Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Pa Dà Máa Fọkàn Tán Ara Yín

Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Pa Dà Máa Fọkàn Tán Ara Yín

Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀

Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Pa Dà Máa Fọkàn Tán Ara Yín

Steve *: “Mi ò lálàá ẹ̀ rí rárá pé Jodi, ìyàwó mi, lè ṣe panṣágà. Ó já mi kulẹ̀ pátápátá. Ó ṣòro fún mi gan-an láti dárí jì í.”

Jodi: “Mo mọ ohun tó mú kí Steve, ọkọ mi, má fọkàn tán mi mọ́. Ó gbà mí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láti jẹ́ kó mọ̀ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ba èmi náà nínú jẹ́ gan-an.”

BÍBÉLÌ gba àwọn tí ọkọ wọn tàbí ìyàwó wọn bá ṣe panṣágà láyè láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ tàbí kí wọ́n má ṣe kọ̀ ọ́ sílẹ̀. * (Mátíù 19:9) Steve tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè yìí pinnu láti má ṣe kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀. Òun àti Jodi, ìyàwó rẹ̀, jọ pinnu pé àwọn kò ní tú ká. Àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n fi wá rí i pé ọ̀rọ̀ náà ju káwọn kàn jọ máa gbé pa pọ̀ lọ. Kí nìdí? Tó o bá kíyè sí ọ̀rọ̀ táwọn méjèèjì sọ, wàá rí i pé ìwàkíwà tí Jodi hù yẹn kò jẹ́ kí Steve lè fọkàn tán an mọ́, ìyẹn kò sì jẹ́ kí àárín wọn gún régé. Níwọ̀n bó sì ti ṣe pàtàkì pé kí tọkọtaya fọkàn tán ara wọn kí wọ́n lè máa láyọ̀, iṣẹ́ ńlá làwọn méjèèjì ní láti ṣe kí àárín wọn tó lè pa dà gún régé.

Bí ìwọ àti ọkọ rẹ tàbí ìyàwó rẹ bá ń sapá láti má ṣe tú ká lẹ́yìn tí ẹnì kan nínú yín ti ṣe àṣìṣe tó lágbára gan-an, irú bí panṣágà, ó dájú pé ìṣòro kékeré kọ́ lẹ máa dojú kọ. Nǹkan máa kọ́kọ́ nira gan-an fún oṣù mélòó kan lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ náà bá hàn síta. Àmọ́ ẹ lè borí ìṣòro náà! Kí lo lè ṣe tí ọkọ rẹ tàbí ìyàwó rẹ á tún fi lè máa fọkàn tán ẹ? Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì lè ṣèrànwọ́. Gbé àwọn àbá mẹ́rin tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.

1 Ẹ Finú Han Ara Yín. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nísinsìnyí tí ẹ ti fi èké ṣíṣe sílẹ̀, kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.” (Éfésù 4:25) Irọ́ pípa, kéèyàn má sọ òótọ́ délẹ̀délẹ̀, kódà dídákẹ́ láìsọ ohunkóhun pàápàá kì í jẹ́ kí tọkọtaya lè fọkàn tán ara wọn dáadáa. Torí náà, ẹ ní láti máa bá ara yín sọ̀rọ̀ dáadáa, kẹ́ ẹ sì máa finú han ara yín.

Níbẹ̀rẹ̀, inú lè máa bí ẹ̀yin méjèèjì gan-an débi pé ẹ ò ní fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ náà. Àmọ́ tó bá yá, ẹ ṣì ní láti sọ tọkàn yín jáde nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ náà. Ẹ lè má sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ bọ́rọ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀, àmọ́ kò ní bọ́gbọ́n mu pé kẹ́ ẹ pẹ́ ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀ láìsọ. Jodi tá a fa ọ̀rọ̀ ẹ yọ lókè sọ pé: “Ó kọ́kọ́ ń tì mí lára láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mo ṣe, ó sì nira fún mi gan-an. Mo kábàámọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ náà gan-an ni, mi ò sì fẹ́ rántí rẹ̀ mọ́ tàbí sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.” Àmọ́ bí tọkọtaya náà ò ṣe bá ara wọn sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀ dá ìṣòro sílẹ̀. Kí nìdí? Steve sọ pé, “Torí pé Jodi ò fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣe yìí, mi ò yéé fura sí i.” Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Jodi wá sọ pé, “Bí mi ò ṣe fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ náà pẹ̀lú ọkọ mi ò jẹ́ kọ́rọ̀ náà tètè tán nílẹ̀.”

