì ti mú kí àwọn èèyàn máa gbé ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ. Kódà, iye èèyàn tó ń gbé láyé yìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po mẹ́ta ti tẹ́lẹ̀.

Gbogbo ìtẹ̀síwájú yìí kò ṣàì ní àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó tiwọn. Bí àpẹẹrẹ, bí àwọn èèyàn ṣe ń lo ayé yìí nílòkulò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bà á jẹ́ débi pé tó bá yá, gbogbo nǹkan dáadáa tí Ọlọ́run dá sí ayé kò ní ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ mọ́. Kódà, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé à ń gbé ní àkókò kan tí wọ́n pè ní Anthropocene, ìyẹn àkókò táwọn èèyàn ń ṣe nǹkan tó túbọ̀ ń ba ayé jẹ́ sí i.

Bíbélì sọ pé àkókò kan ń bọ̀ tí àwọn èèyàn máa “pa ayé run.” (Ìṣípayá 11:18, Bíbélì Mímọ́) Àwọn kan wòye pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àkókò yẹn gan-an la wà yìí. Báwo làwọn èèyàn ṣe máa ba  ayé yìí jẹ́ tó? Ṣé àwọn èèyàn ò ní ba ayé yìí jẹ́ kọjá àtúnṣe?

ǸJẸ́ AYÉ YÌÍ LÈ BÀ JẸ́ KỌJÁ ÀTÚNṢE?

Ṣé òótọ́ ni ayé yìí ti fẹ́ bà jẹ́ kọjá àtúnṣe? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé kò sẹ́ni tó lè sọ bí àwọn ìyípadà tó ń lọ láyé yìí ṣe máa ṣàkóbá tó. Ìdí nìyí tí ẹ̀rù fi ń bà wọ́n pé láìpẹ́, ó ṣeé ṣe kí ojú ọjọ́ ṣàdédé yí pa dà kí àjálù sì ṣẹlẹ̀ kárí ayé.

Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo àwọn òkìtì yìnyín tó máa ń léfòó sórí omi lápá Ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Antarctic, ìyẹn ibi tó tutù jù lọ lágbàáyé. Àwọn kan sọ pé bí ayé ṣe ń móoru yìí kò dáa, tó bá ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ àwọn yìnyín náà á yòrò, ayé yìí á wá bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Èyí sì lè ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ torí pé àwọn òkìtì yìnyín yẹn ló ń gbà wá lọ́wọ́ àwọn ìtànṣán oòrùn ajónigbẹ. Bí àwọn yìnyín náà ṣe ń yòrò, ńṣe ni àwọn ìtànṣán oòrùn ń ràn dé ìsàlẹ̀ omi. Èyí tó le jù ni pé tí apá ibi tó dúdú kirikiri lórí omi bá bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìtànṣán oòrùn yìí sára, ńṣe ni gbogbo yìnyín náà á yọ́ tán tí ẹnikẹ́ni ò sì ní lè ṣe nǹkan kan sí i. Bí èyí bá lọ ṣẹlẹ̀, omi òkun á kún àkúnya, wàhálà dé nìyẹn fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé!

LÍLO ILẸ̀ AYÉ NÍLÒKULÒ

Oríṣiríṣi ètò ni wọ́n ti ṣe láti dènà bí àwọn èèyàn ṣe ń lo ayé yìí nílòkulò. Ọ̀kan lára rẹ̀ ni pé wọ́n ń bójú tó báwọn èèyàn ṣe ń lo àwọn nǹkan, kí wọ́n má bàa ṣì í lò tí á fi wá bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Ǹjẹ́ ètò náà ti kẹ́sẹ járí?

Ó ṣeni láàánú pé, kàkà kí ìṣòro yìí dín kù, ńṣe ló tún ń le sí i. Ọ̀rọ̀ náà wá dà bí ẹni tó ń kówó ìlú jẹ títí tó fi jẹ ìlú run. Òótọ́ ni pé Ọlọ́run ṣe ayé yìí lọ́nà tí àwọn nǹkan tó wà nínú rẹ̀ á fi máa sọ ara wọn dọ̀tun, àmọ́ ìlò táwọn èèyàn ń lò ó ti kọjá bó ṣe yẹ. Kí wá la lè ṣe? Ọ̀gbẹ́ni kan tó mọ̀ nípa àwọn ohun alààyè àti àyíká sọ pé: “Ká sòótọ́, a kò mọ bá a ṣe lè lo ayé yìí àtàwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá sínú rẹ̀ lọ́nà tí kò fi ní bà jẹ́.” Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.

