Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ TÓ DÁ LÓRÍ ÀKÒRÍ Ẹ̀YÌN ÌWÉ

Ọ̀rọ̀ Pàtàkì Fún Àwọn Tó Fẹ́ Ṣí Lọ sí Ìlú Míì

Ọ̀rọ̀ Pàtàkì Fún Àwọn Tó Fẹ́ Ṣí Lọ sí Ìlú Míì

Wọ́n Ń Fẹ́ Kí Nǹkan Ṣẹnuure

NǸKAN tojú sú ọkùnrin kan tó ń jẹ́ George. Ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ kò rí oúnjẹ jẹ. Àwọn èèyàn ń ṣàìsàn lọ́tùn-ún lósì, ebi sì ń pa àwọn kan kú lọ. Àmọ́ orílẹ̀-èdè kan tí nǹkan ti lè ṣẹnuure ò jìnnà púpọ̀ sí ìlú ibi tí George ń gbé. Ìyẹn ló mú kí George ronú pé òun á kúkú ṣí lọ síbẹ̀, òun á wá iṣẹ́ ajé ṣe níbẹ̀, tó bá sì yá, ìyàwó àtàwọn ọmọ òun náà á wá bá òun lọ́hùn-ún.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Patricia náà fẹ́ ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti máa ṣẹnuure fún un. Kò níṣẹ́ lọ́wọ́, kò sì dájú pé ó máa rí tajé ṣe níbi tó wà. Ni Patricia àti ọkùnrin tí wọ́n jọ ń fẹ́ra bá pinnu pé àwọn máa lọ sí orílẹ̀-èdè Sípéènì. Wọ́n gbéra láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, wọ́n sì fẹ́ gba orílẹ̀-èdè Algeria kọjá. Àmọ́ wọn kò mọ̀ pé ìrìn-àjò yẹn kò ní rọrùn rárá nínú Aṣálẹ̀ Sàhárà tí wọ́n fẹ́ gbà kọjá. Patricia sọ pé: “Mo wà nínú oyún nígbà yẹn, àmọ́ mo pinnu pé ìgbé ayé ìdẹ̀rùn ni mo fẹ́ fún ọmọ tí mo fẹ́ bí.”

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Rachel wá bó ṣe máa rí tajé ṣe lọ sí ilẹ̀ Yúróòpù. Iṣẹ́ ti bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́ nílẹ̀ Philippines, àmọ́ àwọn ìbátan rẹ̀ sọ fún un pé iṣẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ tó máa mówó wọlé pọ̀ lórílẹ̀-èdè míì. Ni Rachel bá lọ yá owó tó máa fi wọ ọkọ̀ òfuurufú, ó sì fi ọkọ rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ obìnrin sílẹ̀. Ó ṣèlérí fún wọn pé: “A máa ríra láìpẹ́.”

Àwọn kan fojú bù ú pé àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún méjì mílíọ̀nù ló ti ṣí láti orílẹ̀-èdè kan lọ sí ibòmíì bíi ti George, Patricia àti Rachel láàárín ohun tó lé ní ogún ọdún sẹ́yìn. Òótọ́ ni pé ogun, ìṣẹ̀lẹ̀ àdánidá tàbí ìwà ìkà tí àwọn kan hù ló máa ń mú káwọn èèyàn kan ṣí kúrò nílùú, síbẹ̀, ipò ọrọ̀ ajé ló ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣí lọ sí ìlú míì. Àwọn ìṣòrò wo làwọn tó ṣí lọ sí ìlú míì máa ń ní tí wọ́n bá dé ibi tí wọ́n ń lọ? Ṣé lóòótọ́ ni wọ́n máa ń rí ohun tí wọ́n ń wá? Báwo ni nǹkan ṣe máa ń rí fún àwọn ọmọ tí àwọn òbí bá fi wọ́n sílẹ̀ torí pé wọ́n fẹ́ wáṣẹ́ gidi lọ sí ìlú míì? Wo bí àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

Bí Wọ́n Ṣe Máa Débẹ̀ Àti Bí Wọ́n Ṣe Máa Gbọ́ Bùkátà

Ìṣòro àkọ́kọ́ táwọn tó ń ṣí lọ sí ibòmíì máa ń ní ni bí wọ́n ṣe máa dé ibi tí wọ́n ń lọ. George, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú rìnrìn àjò ọ̀pọ̀ kìlómítà láìsí oúnjẹ. Ó sọ pé: “Ohun tójú rí, ẹnu ò lè ròyìn ẹ̀ tán.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í lè dé ibi tí wọ́n ń lọ.

Orílẹ̀-èdè Sípéènì ni Patricia fẹ́ lọ. Ọkọ̀ akẹ́rù kan tí kò nílé lórí ló wọ̀ gba Aṣálẹ̀ Sàhárà kọjá. Ó sọ pé: “Ọ̀sẹ̀ kan gbáko la fi rìnrìn àjò láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ sí Algeria. Àwa mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] la rún ara wa mọ́ ẹ̀yìn ọkọ̀ yẹn. Bá a ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, àìmọye òkú àwọn èèyàn la rí nílẹ̀ káàkiri àtàwọn míì tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ́mìí mì. Ẹ̀rí fi hàn pé ṣe làwọn kan lára àwọn awakọ̀ yẹn kàn máa ń já àwọn èèyàn jù sílẹ̀ lójú ọ̀nà, tí wọ́n á sì máa bá tiwọn lọ.”

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Rachel yàtọ̀ sí ti George àti Patricia. Ó wọkọ̀ òfuurufú lọ sí ilẹ̀ Yúróòpù, ó sì rí iṣẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ ṣe. Àmọ́ kò tiẹ̀ ṣèèṣì ronú pé àárò ọmọ òun tó jẹ́ ọmọ ọdún méjì ṣì máa sọ òun. Ó sọ pé: “Ṣe ni inú mi máa ń bà jẹ́ tí mo bá rí abiyamọ tó ń tọ́jú ọmọ rẹ̀.”

Ibi tí George ṣí lọ kò tètè mọ́ ọn lára. Ọ̀pọ̀ oṣù ti kọjá kó tó lè rí owó fi ránṣẹ́ sílé. Ó sọ pé: “Àìmọye ìgbà ni mo máa ń bú sẹ́kún lóru torí pé nǹkan ò rí bí mo ṣe rò, mi ò sì ní alábàárò kankan.”

Lẹ́yìn tí Patricia ti lo ọ̀pọ̀ oṣù ní orílẹ̀-èdè Algeria, ó dé ẹnubodè orílẹ̀-èdè Mòrókò. Ó sọ pé: “Ìtòsí ẹnubodè orílẹ̀-èdè Mòrókò àti Algeria ni mo bí ọmọ mi sí. Ṣe ni mo sá pa mọ́ fún àwọn tó máa ń fipá mú àwọn obìnrin tó bá wá láti ìlú míì kí wọ́n lè lọ fi wọ́n ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó. Nígbà tó yá, mo rí owó láti fi wọ ọkọ̀ òkun kọjá lọ sí orílẹ̀-èdè Sípéènì. Ìrìn-àjò orí omi yẹn léwu gan-an ni. Ọkọ̀ ojú omi hẹ́gẹhẹ̀gẹ kan báyìí la wọ̀. Iye àwa tá a wọ ọkọ̀ náà sì pọ̀ ju iye tó lágbára láti gbé lọ. Bàtà ẹsẹ̀ wa la fi ń gbọ́n omi kúrò nínú ọkọ̀ ọ̀hún! Nígbà tá a dé etíkun ilẹ̀ Sípéènì, mi ò lágbára láti sọ̀ kalẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ náà.”

Ó yẹ kí àwọn tó fẹ́ ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè míì máa rò ó dáadáa, kí wọ́n ronú lórí gbogbo ewu tó ṣeé ṣe kí wọ́n dojú kọ lẹ́nu ìrìn-àjò yẹn. Wọ́n tún ní láti ronú nípa bó ṣe lè ṣòro tó láti kọ́ èdè àti àṣà àwọn èèyàn ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń lọ àti ohun tó máa ná wọn láti di ojúlówó ọmọ onílùú tàbí ẹni tí òfin gbà láyè láti máa gbé ìlú náà. Ó máa ń ṣòro fún àwọn tí kò bá ní ìwé àṣẹ ọmọ onílùú láti rí iṣẹ́ tó dáa, ilé tó dùn-ún gbé, ètò ẹ̀kọ́ tó jíire títí kan ètò ìlera tó yẹ. Ó tún lè ṣòro fún wọn láti rí ìwé àṣẹ ìwakọ̀ gbà tàbí láti ṣí àkáǹtì sí báńkì. Ohun tó wá burú jù ni pé ìlòkulò làwọn agbanisíṣẹ́ máa ń lo àwọn tí kò bá ní ìwé àṣẹ ọmọ onílùú. Àwọn èèyàn sì máa ń rẹ́ wọn jẹ láwọn ọ̀nà míì.

Nǹkan míì tó tún yẹ kí wọ́n rò dáadáa ni ọ̀rọ̀ nípa owó. Ṣé lóòótọ́ ni owó lè fún wa ní gbogbo ohun tí à ń fẹ́ láyé? Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Má ṣe làálàá àtilọ́rọ̀: ṣíwọ́ kúrò nínú òye ara rẹ. Ìwọ ó ha fi ojú rẹ wò ó? Kì yóò sì sí mọ́, nítorí tí ọrọ̀ hu ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀ bí idì tí n fò ní ojú ọ̀run.” (Òwe 23:4, 5, Bíbélì Mímọ́) Má ṣe gbàgbé pé àwọn ohun tí kò ṣeé fowó rà làwa èèyàn nílò jù, irú bí ìfẹ́, ìbàlẹ̀ ọkàn àti ìdílé tó wà níṣọ̀kan. Kì í ṣe ohun tó dáa tí tọkọtaya bá jẹ́ kí ìlépa owó ṣe pàtàkì sí wọn ju ìfẹ́ tó yẹ kí wọ́n ní sí ara wọn lọ títí kan ìfẹ́ tó yẹ kí wọ́n ní sí àwọn ọmọ wọn!—2 Tímótì 3:1-3.

Ohun míì táwa èèyàn tún nílò ni bá a ṣe fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run. (Mátíù 5:3) Torí náà, àwọn òbí tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ máa ń sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè ṣe ojúṣe wọn láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìlànà Ọlọ́run. Wọ́n á jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún àwa èèyàn àti bí wọ́n ṣe máa sún mọ́ Ọlọ́run.—Éfésù 6:4.

Ìdílé Tó Wà Ní Ìṣọ̀kan Kò Ṣeé Fowó Rà

Lóòótọ́, nǹkan ò rí bákan náà fún gbogbo ẹni tó ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè míì, síbẹ̀ ohun kan náà sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn. Ohun tá a kà nípa George, Rachel àti Patricia nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú fi hàn pé nǹkan kì í rọrùn rárá fáwọn ọmọ tí òbí wọn bá fi sílẹ̀ tàbí fún àwọn ọkọ tàbí aya tí ẹnì kejì wọn bá fi sílẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀ ọdún sì lè ti kọjá kí wọ́n tó lè pa dà máa gbé pọ̀. Ní ti ìdílé George, ó tó ọdún mẹ́rin kí wọ́n tó lè pa dà máa gbé pọ̀.

Nǹkan bí ọdún márùn-ún ni Rachel lò kó tó pa dà sí orílẹ̀-èdè Philippines láti lọ mú ọmọbìnrin rẹ̀. Patricia àti ọmọ ìkókó rẹ̀ tó gbé dání ló jọ wọ orílẹ̀-èdè Sípéènì. Ó sọ pé: “Ọmọ yìí nìkan lẹni tí mo ní, torí náà gbogbo ohun tí mo ní ni mo fi ń tọ́jú rẹ̀.”

