Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Máa Gbọ́ràn

Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Máa Gbọ́ràn

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Gbogbo ìgbà ṣáá ni ọmọ rẹ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin máa ń kọ ọ̀rọ̀ sí ẹ lẹ́nu. Ó sì máa ń mú un jẹ.

  • Tó o bá ní kó ṣe ohun kan, àmọ́ tí kò wù ú ṣe, ńṣe ló máa fi ẹ́ gún lágídi.

  • Tí ọmọ náà bá fẹ́ ṣe nǹkan, àmọ́ tó o sọ pé kò gbọ́dọ̀ ṣe é, ńṣe láá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìjọ̀ngbọ̀n.

O lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé, ‘Ṣé torí pé ó ṣì kéré ló fi ń ṣe báyìí? Ṣé ó ṣì máa jáwọ́ tó bá yá?’

O kọ́ ọmọ rẹ láti máa gbọ́ràn. Àmọ́ ká tó jíròrò ohun tó o lè ṣe, ó yẹ kó o mọ ìdí tí ọmọ rẹ fi ń ṣàìgbọràn.

ÌDÍ TÓ FI MÁA Ń ṢẸLẸ̀

Nígbà tí ọmọ rẹ wà ní ìkókó, ojúṣe rẹ ni láti máa fún un ní ìtọ́jú tó yẹ. Gbogbo ohun tó bá ṣáà ti fẹ́ lo máa ń ṣe fún un. Tó bá ti sunkún, kíá o ti fò dìde, bó o ṣe ń fi tibí lọ̀ ọ́, ni wà á máa fi tọ̀hún lọ̀ ọ́. Ká sòótọ́, ohun tó yẹ kó o ṣe lò ń ṣe torí pé àwọn ọmọ ìkókó máa ń nílò àbójútó ní gbogbo ìgbà.

Tó o bá ṣìkẹ́ rẹ̀ lọ́nà yìí fún ọ̀pọ̀ oṣù, kò ní pẹ́ tí ọmọ náà á fi máa rí ara rẹ̀ bí ọba nínú ilé. Á máa wo àwọn òbí rẹ̀ bí ọmọ-ọ̀dọ̀ tó ń ṣe gbogbo nǹkan tó bá fẹ́. Àmọ́ tí ọmọ náà bá ti ń pé bí ọmọ ọdún méjì, nǹkan á yí pa dà bírí, á sì bẹ̀rẹ̀ sí í kíyèsí pé ìjọba òun ti dópin. Lọ́tẹ̀ yìí, òun kọ́ láá máa sọ nǹkan tó fẹ́ fún àwọn òbí rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn òbí rẹ̀ láá máa sọ ohun tí wọ́n fẹ́ fún un. Àyípadà yìí kì í bára dé fún àwọn ọmọ. Èyí lè mú kí àwọn ọmọ kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìjọ̀ngbọ̀n. Àwọn míì sì máa ń ṣàìgbọràn kí wọ́n lè mọ bí òfin àwọn òbí náà ṣe rinlẹ̀ tó.

Ní àkókò tó gbẹgẹ́ yẹn, o gbọ́dọ̀ jẹ́ kó ṣe kedere pé ìwọ ni ọ̀gá inú ilé báyìí. Iṣẹ́ rẹ sì ni láti máa sọ ohun tí ọmọ rẹ gbọ́dọ̀ ṣe. Àmọ́, tí ọmọ rẹ bá ń ṣorí kunkun bíi ti ọmọ tá a ṣàpèjúwe rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ńkọ́?

