Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | TỌKỌTAYA

Bí Ẹ Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Bíbá Ara Yín Jiyàn

Bí Ẹ Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Bíbá Ara Yín Jiyàn

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Ṣé ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ kì í lè fi sùúrù bá ara yín sọ̀rọ̀? Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé àdó olóró fẹ́ bú gbàù nígbà tí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ bá jọ ń sọ̀rọ̀?

Tó bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó bà ni, kò tíì bà jẹ́. O gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ohun tó fà á tí ẹ̀yin méjèèjì fi máa ń bára yín jiyàn tó bẹ́ẹ̀.

OHUN TÓ FÀ Á

Àìgbọ́ra-ẹni-yé.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Jillian * sọ pé: “Nígbà míì, tí n bá fẹ́ bá ọkọ mi sọ̀rọ̀, màá ti sọ̀rọ̀ yẹn tán kí n tó wá rí i pé kì í ṣe ohun tí mo ní lọ́kàn ni mo sọ yẹn. Nígbà míì, mo tún lè rò pé mo ti sọ nǹkan kan fún ọkọ mi, láìmọ̀ pé mi ò tiẹ̀ tí ì sọ ọ́ rárá. Ìyẹn ti ṣẹlẹ̀ sí mi láìmọye ìgbà!”

Èrò tó yàtọ̀ síra.

Kò sí bí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ ṣe lè mọwọ́ ara yín tó, èrò yín ò lè máa fìgbà gbogbo dọ́gba. Ìdí ni pé ẹni méjì ò lè rí bákan náà délẹ̀délẹ̀, ó ṣe tán, ahọ́n àti eyín pàápàá máa ń jà. Ìyàtọ̀ tó wà láàárín yín lè pa kún adùn ìgbéyàwó tàbí kó fa ìṣòro. Ó ṣeni láàánú pé awuyewuye lọ̀rọ̀ yìí máa ń dá sílẹ̀ láàárín ọ̀pọ̀ tọkọtaya.

Àwòkọ́ṣe tí kò sunwọ̀n.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Rachel sọ pé: “Àwọn òbí mi máa ń bára wọn jiyàn gan-an, wọ́n sì máa ń sọ òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn. Nígbà témi náà lọ́kọ, kàkà kí n máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ mi, ṣe ni mo máa ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ lù ú bíi ti ìyá mi.”

Ohun tó wà lẹ́yìn ọ̀rọ̀ náà.

Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í ṣe ohun tí ẹ̀ ń bá ara yín jiyàn lé lórí ló fa wàhálà. Bí àpẹẹrẹ, àríyànjiyàn lè bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ọkọ jágbe mọ́ aya rẹ̀ pé: “Gbogbo ìgbà lo máa ń pẹ́!” Àmọ́ ó lè máà jẹ́ torí pé aya rẹ̀ pẹ́ ni àríyànjiyàn ṣe bẹ́ sílẹ̀. Ó lè jẹ́ torí pé ẹnì kan nínú àwọn méjèèjì rò pé ẹnì kejì kò ka òun kún.

Ohun yòówù kó fa àríyànjiyàn yín, tẹ́ ẹ bá ń bá ara yín fa ọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́, ó lè ṣàkóbá fún ìlera rẹ. Ó sì lè yọrí sí ìkọ̀sílẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Kí wá lọ̀nà àbáyọ?

OHUN TẸ́ Ẹ LÈ ṢE

Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kéèyàn kọ́kọ́ mọ ohun tó fa àríyànjiyàn yẹn gan-an. Tí gbogbo nǹkan bá ti rọlẹ̀, àwọn ohun tẹ́ ẹ lè ṣe nìyí.

1. Kí ẹ̀yin méjèèjì mú abala ìwé kọ̀ọ̀kan, kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín sì kọ ohun tẹ́ ẹ jiyàn lé lórí lẹ́nu àìpẹ́ yìí sínú ìwé tirẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ lè kọ ọ́ sínú ìwé tirẹ̀ pé: “O kàn bá àwọn ọ̀rẹ́ ẹ jáde láìjẹ́ kí n mọ ibi tó o wà.” Aya lè kọ ọ́ sínú ìwé tirẹ̀ pé: “Ò ń bínú torí pé mo bá àwọn ọ̀rẹ́ mi jáde.”

2. Láì fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ẹ jọ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn tiẹ̀ le tó bí a ṣe mú un? Ǹjẹ́ kò ní dáa ká ní mo ti gbójú fo ọ̀rọ̀ náà dá, tí mo sì gbàgbé rẹ̀? Kí àlàáfíà lè jọba, lọ́pọ̀ ìgbà, ó lè jẹ́ ohun tó máa dáa jù ni pé kí ẹ̀yin méjèèjì gbà pé èrò yín ni kò dọ́gba, kẹ́ ẹ sì jọ fìfẹ́ parí ọ̀rọ̀ náà.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 17:9.

Tí ẹ̀yin méjèèjì bá gbà pé nǹkan kékeré lọ̀rọ̀ náà, ẹ tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ara yín, kẹ́ ẹ sì jọ gbàgbé ọ̀rọ̀ náà.—Ìlànà Bíbélì: Kólósè 3:13, 14.

Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ẹnì kan nínú yín tàbí ẹ̀yin méjèèjì ka ọ̀rọ̀ náà sí ohun tó le, ohun tẹ́ ẹ lè ṣe rèé.

3. Kí ẹ̀yin méjèèjì kọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára yín nígbà tí àríyànjiyàn yẹn wáyé sínú ìwé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ọkọ lè sọ nípa aya rẹ̀ pé: “Ó dà bíi pé o fẹ́ràn kó o máa bá àwọn ọ̀rẹ́ ẹ jáde ju kó o máa wà lọ́dọ̀ mi lọ.” Aya lè sọ nípa ọkọ rẹ̀ pé: “Ó ń ṣe mí bíi pé o kà mí sí aròbó tó gbọ́dọ̀ gbàṣẹ lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀ kó tó ṣe ohunkóhun.”

4. Ẹ fi ohun tí ẹ̀yin méjèèjì kọ sínú ìwé han ara yín, kẹ́ ẹ sì kà á. Kí lohun tó ń jẹ ọkọ tàbí aya rẹ lọ́kàn gan-an nígbà tí ẹ̀ ń bá ara yín fa ọ̀rọ̀ yẹn? Ẹ jọ jíròrò ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ì bá ti ṣe kí ọ̀rọ̀ yẹn lè parí láìfa àríyànjiyàn.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 29:11.

5. Ẹ jọ jíròrò ohun tẹ́ ẹ kọ́ nínú àwọn ìgbésẹ̀ tẹ́ ẹ gbé yìí. Tí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ bá tún wáyé, báwo lẹ ṣe lè fi ohun tẹ́ ẹ kọ́ yanjú ẹ̀ tàbí kí lẹ máa ṣe kí irú ẹ̀ má bàa wáyé nígbà míì?

^ ìpínrọ̀ 7 A ti yí àwọn orúkọ yìí pa dà.