Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Lo Lè Ṣe Bí Ọmọ Rẹ Tó Ti Bàlágà Bá Ń Ṣiyè Méjì Nípa Ẹ̀sìn Rẹ?

Kí Lo Lè Ṣe Bí Ọmọ Rẹ Tó Ti Bàlágà Bá Ń Ṣiyè Méjì Nípa Ẹ̀sìn Rẹ?

Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀

Kí Lo Lè Ṣe Bí Ọmọ Rẹ Tó Ti Bàlágà Bá Ń Ṣiyè Méjì Nípa Ẹ̀sìn Rẹ?

Bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń dàgbà, ọ̀pọ̀ lára wọn máa ń yan ẹ̀sìn òbí wọn. (2 Tímótì 3:14) Àmọ́ àwọn kan kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Kí lo lè ṣe bí ọmọ rẹ tó ti bàlágà bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì nípa ẹ̀sìn rẹ? Àpilẹ̀kọ yìí máa ṣàlàyé nípa bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń yanjú irú ìṣòro bẹ́ẹ̀.

“Mi ò fẹ́ ṣe ẹ̀sìn tí àwọn òbí mi ń ṣe mọ́. Kò kàn wù mí mọ́ ni.”—Cora, ọmọ ọdún méjìdínlógún. *

ÓDÁ ọ lójú pé òtítọ́ nípa Ọlọ́run ni ẹ̀sìn rẹ fi ń kọ́ni. O gbà pé Bíbélì ń kọ́ni béèyàn ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dára jù lọ. Nígbà náà, ohun tó máa wù ẹ́ ni pé kó o fi àwọn ohun tó o kà sí iyebíye yìí kọ́ ọmọ rẹ. (Diutarónómì 6:6, 7) Àmọ́, kí ni wàá ṣe ká ní bí ọmọ rẹ ṣe ń dàgbà ni ìfẹ́ rẹ̀ sí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọsìn Ọlọ́run ń dín kù? Kí ni wàá ṣe bí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì nípa ẹ̀sìn tó jọ pé ó fayọ̀ tẹ́wọ́ gbà láti kékeré?—Gálátíà 5:7.

Bí irú èyí bá ń ṣẹlẹ̀ sí ọ, má ṣe rò pé òbí tó ti di aláṣetì ni ẹ́. Ó lè jẹ́ pé nǹkan míì ló fà á, a sì máa mọ àwọn nǹkan náà bí a ti ń bá ọ̀rọ̀ yìí lọ. Àmọ́, jẹ́ kí ó yé ọ pé: Bí o bá ṣe bójú tó iyèméjì tí ọmọ rẹ ní ló máa pinnu bóyá ọmọ náà máa fẹ́ láti mọ̀ sí i nípa ẹ̀sìn rẹ tàbí á fẹ́ láti jáwọ́ nínú rẹ̀. Tí o bá sọ ọ̀rọ̀ náà di awuyewuye, ó máa dá ìjà ńlá sílẹ̀ láàárín yín, bóyá ni wàá lè borí nínú ìjà náà.—Kólósè 3:21.

Ó sàn kéèyàn fetí sí ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó sọ pé: “Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, ẹni tí ó tóótun láti kọ́ni, tí ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu.” (2 Tímótì 2:24) Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o “tóótun láti kọ́ni” bí ọmọ rẹ tó ti bàlágà bá ń ṣiyè méjì nípa ẹ̀sìn rẹ?

Lo Ìjìnlẹ̀ Òye

Lákọ̀ọ́kọ́, sapá láti mọ àwọn ohun tó fà á tí ọmọ rẹ fi sọ pé òun kò ṣe ẹ̀sìn rẹ mọ́. Bí àpẹẹrẹ:

Ṣé ọmọ rẹ ń ronú pé òun dá wà tí òun kò sì ní ọ̀rẹ́ láàárín ìjọ Kristẹni ni? “Nítorí pé mo fẹ́ ní ọ̀rẹ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn kan lára àwọn tá a jọ ń lọ sí iléèwé ṣọ̀rẹ́, ìyẹn kò sì jẹ́ kí n ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún. Mi ò nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, ohun tó sì fà á ni ẹgbẹ́ búburú tí mò ń kó, mo wá ń kábàámọ̀ gan-an báyìí.”—Lenore, ọmọbìnrin ọdún mọ́kàndínlógún

Ṣé àyà ọmọ rẹ máa ń já, tó sì máa ń ṣòro fún un láti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn rẹ̀? “Nígbà tí mo wà nílé ìwé, mi ò kì í fẹ́ sọ nípa ẹ̀sìn mi fún àwọn ọmọ kíláàsì mi. Ẹ̀rù máa ń bà mí pé wọ́n á máa wò mí bí ẹni tí kò bẹ́gbẹ́ mu tàbí bí ẹní tí kò mọ̀ jù ọ̀ràn Bíbélì lọ. Wọn kì í fojúure wo ọmọ tó bá ti yàtọ̀, mi ò sì fẹ́ kí irú ìyẹn ṣẹlẹ̀ sí mi.”—Ramón, ọmọkùnrin ọdún mẹ́tàlélógún.

Ṣé ọmọ rẹ rò pé àwọn ìlànà Kristẹni ti le ju ohun tóun lè máa tẹ̀ lé? “Ó ń ṣe mí bíi pé ìyè àìnípẹ̀kun tí Bíbélì ṣèlérí wà ní òkè àtẹ̀gùn kan tó ga, tí mi ò tiẹ̀ tíì bẹ̀rẹ̀ sí í gun àtẹ̀gùn náà, nítorí ọ̀nà mi jìn gan-an sí ibi tí àtẹ̀gùn náà wà. Ẹ̀rù ń bà mí gan-an pé ọwọ́ mi ò ní lè tẹ ìyè àìnípẹ̀kun débi tí mo fi ń ronú pé bóyá kí n má ṣe ẹ̀sìn mi mọ́.”—Renee, ọmọbìnrin ọdún mẹ́rìndínlógún.

Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀

Kí ni ọmọ rẹ tó ti bàlágà ń rò nípa ẹ̀sìn rẹ? Ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà mọ̀ ni pé kó o béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Àmọ́, kó o ṣọ́ra kí ọ̀rọ̀ yín má di àríyànjiyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, tẹ̀ lé àmọ̀ràn tó wà nínú ìwé Jákọ́bù 1:19 tó sọ pé: “Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” Ní sùúrù fún un. Lo “gbogbo ìpamọ́ra àti ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” láti bá a sọ̀rọ̀ bó o ṣe máa bá ẹni tí kì í ṣe ará ilé rẹ sọ̀rọ̀.—2 Tímótì 4:2.

Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ rẹ kò bá fẹ́ máa lọ sí ìpàdé ìjọ Kristẹni, sapá láti mọ̀ bóyá nǹkan míì wà tó ń dà á láàmú. Àmọ́ sùúrù ni kó o fi ṣe é. Ó ṣòro fún òbí tá a fẹ́ sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpẹẹrẹ yìí láti mọ ohun tó wà lọ́kàn ọmọ rẹ̀.

Ọmọ: Ìpàdé ìjọ ò wù mí lọ mọ́.

Bàbá: [ó fi ìbínú sọ̀rọ̀] Kí nìdí tí ò fi wù ẹ́ mọ́?

Ọmọ: Ó kàn mi náà ni!

Bàbá: Ṣé èrò rẹ nípa Ọlọ́run nìyẹn? Ṣé Ọlọ́run ti  ẹ ni? Ọ̀rọ̀ játijàti lò ń sọ lẹ́nu yẹn! Níwọ̀n ìgbà tó o bá ṣì ń gbé lábẹ́ òrùlé mi, dandan ni kí o máa bá wa lọ sáwọn ìpàdé ìjọ!

Ọlọ́run ní kí àwọn òbí máa kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa òun àti pé kí àwọn ọmọ máa ṣègbọràn sí àwọn òbí wọn. (Éfésù 6:1) Àmọ́, o kò ní fẹ́ kí ọmọ rẹ máa ṣe ìjọsìn pẹ̀lú rẹ láìronú, o kò sì ní fẹ́ kó máa bá ẹ lọ sí ìpàdé tí kò bá ti ọkàn rẹ̀ wá. Tó bá ṣeé ṣe, o fẹ́ kí ìjọsìn tí ẹ jọ ń ṣe ti ọkàn rẹ̀ wá.