Láìsí àní-àní, ìgbàkígbà tí ọ̀rọ̀ bá kan bí tọkọtaya kan ṣe já ara wọn kulẹ̀, ó máa dùn wọ́n wọra gan-an. Lẹ́yìn tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Paul bá akọ̀wé rẹ̀ níbi iṣẹ́ ṣèṣekúṣe, Debbie ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “Mo ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè láti bi ọkọ mi. Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀? Kí ló sún un débẹ̀? Kí ni wọ́n jọ máa ń sọ? Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn máa ń dà mí lọ́kàn rú, mo máa ń ronú nípa rẹ̀ ní gbogbo ìgbà, oríṣiríṣi ìbéèrè ló sì máa ń wá sọ́kàn mi bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́.” Paul sọ pé: “Nígbà míì, témi àti Debbie bá ń sọ̀rọ̀, ó máa ń di ariwo, ohun tó fà á sì yé mi. Àmọ́, a máa ń tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ara wa tó bá yá. Bí olúkúlùkù wa ṣe sọ tọkàn ẹ̀ jáde yẹn jẹ́ ká túbọ̀ mọ́wọ́ ara wa sí i.”

Kí lo lè ṣe tí ọ̀rọ̀ yìí kò fi ní máa di ariwo ní gbogbo ìgbà? Má gbàgbé pé ṣe lo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ náà, kó o sì wá bí ìgbéyàwó yín ò ṣe ní tú ká, kì í ṣe pé o fẹ́ fìyà jẹ ọkọ ẹ tàbí ìyàwó ẹ tó ṣe panṣágà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Chul Soo ṣe ìṣekúṣe, ìyẹn mú kí òun àti Mi Young, ìyàwó rẹ̀, jọ ronú nípa bí àárín àwọn méjèèjì ṣe rí. Chul Soo sọ pé: “Mo wá rí i pé àwọn nǹkan tara mi ti gbà mí lọ́kàn jù. Bí mo tún ṣe máa tẹ́ àwọn míì lọ́rùn tí màá sì ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́ ló máa ń jẹ mí lógún jù lọ. Àwọn ẹlòmíì ni mo máa ń lo àkókò mi fún jù lọ tí mo sì máa ń ráyè gbọ́ tiwọn. Ìyẹn ló fà á tó fi jẹ́ pé ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ni mo máa ń ní fún ìyàwó mi.” Ohun tí Chul Soo àti Mi Young wá mọ̀ yìí jẹ́ kí wọ́n lè wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó wọn tí wọn ò fi tú ká.

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Tó bá jẹ́ pé ìwọ lẹni tó ṣe ìṣekúṣe, má ṣe máa ṣàwáwí tàbí kó o máa di ẹ̀bi ohun tó ṣẹlẹ̀ náà ru ẹnì kejì rẹ. Gbà pé ìwọ lo jẹ̀bi, àti pé ìwọ lo fa ẹ̀dùn ọkàn fún ẹnì kejì rẹ. Tó bá jẹ́ pé ìwọ lẹni tí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ ṣe ìṣekúṣe, má ṣe jágbe mọ́ ọn, má sì ṣe sọ̀rọ̀ burúkú sí i. Tí o kò bá jágbe mọ́ ọn, tí o kò sì sọ̀rọ̀ burúkú sí i, ìyẹn máa jẹ́ kó lè máa sọ tọkàn rẹ̀ fún ọ.—Éfésù 4:32.

2 Ẹ Jọ Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀. Bíbélì sọ pé: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan.” Kí nìdí? “Nítorí pé wọ́n ní ẹ̀san rere fún iṣẹ́ àṣekára wọn. Nítorí, bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde.” (Oníwàásù 4:9, 10) Ìlànà tó wà nínú Bíbélì yìí máa ń wúlò gan-an nígbà tí tọkọtaya bá ń sapá kí wọ́n lè pa dà máa fọkàn tán ara wọn.

Tẹ́ ẹ bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, ẹ̀yin méjèèjì á lè jọ gbógun ti àìfọkàn-tánra-ẹni tó fẹ́ ba àárín yín jẹ́. Àmọ́, ẹ̀yin méjèèjì lẹ ní láti jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ láti wá nǹkan ṣe kí ìgbéyàwó yín má bàa tú ká. Tẹ́ ẹ bá fẹ́ dá a ṣe lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, ṣe nìyẹn tún máa dá kún ìṣòro tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ẹ ní láti ṣera yín lọ́kan.

