Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LIBRARY

Wo Àwọn Ohun Tó O Ti Kà Tẹ́lẹ̀​—Lórí Windows

Wo Àwọn Ohun Tó O Ti Kà Tẹ́lẹ̀​—Lórí Windows

JW Library máa ń tọ́jú ìsọfúnni nípa àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn orí Bíbélì tó o ti kà. Ó máa wúlò, bí àpẹẹrẹ, tó o bá fẹ́ pa dà lọ ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó o ti kà tẹ́lẹ̀.

Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè wo àwọn ohun tó o ti kà tẹ́lẹ̀:

 Pa Dà sí Ìwé Tó O Ti Kà Tẹ́lẹ̀

Ṣí àpótí App Commands bar, kó o wá tẹ History kó o lè rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tàbí àpilẹ̀kọ tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà. Tó bá ti gbé wọn wá, tẹ èyí tó o fẹ́, á gbé ẹ pa dà sí ẹsẹ yẹn nínú Bíbélì tàbí inú àpilẹ̀kọ náà gangan.

 Pa Ìsọfúnni Nípa Ohun Tó O Ti Kà Tẹ́lẹ̀ Rẹ́

Tẹ bótìnì apá ọ̀tún lórí mouse rẹ tàbí kó o fìka fa ojú fóònù ẹ wálẹ̀ látòkè kó o lè ṣí àpótí App commands. Tẹ History kó o lè rí àwọn ohun tó o ti kà tẹ́lẹ̀. Wá tẹ Clear kó o lè pa gbogbo ẹ̀ rẹ́.

March 2014 la gbé àwọn àtúnṣe yìí jáde, ó bá JW Library 1.1 wá. Ó máa ṣiṣẹ́ lórí Windows 8.0 sókè. Tó ò bá rí i lórí fóònù ẹ, jọ̀ọ́ tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú àpilẹ̀kọ “Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library​—Lórí Windows,” lábẹ́ Rí Àwọn Ohun Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé.