Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Pansaga

Pansaga

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló gbà pé ó dáa kí tọkọtaya jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn, síbẹ̀ panṣágà ṣì ń dá ìṣòrò tó le koko sílẹ̀ nínú ọ̀pọ̀ ìdílé.

Kí ni panṣágà?

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan, wọ́n gbà pé kò sí ohun tó burú nínú kéèyàn máa yan àlè, pàápàá tó bá jẹ́ ọkọ. Àwọn kan sì gbà pé ìgbéyàwó kì í ṣe ohun tó yẹ kó wà pẹ́ títí.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Nínú Bíbélì, ohun tí panṣágà túmọ̀ sí ni pé kí ẹnì kan tó ti ṣègbéyàwó, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, mọ̀ọ́mọ̀ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ̀. (Jóòbù 24:15; Òwe 30:20) Ọlọ́run kórìíra panṣágà. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ní Ísírẹ́lì àtijọ́, ẹjọ́ ikú ni wọ́n máa ń dá fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣe panṣágà. (Léfítíkù 18:20, 22, 29) Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.—Mátíù 5:27, 28; Lúùkù 18:18-20.

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ

Ńṣe ni ẹni tó bá ṣe panṣágà da ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ fún ẹnì kejì rẹ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn. Ó sì tún jẹ́ ‘ẹ̀ṣẹ̀ sí Ọlọ́run.’ (Jẹ́nẹ́sísì 39:7-9) Panṣágà tún máa ń fa ìyapa láàárín òbí àti ọmọ. Láfikún sí i, Bíbélì kìlọ̀ pé “Ọlọ́run yóò dá . . . àwọn panṣágà lẹ́jọ́.”—Hébérù 13:4.

“Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin.”—Hébérù 13:4.

Ṣé panṣágà lè mú kí tọkọtaya kọ ara wọn sílẹ̀?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì sọ pé àwọn tọkọtaya lè kọ ara wọn sílẹ̀ tí ọkàn lára wọn bá ṣe panṣágà. (Mátíù 19:9) Èyí fi hàn pé tí ẹnì kan bá dalẹ̀ ọkọ tàbí aya rẹ̀, ẹnì kejì lè pinnu láti dárí jì í tàbí kó jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ fún un. Àmọ́ o, òun fúnra rẹ̀ ló máa yan èyí tó máa ṣe.—Gálátíà 6:5.

Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí ohunkóhun má ṣe tú ìgbéyàwó ká. (1 Kọ́ríńtì 7:39) Ọlọ́run kò fẹ́ kí ẹnì kan kọ ọkọ tàbí aya rẹ̀ sílẹ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn tí kò tó nǹkan, irú bíi pé ìwà ẹnì kejì rẹ̀ kò tẹ́ ẹ lọ́rùn. Torí náà, kò yẹ kéèyàn kàn ṣàdédé pinnu pé òun máa kọ ọkọ tàbí aya òun sílẹ̀.—Málákì 2:16; Mátíù 19:3-6.

“Mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe ní tìtorí àgbèrè, sọ ọ́ di olùdojúkọ ewu panṣágà.”Mátíù 5:32.

Ṣé Ọlọ́run lè dárí ji ẹni tó bá ṣe panṣágà?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa ń fi àánú hàn sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà, tí wọ́n sì jáwọ́ nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, títí kan ẹni tó ṣe panṣágà. (Ìṣe 3:19; Gálátíà 5:19-21) Bíbélì tiẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tó jáwọ́ nínú ṣíṣe panṣágà, tí wọ́n sì di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.—1 Kọ́ríńtì 6:9-11.

Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tí Ọlọ́run fojú àánú hàn sí Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un, tó ṣe panṣágà pẹ̀lú ìyàwó ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 11:2-4) Bíbélì sọ ní kedere pé “ohun tí Dáfídì ṣe jẹ́ ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.” (2 Sámúẹ́lì 11:27) Lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá Dáfídì wí, ó ronú pìwà dà, Ọlọ́run sì dárí jì í. Àmọ́, Dáfídì ṣì jìyà àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 12:13, 14) Nígbà tó yá, Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba sọ pé “ẹni tí ó bá . . . ṣe panṣágà, kò ní òye.”—Òwe 6:32. BIBELI YORUBA ATỌ́KA.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Tó o bá ti ṣe panṣágà, ó yẹ kó o tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Ọlọ́run, kó o sì tún bẹ ẹnì kejì rẹ pé kó dárí jì ẹ́. (Sáàmù 51:1-5) Ìwọ́ náà gbọ́dọ̀ kórìíra panṣágà bí Ọlọ́run ṣe kórìíra rẹ̀. (Sáàmù 97:10) Pinnu pé o kò ní máa wo fíìmù tàbí fọ́tò ìṣekúṣe, o sì tún gbọ́dọ̀ fa èrò ìṣekúṣe tu kúrò lọ́kàn rẹ. Síwájú sí i, má ṣe máa tage, má sì ṣe ohunkóhun tó lè mú kó máa wù ẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ.—Mátíù 5:27, 28; Jákọ́bù 1:14, 15.

Bí ọkọ tàbí aya rẹ bá ti ṣe panṣágà rí, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ. (Málákì 2:13, 14) Bẹ Ọlọ́run pé kó tù ẹ́ nínú, kó sì tọ́ ẹ sọ́nà. Ó dájú pé Ọlọ́run á “gbé ọ ró.” (Sáàmù 55:22) Tó o bá yàn láti dárí ji ẹnì kejì rẹ tó ṣe panṣágà kí ìgbéyàwó yín má báa túká, ẹ̀yin méjèèjì lẹ jọ máa pawọ́ gbé ìdílé yín ró.—Éfésù 4:32.

Lẹ́yìn tí Dáfídì ronú pìwà dà, wòlíì Nátánì sọ fún un pé “Jèhófà, ẹ̀wẹ̀, jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kọjá lọ.”—2 Sámúẹ́lì 12:13.