Àmọ́ Bíbélì tún fi dá wa lójú pé, Ẹlẹ́dàá wa kò ní gbà kí àwọn èèyàn ba ayé yìí jẹ́ kọjá àtúnṣe. Ó sọ nínú Sáàmù 115:16 pé: “Ilẹ̀ ayé ni [Ọlọ́run] fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.” A gbà pé “ẹ̀bùn rere” ni  ayé yìí jẹ́ látọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run. (Jákọ́bù 1:17) Ó sì dájú pé Ọlọ́run ò ní gbé páńda lé wa lọ́wọ́ kó wá pè é ní ẹ̀bùn! Bó ṣe dá ayé yìí fi hàn pé kò fẹ́ kó pa run.

OHUN TÍ ỌLỌ́RUN NÍ LỌKÀN TÓ FI DÁ AYÉ YÌÍ

Ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe fọgbọ́n gbé ayé kalẹ̀ lọ́nà àrà. Ayé kọ́kọ́ wà ní “bọrọgidi, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà.” Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa “ibú omi” tó wà lórí ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2) Ọlọ́run wá pàṣẹ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:3) Ó dájú pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí oòrùn máa tàn yòò lójú ọ̀run tó sì mọ́lẹ̀ dé ayé. Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wá dá ilẹ̀ gbígbẹ àti òkun. (Jẹ́nẹ́sísì 1:9, 10) Nígbà tó yá, “ewéko bẹ̀rẹ̀ sí í mú irúgbìn jáde ní irú tirẹ̀, àwọn igi sì ń so èso.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:12) Gbogbo ohun tó máa gbẹ́mìí wa ró ló ti wà ní sẹpẹ́ kó tó dá èèyàn. Lára ohun ìgbẹ́mìíró yìí ni ètò tí Ọlọ́run ṣe kí àwọn ewéko lè máa méso jáde, kí wọ́n sì máa tú afẹ́fẹ́ tó tura jáde fún wa. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ṣe gbogbo ètò yìí?

Wòlíì Aísáyà sọ nípa Ọlọ́run pé òun ni: “Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀, Òun tí í ṣe Ẹni tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, ẹni tí kò wulẹ̀ dá a lásán, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Gbogbo èyí fi hàn pé ńṣe ni Ọlọ́run dá ayé fún wa ká lè máa gbé inú rẹ̀ títí láé.

Ó kàn jẹ́ pé àwọn èèyàn ti lo ayé yìí nílòkulò débi pé wọ́n ti fẹ́ bà á jẹ́ pátápátá. Àmọ́ ìyẹn ò yí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ayé yìí pa dà. Ọkùnrin kan tó gbé láyé àtijọ́ sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn tí yóò fi purọ́, tàbí ọmọ aráyé tí yóò fi kábàámọ̀. Òun fúnra rẹ̀ ha ti sọ ọ́ tí kì yóò sì ṣe é, Ó ha sì ti sọ̀rọ̀ tí kì yóò sì mú un ṣẹ.” (Númérì 23:19) Kì í ṣe pé Ọlọ́run fẹ́ gba ayé yìí lọ́wọ́ àwọn tó ń bà á jẹ́ nìkan, àmọ́ ó máa ‘run àwọn tí ń pa ayé run.’—Ìṣípayá 11:18, Bíbélì Mímọ́.

ILẸ̀ AYÉ JẸ́ IBÙGBÉ WA TÍTÍ LÁÉ

Nínú Ìwàásù Lórí Òkè tí Jésù ṣe, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5) Nígbà tó yá, Jésù tún sọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe kí àwọn èèyàn má bàa ba ayé yìí jẹ́ kọjá sísọ. Ó ní kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” Ìyẹn ni pé Ìjọba  ọ̀run ni Ọlọ́run máa lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ fún ayé yìí ṣẹ.—Mátíù 6:10.