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé ohun tó o sọ labẹ gé. Ọmọ rẹ kò ní gbà pé ìwọ lọ̀gá inú ilé àyàfi tó bá rí ẹ tó o ṣèṣe ọ̀gá. Torí náà, o gbọ́dọ̀ jẹ́ kó mọ̀ pé ìwọ ni wàá máa sọ bí nǹkan á ṣe máa lọ nínú ilé, síbẹ̀ má ṣe le koko jù. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní ọ̀mọ̀ràn sọ pé kò yẹ kéèyàn máa pàṣẹ fún ẹlòmíì. Ọ̀kan nínú wọn tiẹ̀ sọ pé kí òbí máa pàṣẹ fún ọmọ kò yẹ láwùjọ èèyàn rára. Àmọ́ tí èèyàn bá lọ kẹ́ ọmọ ju bó ṣe yẹ lọ, ńṣe ni ọmọ náà máa bà jẹ́, kò ní mọ ohun tó yẹ kó ṣe, á sì máa rò pé gbogbo ohun tí òun bá ṣe ló tọ́. Ọmọ téèyàn bá tọ́ lọ́nà yìí lè má wúlò fún ara rẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 29:15.

Máa fún ọmọ rẹ ní ìbáwí tó tọ́. Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé ìbáwí túmọ̀ sí “kíkọ́ ẹnì kan láti jẹ́ onígbọràn tàbí ẹni tó ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu. Ó máa ń gba pé kí èèyàn ṣòfin, kí ìyà tó tọ́ sì wà fún ẹni tó bá rú òfin náà.” Kò yẹ kí èèyàn wá tìtorí pé ó fẹ́ bá ọmọ wí, kó wá máa lù ú nílùkulù tàbí kó máa ṣépè fún un. Bákan náà, tó o bá fẹ́ bá ọmọ rẹ wí, jẹ́ kó mọ ìdí tó o fi ń bá a wí àti ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ tó bá ṣàìgbọràn.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 23:13.

Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe kedere. Kàkà kí àwọn òbí kan sọ̀rọ̀ ṣàkó, ńṣe ni wọ́n máa ń pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè sọ pé, “ṣé ò ní gbalẹ̀ ilé yìí ni?” Wọ́n lè máa rò pé àwọn ò fẹ́ le koko mọ ọmọ náà. Àmọ́ irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kí òbí lẹ́nu ọ̀rọ̀, ńṣe ló máa ń mú kí ọmọ rò pé òun lè yàn láti ṣe nǹkan náà tàbí kí òun má ṣe é. Dípò tí wàá fi máa pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ, á dáa kó o sọ ohun tó o fẹ́ kí ọmọ náà ṣe lọ́nà tó ṣe kedere.—Ìlànà Bíbélì: 1 Kọ́ríńtì 14:9.

Dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ. Bó o bá ti sọ pé nǹkan báyìí lo máa ṣe, má ṣe yí ọ̀rọ̀ rẹ pa dà. Kí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ sì jọ fi ẹnu kan bá ọmọ yín wí. Bó o bá ti sọ ìyà tí wàá fi jẹ ọmọ rẹ tó bá ṣàìgbọràn, rí i dájú pé ìyà yẹn náà lo fi jẹ ẹ́. Má ṣe máa bá ọmọ rẹ jiyàn lórí ìdí tó o fi ṣe ìpinnu kan. Òótọ́ kan ni pé, ó máa rọrùn fún ọmọ rẹ àti ìwọ alára tó o bá jẹ́ ‘kí Bẹ́ẹ̀ ni rẹ jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni, àti Bẹ́ẹ̀ kọ́ rẹ, Bẹ́ẹ̀ kọ́.’—Jákọ́bù 5:12.

Nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ. Kò yẹ kéèyàn gbọ̀jẹ̀gẹ́ tàbí kó o jẹ́ apàṣẹwàá nínú ìdílé. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ṣètò ìdílé kí àwọn òbí lè fìfẹ́ tọ́ àwọn ọmọ kí wọ́n lè di àrídunnú lẹ́yìnwá ọ̀la. Ìbáwí wà lára ohun téèyàn fi ń tọ́ ọmọ kó lè jẹ́ onígbọràn, èyí á sì mú kí ọkàn ọmọ rẹ balẹ̀ pé lóòótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ òun.