Wàá lè ràn án lọ́wọ́ lórí èyí, tó o bá mọ àwọn ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ tó mú kó sọ ohun tó sọ. Wá wo bí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ìṣáájú yẹn ṣe yẹ kó rí, tó sì máa so èso rere.

Ọmọ: Ìpàdé ìjọ ò wù mí lọ mọ́.

Bàbá: [ó fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ sọ̀rọ̀] Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

Ọmọ: Ó kàn mi náà ni!

Bàbá: Kéèyàn jókòó fún wákàtí kan tàbí méjì lè súni lóòótọ́. Àmọ́, kí ló jẹ́ kó sú ẹ gan-an?

Ọmọ: Mi ò tiẹ̀ mọ̀. Ó kan ń ṣe mí bíi pé, ó yẹ kí n wà níbòmíì ni.

Bàbá: Ṣé ohun táwọn ọ̀rẹ́ rẹ ń rò nìyẹn?

Ọmọ: Ìṣòro mi gan-an nìyẹn! Mi ò ọ̀rẹ́ kankan mọ́. Láti ìgbà tí ọ̀rẹ́ mi àtàtà ti lọ kúrò níbí, mi ò rí ẹni bá sọ̀rọ̀ mọ́! Kálukú ló ní ẹni tó ń bá kẹ́gbẹ́, àmọ́ èmi kò rí ẹni bá rìn!

Bàbá yìí mú kí ọmọ rẹ̀ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Yàtọ̀ sí pé èyí jẹ́ kó mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro ọmọ náà, ìyẹn ìdánìkanwà, ó tún mú kí ọmọ náà fọkàn tán òun, kó fẹ́ láti máa sọ èrò ọkàn rẹ̀.—Wo àpótí náà,  “Ní Sùúrù!”

Bí àkókò ti ń lọ, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ máa ń rí i pé bí wọ́n bá wá nǹkan ṣe sí ohun tí kì í jẹ kí wọ́n fẹ́ jọ́sìn Ọlọ́run, inú wọn máa ń dùn sí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti sí ara wọn. Gbé ọ̀ràn Ramón yẹ̀ wò, ọ̀dọ́kùnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ tó máa ń tijú nílé ìwé láti fi ara rẹ̀ hàn pé Kristẹni lòun. Níkẹyìn, Ramón rí i pé tí òun bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn òun, kì í fún òun ní ìpayà bí òun ṣe rò tẹ́lẹ̀, kódà bí wọ́n tiẹ̀ fi òun ṣe yẹ̀yẹ́. Ó sọ pé:

“Nígbà kan, ọmọkùnrin kan nílé ìwé ń fi mi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ẹ̀sìn mi. Jìnnìjìnnì bò mí, mo sì mọ̀ pé gbogbo kíláàsì ti ń gbọ́ ohun tí à ń sọ. Nígbà náà ni mo dojú ọ̀rọ̀ kọ ọmọkùnrin náà, mo bi í ní ìbéèrè nípa ẹ̀sìn rẹ̀. Ó yà mí lẹ́nu pé jìnnìjìnnì tó bá a ju tèmi lọ! Ìgbà yẹn ni mo wá mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ní ẹ̀sìn, àmọ́ wọn kò mọ ohun tí ẹ̀sìn wọn fi ń kọ́ni. Tèmi tiẹ̀ ṣì dáa, mo lè ṣàlàyé ẹ̀sìn mi. Ní tòótọ́, tí a bá ní ki ẹnì kọ̀ọ̀kan máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn rẹ̀, àwọn ọmọ kíláàsì mi ló yẹ kí ojú máa tì, kì í ṣe èmi!”

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Wádìí ohun tó wà lọ́kàn ọmọ rẹ tó ti bàlágà, kí o béèrè èrò rẹ̀ nípa jíjẹ́ tó jẹ́ Kristẹni. Ní tirẹ̀, àwọn àǹfààní wo ló rò pé ó wà nínú rẹ̀? Àwọn nǹkan wo lo gbọ́dọ̀ yááfì láti jẹ́ Kristẹni? Ṣé àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀ ju àwọn nǹkan tó o máa yááfì lọ? Tó bá jẹ́ pé àwọn àǹfààní náà ló pọ̀ jù lọ, kí nìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀? (Máàkù 10:29, 30) Ọmọ náà lè kọ èrò rẹ̀ sórí ìwé, kí ó pín in sí ọ̀nà méjì, apá àkọ́kọ́ wà fún àwọn ohun tó ní láti yááfì, apá kejì wà fún àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀. Rírí àlàyé yìí lórí ìwé máa jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ ìṣòro rẹ̀ àti ohun tó máa ṣe láti yanjú rẹ̀.

“Agbára Ìmọnúúrò” Ọmọ Rẹ

Àwọn òbí àtàwọn ọ̀mọ̀ràn ṣàkíyèsí pé ọ̀nà tí àwọn ọmọdé ń gbà ronú yàtọ̀ gan-an sí ọ̀nà tí àwọn ọmọ tó ti bàlágà ń gbà ronú. (1 Kọ́ríńtì 13:11) Àwọn ọmọdé kì í ronú jinlẹ̀, àmọ́ àwọn ọmọ tó ti bàlágà máa ń ronú jinlẹ̀ lóríṣiríṣi ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè kọ́ ọmọdé pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo. (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Àmọ́, ọmọ tó ti bàlágà lè máa ronú lórí àwọn ìbéèrè bíi: ‘Báwo ni mo ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run wà? Kí nìdí tí Ọlọ́run ìfẹ́ fi fàyè gba ibi? Báwo ló ṣe jẹ́ òótọ́ pé Ọlọ́run wà láti ayérayé?’—Sáàmù 90:2.

O lè rò pé irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ọmọ rẹ tó ti bàlágà ti ń fi ohun tó gbà gbọ́ sílẹ̀ nìyẹn. Àmọ́, ńṣe ló ń fi hàn pé ó fẹ́ mọ ohun tó gbà gbọ́ ní àmọ̀dájú. Ó ṣe tán, bíbéèrè ìbéèrè jẹ́ ohun pàtàkì tó fi hàn pé àjọṣe ẹnì kan pẹ̀lú Ọlọ́run ti ń dára sí i.—Ìṣe 17:2, 3.

Síwájú sí i, ọmọ rẹ tó ti bàlágà ń kọ́ bó ṣe máa lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ̀. (Róòmù 12:1, 2) Nítorí náà, yóò lè mọ “ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” ohun tí Kristẹni gbà gbọ́, tó máa yàtọ̀ sí bí ọmọdé ṣe mọ̀ ọ́n. (Éfésù 3:18) Yàtọ̀ síyẹn, ìsinsìnyí ló yẹ kó o ran ọmọ rẹ tó ti bàlágà lọ́wọ́ láti máa ronú lórí àwọn ohun tó gbà gbọ́ kí àwọn ohun náà lè dá a lójú.—Òwe 14:15; Iṣe 17:11.

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn ohun tó yẹ kéèyàn kọ́kọ́ mọ̀, kí ìwọ àti ọmọ rẹ tún gbé àwọn nǹkan tí ẹ lè má fi bẹ́ẹ̀ kà sí tẹ́ lẹ̀ yẹ̀ wò. Bí àpẹẹrẹ, ní kí ó ronú lórí àwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí ló mú kí n gbà pé Ọlọ́run wà? Ẹ̀rí wo ni mo rí tó fi hàn pé Ọlọ́run bìkítà nípa mi? Kí nìdí tí mo fi rò pé ìgbà gbogbo ló máa ṣe mí láǹfààní tí mo bá ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run?’ Ṣọ́ra kí ó má ṣe fipá mú ọmọ rẹ pé kó gba èrò rẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o ràn án lọ́wọ́ kí ohun tó gbà gbọ́ náà lè dá a lójú. Nípa bẹ́ẹ̀, yóò rọrùn fún un láti mọ̀ pé ẹ̀sìn òun dára.

‘Yí I Lérò Padà Láti Gbà Gbọ́’

Bíbélì sọ nípa ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Tímótì tó ti mọ Ìwé Mímọ́ “láti ìgbà ọmọdé jòjòló.” Síbẹ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì pé: “Máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́.” (2 Tímótì 3:14, 15) Bíi ti Tímótì, o ti lè kọ́ ọmọ rẹ tó ti bàlágà ní àwọn ìlànà inú Bíbélì láti ìgbà tó o ti bí i. Àmọ́ nísinsìnyí, o ní láti ràn án lọ́wọ́ kí ohun tó gbà gbọ́ lè dá a lójú.