Ọlọ́run sọ díẹ̀ lára àwọn ìyípadà tó gadabú tí Ìjọba rẹ̀ máa ṣe, ó ní: “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” (Ìṣípayá 21:5) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run máa pa ayé yìí run, á wá dá ayé míì? Rárá o, torí pé ayé yìí kọ́ ló ní ìṣòro. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tó ń ba ayé yìí jẹ́, ìyẹn “àwọn tí ń pa ayé run,” títí kan onírúurú ètò tí àwọn èèyàn gbé kalẹ̀ àtàwọn ìjọba jẹgúdújẹrá, ni ìṣòro. Ọlọ́run yóò fi “ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan” rọ́pò wọn. Ọ̀run tuntun, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso lórí ayé tuntun, ìyẹn àwùjọ àwọn èèyàn tó ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run.—Ìṣípayá 21:1.

Ọlọ́run máa ṣàtúnṣe sí gbogbo ohun táwọn èèyàn ti lò nílòkulò àti ibi táwọn èèyàn ti bà jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé. Ọlọ́run mí sí onísáàmù náà láti kọ̀wé pé: “Ìwọ ti yí àfiyèsí rẹ sí ilẹ̀ ayé, kí o lè fún un ní ọ̀pọ̀ yanturu.” Tí ojú ọjọ́ bá ti bára dé, tí Ọlọ́run sì bù kún wa, ayé yìí á di Párádísè, á sì mú oúnjẹ tó pọ̀ rẹpẹtẹ jáde.—Sáàmù 65:9-13.

Ọ̀gbẹ́ni Pyarelal tó jẹ́ akọ̀wé Mohandas Gandhi, ìyẹn aṣáájú nínú ọ̀ràn ìṣèlú àti ìjọsìn lórílẹ̀-èdè Íńdíà, sọ ohun tó gbọ́ lẹ́nu Mohandas Gandhi pé: “Ohun tó wà nínú ayé yìí tó aráyé lò, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò ṣe é torí àwọn ọ̀kánjúà tó walé ayé mọ́yà.” Ìjọba Ọlọ́run máa yanjú ohun tó wà nídìí gbogbo ìṣòro yìí, nípa yíyí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ronú pa dà. Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, àwọn èèyàn “kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí,” síra wọn tàbí sí ilẹ̀ ayé. (Aísáyà 11:9) Ní báyìí, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn láti onírúurú ẹ̀yà ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n lè mọ ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́. Ara ohun tí wọ́n ń kọ́ nínú Bíbélì ni pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò wọn, kí wọ́n máa moore, kí wọ́n má ṣe ba àyíká jẹ́, kí wọ́n má ṣe lo àyíká nílòkulò, kí wọ́n sì gbé ìgbé ayé tí Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo èèyàn máa gbé. Ńṣe ni gbogbo ohun tí wọ́n kọ́ yìí ń múra wọn sílẹ̀ de ayé tuntun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Oníwàásù 12:13; Mátíù 22:37-39; Kólósè 3:15.

Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye ni ayé wa yìí, kò yẹ ká jẹ́ kí ó bà jẹ́

Ọ̀rọ̀ tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì fi parí ọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá ni pé: “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Tí àwa náà bá wò ó dáadáa, ẹ̀bùn tó ṣeyebíye ni ayé wa yìí, kò yẹ ká jẹ́ kó bà jẹ́. Ìtùnú ńlá gbáà ló jẹ́ fún wa pé ayé yìí kò ní bà jẹ́ torí pé Ọlọ́run ló dá a, ó sì fẹ́ kó wà títí láé. Ó sì ti ṣèlérí pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, Wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Àdúrà wa ni pé kí ìwọ náà wà lára “àwọn olódodo” tó máa fi ayé yìí ṣe ibùgbé tá á sì gbé inú rẹ̀ títí láé.

^ ìpínrọ̀ 3 Ìwé Oníwàásù 1:4 nínú Bíbélì.