Ohun tí Steve àti Jodi rí i pé ó ṣiṣẹ́ fáwọn nìyẹn. Jodi sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó gba àkókò, àmọ́ èmi àti ọkọ mi jọ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ká lè ṣera wa lọ́kàn. Mo pinnu lọ́kàn mi pé mi ò tún ní kó irú ẹ̀dùn ọkàn bẹ́ẹ̀ bá a mọ́ láéláé. Lóòótọ́, ohun tí mo ṣe yẹn ba ọkọ mi nínú jẹ́ gan-an, síbẹ̀ ó pinnu pé òun ò ni jẹ́ kí ìgbéyàwó wa tú ká. Lójoojúmọ́, mo máa ń wá ọ̀nà tí mo lè fi jẹ́ kó mọ̀ pé mi ò tún ní já a kulẹ̀ mọ́, òun náà sì máa ń fìfẹ́ hàn sí mi. Mi ò lè gbàgbé ohun tó ṣe yìí láéláé.”

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ẹ jọ pinnu pé ẹ máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kẹ́ ẹ lè pa dà máa fọkàn tán ara yín.

3 Ẹ Fi Ìwà Tuntun Rọ́pò Ògbólógbòó. Lẹ́yìn tí Jésù ti kìlọ̀ fáwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n ṣọ́ra fún panṣágà, ó wá sọ pé: “Wàyí o, bí ojú ọ̀tún rẹ yẹn bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” (Mátíù 5:27-29) Tó bá jẹ́ pé ìwọ lẹni tó ṣe ìṣekúṣe, ǹjẹ́ o lè ronú kan àwọn ìwà rẹ kan tó o lè ‘yọ jáde, kí o sì sọ ọ́ nù’ torí kí àlàáfíà lè jọba láàárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ?

O gbọ́dọ̀ rí i dájú pé o fòpin sí ohunkóhun tó tún lè pa ìwọ àtẹni tẹ́ ẹ jọ ṣe panṣágà náà pọ̀. * (Òwe 6:32; 1 Kọ́ríńtì 15:33) Paul tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan yí ètò iṣẹ́ rẹ̀ àti nọ́ńbà fóònù rẹ̀ pa dà, ìyẹn ò jẹ́ kí ohunkóhun pa òun àti obìnrin tí wọ́n jọ ṣe panṣágà náà pọ̀ mọ́. Síbẹ̀, gbogbo ohun tó ṣe yẹn ò tíì ní kí òun àti obìnrin yẹn má ṣì máa sọ̀rọ̀ tàbí ríra wọn. Paul pinnu pé gbogbo ohun tó bá gbà ni òun máa fún un kí ìyàwó òun lè pa dà fọkàn tán òun, torí náà, ó fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀. Kò tún lo fóònù rẹ̀ mọ́, òun àti ìyàwó rẹ̀ sì jọ ń lo fóònù kan náà. Ǹjẹ́ gbogbo èyí tiẹ̀ ṣe wọ́n ní àǹfààní kankan? Debbie, ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “Ó ti pé ọdún mẹ́fà báyìí tí ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹlẹ̀, ominú ṣì máa ń kọ mi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé obìnrin náà ṣì lè máa gbìyànjú láti wá a kàn. Àmọ́ mo ti wá jẹ́rìí ọkọ mi pé kò lè gbà kó tún rí òun mú.”

Tó bá jẹ́ pé ìwọ lẹni tó ṣe ìṣekúṣe, ó lè gba pé kó o yí ìwà rẹ pa dà. Bí àpẹẹrẹ, o lè jẹ́ ẹni tó ti mọ́ lára láti máa bá àwọn ọkùnrin tàbí obìnrin tage, tàbí kó o fẹ́ràn láti máa ronú nípa bíbá àwọn ẹlòmíì ṣeré ìfẹ́. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀.” Fi àwọn ìwà tuntun rọ́pò tàtijọ́, kí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ lè túbọ̀ máa fọkàn tán ẹ. (Kólósè 3:9, 10) Ǹjẹ́ bí wọ́n ṣe tọ́ ẹ dàgbà jẹ́ kó ṣòro fún ẹ láti máa fi ìfẹ́ hàn? Kódà, tó bá tiẹ̀ dà bí ohun tí kò kọ́kọ́ bá ẹ lára mu, máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí ìyàwó rẹ, kó o sì máa fi dá a lójú pé irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀ ò ní wáyé mọ́. Steve rántí pé: “Jodi máa ń fìfẹ́ hàn sí mi bó ṣe rọra máa ń fọwọ́ pa mí lára, tó sì máa ń sọ fún mi nígbà gbogbo pé, ‘Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ.’”

Fún àwọn àkókò kan, á dáa kó o máa sọ gbogbo ìrìn rẹ fún ọkọ tàbí ìyàwó rẹ lójoojúmọ́. Mi Young, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ọkọ mi sọ ọ́ di àṣà láti máa sọ gbogbo nǹkan tó bá ṣẹlẹ̀ fún mi lójoojúmọ́, kódà ó máa ń sọ àwọn nǹkan tí kò tiẹ̀ tó nǹkan pàápàá, ó ṣáà fẹ́ kí n mọ̀ pé òun ò fi nǹkan kan pa mọ́ fún mi.”

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ẹ béèrè lọ́wọ́ ara yín ohun tẹ́ ẹ lè ṣe táá jẹ́ kẹ́ ẹ lè pa dà máa fọkàn tán ara yín. Ẹ kọ wọ́n sílẹ̀, kẹ́ ẹ sì máa ṣe wọ́n. Bákan náà, ẹ fi àwọn ohun tẹ́ ẹ lè jọ máa ṣe kún ìgbòkègbodò yín.

4 Ẹ Mọ Ìgbà Tí Ọ̀rọ̀ Náà Bá Ti Tán Nílẹ̀. Ẹ má ṣe yára ronú pé ọ̀rọ̀ náà ti parí nìyẹn, pé ẹ lè jọ máa ṣe bẹ́ ẹ ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ìwé Òwe 21:5 kìlọ̀ pé: “Àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” Ó máa gba ọ̀pọ̀ àkókò, kódà ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún, kí ẹ tó lè pa dà máa fọkàn tán ara yín.

Tó bá jẹ́ pé ìwọ lẹni tí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ ṣe ìṣekúṣe, fara balẹ̀ dáadáa kí ọ̀rọ̀ náà lè tán lọ́kàn rẹ pátápátá. Mi Young sọ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, mo máa ń ronú pé kí ló lè fà á tí ìyàwó kan kò fi ní lè dárí ji ọkọ rẹ̀ tó ṣàṣìṣe? Mi ò mọ ìdí tírú aya bẹ́ẹ̀ á fi bínú lọ rangbọndan fún àkókò gígùn. Àmọ́ nígbà tí ọkọ mi ṣèṣekúṣe, mo wá rí i pé kò rọrùn láti dárí jini lóòótọ́.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ni ẹ ó wá pa dà máa fọkàn tán ara yín, tí ẹ ó sì lè wá dárí ji ara yín.

Ìwé Oníwàásù 3:1-3 sọ pé, “ìgbà mímúláradá” wà. Ó lè kọ́kọ́ ṣe ẹ́ bíi pé ohun tó dáa jù ni pé kó o má ṣe sọ èrò ọkàn rẹ fún ọkọ tàbí ìyàwó rẹ. Àmọ́ tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní jẹ́ kó o lè pa dà máa fọkàn tán ọkọ tàbí ìyàwó rẹ. Kó o lè ṣe àtúnṣe sí àjọṣe yín tó ti bàjẹ́ náà, dárí ji ọkọ tàbí ìyàwó rẹ, kó o sì jẹ́ kó hàn nínú ọ̀rọ̀ rẹ àti bó o ṣe ń ṣe pé o ti dárí jì í. Bákan náà, gba ọkọ tàbí ìyàwó rẹ níyànjú pé kó máa sọ àwọn ohun tó bá múnú rẹ̀ dùn àtàwọn ohun tó bá ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún ẹ.

Má ṣe gbé ohun tó máa mú kínú ẹ túbọ̀ máa bà jẹ́ sọ́kàn. Ṣe ni kó o sapá láti mú un kúrò lọ́kàn. (Éfésù 4:32) Wàá rí i pé ó máa ṣèrànwọ́ tó o bá ronú lórí àpẹẹrẹ ti Ọlọ́run fúnra rẹ̀. Nígbà táwọn olùjọ́sìn Jèhófà ní Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ kọ̀ tí wọn kò jọ́sìn rẹ̀ mọ́, ọ̀rọ̀ náà bà á lọ́kàn jẹ́ gan-an. Jèhófà Ọlọ́run tiẹ̀ fi ara rẹ̀ wé ẹni tí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ lọ ṣe panṣágà. (Jeremáyà 3:8, 9; 9:2) Àmọ́ kò “máa fìbínú hàn fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Jeremáyà 3:12) Nígbà táwọn èèyàn rẹ̀ ronú pìwà dà tọkàntọkàn tí wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó dárí jì wọ́n.

Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, tẹ́yin méjèèjì bá ti gbà pé ẹ ti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ kẹ́ ẹ ṣe sí àjọṣe yín, ọkàn yín á wá balẹ̀, ìyẹn á sì jẹ́ kẹ́ ẹ lè fọkàn tán ara yín. Yóò wá ṣeé ṣe fún yín láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan míì tẹ́ ẹ fẹ́ kọ́wọ́ yín tẹ̀, dípò lílo gbogbo àkókò yín lórí bí ìgbéyàwó yín kò ṣe ní tú ká. Síbẹ̀ náà, kẹ́ ẹ dá àkókò tí ẹ ó fi máa jọ ṣàyẹ̀wò bẹ́ ẹ ti ṣe tẹ̀ síwájú sí. Ẹ má ṣe jẹ́ kí gbogbo nǹkan ṣáà ti máa dá a lójú yín. Ẹ wá nǹkan ṣe sí àwọn nǹkan kéékèèké tó lè fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀, kẹ́ ẹ sì máa fi dá ara yín lójú pé ẹ ò ní já ara yín kulẹ̀.—Gálátíà 6:9.

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Dípò tí ẹ ó fi máa wá bẹ́ ẹ ṣe máa jẹ́ kí ìgbéyàwó yín pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, ṣe ni kẹ́ ẹ máa wo ara yín bí ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àjọṣe tuntun tó máa lágbára.

Ẹ Lè Ṣàṣeyọrí

Láwọn ìgbà míì tó bá ń ṣe yín bíi pé ẹ ò lè ṣàṣeyọrí, ẹ máa rántí kókó yìí pé: Ọlọrun ni Olùdásílẹ̀ ètò ìgbéyàwó. (Mátíù 19:4-6) Nítorí náà, lọ́lá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, ẹ lè ṣàṣeyọrí gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya. Gbogbo àwọn tọkọtaya tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú àpilẹ̀kọ yìí ni wọ́n tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì, wọ́n sì ṣe ohun tí kò jẹ́ kí ìgbéyàwó wọn tú ká.

Ó ti lé lógún ọdún tí ìṣòro tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé Steve àti Jodi ti wáyé báyìí. Steve sọ ohun táwọn ṣe láti mú kí àárín àwọn pa dà gún régé, ó ní: “Ìgbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la ṣe àwọn àtúnṣe pàtàkì tó ràn wá lọ́wọ́. Ìrànlọ́wọ́ tá a rí gbà ò ṣeé fowó rà. Òun ló jẹ́ ká lè fara da gbogbo àkókò tí àárín wa gbóná girigiri.” Jodi sọ pé: “Ayọ̀ mi kún gan-an pé a lè fara da àkókò tó le koko yẹn. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a jọ ń ṣe àti ìsapá gidi tá a ṣe ti wá jẹ́ ká lè mọwọ́ ara wa gan-an báyìí.”

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.

^ Tó o bá fẹ́ ìrànlọ́wọ́ lórí bó o ṣe máa ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀, wo Jí! May 8, 1999, ojú ìwé 6 àti August 8, 1995, ojú ìwé 10 àti 11.

^ Tó bá ṣẹlẹ̀ pé fún àwọn àkókò kan, ó di dandan kó o fojú kan ẹni náà (bóyá níbi iṣẹ́), a jẹ́ pé ó gbọ́dọ̀ jẹ́ torí ohun tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Jẹ́ kí àwọn èèyàn wà níbẹ̀ tí nǹkan kan bá máa dà yín pọ̀, kó o sì jẹ́ kí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ mọ gbogbo bí nǹkan bá ṣe ń lọ.

BI ARA RẸ PÉ . . .

▪ Kí nìdí tí mo fi pinnu pé mi ò ní kọ ọkọ tàbí ìyàwó mi sílẹ̀ láìka ìṣekúṣe tó wáyé sí?

▪ Àwọn ìwà dáadáa wo ni mo ń rí lára ọkọ tàbí ìyàwó mi báyìí?

▪ Àwọn nǹkan wo ni mo ṣe láti jẹ́ kí ọkọ tàbí ìyàwó mi mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ òun nígbà tá a ṣì ń fẹ́ ara wa sọ́nà, báwo ni mo tún ṣe lè máa ṣe àwọn nǹkan yẹn pa dà?