Ìwé náà, Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní sọ pé: “Bí ọmọ rẹ bá ṣì ń gbé nínú ilé rẹ, o lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ kó mọ̀ pé ìjọsìn kan náà lo fẹ́ kẹ́ ẹ jọ máa ṣe. Ṣùgbọ́n, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o jẹ́ kí ọmọ rẹ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kì í ṣe pé kó kàn máa fojú lásán ṣe ìjọsìn láìfọkàn ṣe é.” Tí o bá fi èyí sọ́kàn, wàá lè ran ọmọ rẹ tó ti bàlágà lọ́wọ́ láti “dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́” tí yóò sì di ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀, kì í ṣe tìrẹ nìkan. *1 Pétérù 5:9.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí àwọn orúkọ inú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i wo Ilé Ìṣọ́ May 1, 2009, ojú ìwé 10 sí 12, àti Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní, ojú ìwé 315 sí 318.

BI ARA RẸ . . .

▪ Báwo ni mo ṣe máa ṣe tí ọmọ mi bá ń ṣiyè méjì nípa ẹ̀sìn mi?

▪ Báwo ni mo ṣe máa lo ohun tó wà nínu àpilẹ̀kọ yìí láti tún èrò mi ṣe?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]

Ṣé Wọ́n Ń Ra Ọmọ Wọn Níyè Ni?

Irọ́: Àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fipá mú àwọn ọmọ wọn láti ṣe ẹ̀sìn wọn.

Òótọ́: Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti pa á láṣẹ fún àwọn òbí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. (Éfésù 6:4) Àmọ́ ṣá o, wọ́n mọ̀ pé bí ọmọ kan bá ti dàgbà, òun fúnra rẹ̀ ló máa pinnu ẹ̀sìn tí òun máa ṣe.—Róòmù 14:12; Gálátíà 6:5.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ní Sùúrù!

 Tó o bá ń bá ọmọ rẹ tó ti bàlágà sọ̀rọ̀, ìyẹn lè gba pé kó o ní sùúrù gan-an. Àmọ́ bí ọmọ rẹ bá ti wá fọkàn tán ẹ, wàá rí i pé àǹfààní tó wà níbẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọmọbìnrin ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan sọ pé: “Nìgbà tí mò ń bá dádì mi sọ̀rọ̀ ní alẹ́ ọjọ́ kan, mo sọ fún un pé mo ti ń lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì láìjẹ́ kí ó mọ̀, mo ní ọ̀rẹ́kùnrin kan, mo sì fẹ́ sá kúrò nílé. Dádì mi kò bínú rárá ní ìgbà tó fi bá mi sọ̀rọ̀! Mi ò mọ bàbá tó máa jókòó tí kò ní jágbe mọ́ ọmọbìnrin rẹ̀ lẹ́yìn tó gbọ́ pé ó fẹnu ko ọkùnrin kan lẹ́nu àti pé ìgbà gbogbo ló ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i lórí fóònù. Mi ò rò pé nǹkan wà láyé yìí tí mi ò lè sọ fún dádì mi. Mo mọ̀ pé ó fẹ́ ràn mí lọ́wọ́ lóòótọ́.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]

Ó Nílò Agbaninímọ̀ràn

Nígbà míì, àwọn ọ̀dọ́ máa ń ṣe dáadáa tí wọ́n bá rí àgbàlagbà míì kan tí kì í ṣe ará ilé wọn tó ń gbà wọ́n nímọ̀ràn. Ǹjẹ́ o mọ ẹnì kan tó ń ṣe dáadáa nínú ìjọsìn Ọlọ́run tí ọmọ rẹ lè fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? O ò ṣe kúkú ṣètò pé kí ọmọ rẹ àti ẹni náà jọ ṣe àwọn nǹkan kan pa pọ̀? Kì í ṣe torí kó o lè yẹ ojúṣe rẹ sílẹ̀ o. Ìwọ wo àpẹẹrẹ Tímótì. Ó jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ látara àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, Pọ́ọ̀lù náà sì jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ bí Tímótì ṣe jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.—Fílípì 2:20, 22. *

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A mú un jáde látinú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní, tí a tẹ̀ ní ọdún 2011, ojú ìwé 318, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.