Àwọn kan lára àwọn tí wọ́n ṣí lọ sí ìlú míì máa ń ta kú síbi tí wọ́n wà, tí wọn ò sì ní fẹ́ pa dà sílé láìka ìdánìkanwà, àìlówó lọ́wọ́ àti bí àárò ilé ṣe ń sọ wọ́n sí. Wọ́n ti ṣe wàhálà púpọ̀, wọ́n sì ti náwó nára láti débi tí wọ́n dé yìí. Torí náà, tí nǹkan ò bá tiẹ̀ jọra wọn mọ́, kì í ṣe gbogbo wọn ló máa ń fẹ́ gba kámú kí wọ́n sì pa da sílé. Ó máa ń tì wọ́n lójú, wọ́n sì máa ń ronú pé àwọ́n kàn máa lọ fi ara àwọn wọ́lẹ̀ ni.

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Allan ṣọkàn akin, ó sì pa dà sílé nílẹ̀ Philippines nígbà tí nǹkan kò lọ déédéé fún un mọ́ nílẹ̀ òkèèrè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó rí iṣẹ́ gidi sí orílẹ̀-èdè Sípéènì, kò ju ọdún kan àtààbọ̀ lọ tó fi pa dà sílé. Ó sọ pé: “Àárò ìyàwó àti ọmọ mi ń sọ mí gan-an. Mo bá pinnu pé mi ò ní dá lọ ṣiṣẹ́ nílẹ̀ òkèèrè mọ́, àyàfi tí ìyàwó àtàwọn ọmọ mi bá tẹ̀ lé mi lọ. Ohun tá a sì ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ó ṣe tán, ohun a ní là á náání, ìdílé ẹni kò ṣeé fowó rà.”

Patricia náà gbà pé ohun kan tún wà tó ṣe pàtàkì ju owó lọ. Ó mú “Bíbélì Májẹ̀mú Tuntun” dáni lọ sí orílẹ̀-èdè Sípéènì torí ó rò pé oògùn ajẹ́bíidán ni. Ó sọ pé: “Mo pàdé obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan. Bẹ́ẹ̀ sì rèé mi kì í gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn tẹ́lẹ̀. Torí náà, mo da ìbéèrè bo obìnrin yìí kí n lè fi hàn án pé irọ́ làwọn ohun tó gbà gbọ́. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bí mo ṣe rò. Gbogbo ìbéèrè tí mo bi í pátá ló fi Bíbélì dáhùn lọ́kọ̀ọ̀kan.”

Ohun tí Patricia kọ́ látinú Bíbélì jẹ́ kó wá gbà pé ìlú ibi téèyàn ń gbé tàbí bí èèyàn ṣe lówó tó kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ayọ̀ tó máa wà pẹ́ títí àti ìrètí ọjọ́ ọ̀la. Kàkà bẹ́ẹ̀, ojúlówó ìmọ̀ nípa Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé ló lè fúnni láyọ̀ tó máa wà pẹ́ títí. (Jòhánù 17:3) Lára ohun tí Patricia kọ́ ni pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ó tún kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì pé Ọlọ́run ò ní pẹ́ lo Ìjọba rẹ̀ láti fòpin sí ipò òṣì, Jésù Kristi ló sì máa jẹ́ ọba ìjọba náà. (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Abájọ tí Sáàmù 72:12, 14 fi sọ pé: “[Jésù] yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.”

Ìwọ náà ò ṣe fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí? Ìwé ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run yìí máa jẹ́ kó o mọ ohun tó yẹ kó o kà sí pàtàkì jù ní ìgbésí ayé rẹ, kó o lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Kó o sì lè máa fara da àwọn ìṣòro tó o bá ní, pẹ̀lú ìrètí àti ìdùnnú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.—Òwe 2:6-9, 20, 21.