Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LIBRARY

Wo Àwọn Ohun Tó O Ti Kà Tẹ́lẹ̀​—Lórí iOS

Wo Àwọn Ohun Tó O Ti Kà Tẹ́lẹ̀​—Lórí iOS

JW Library máa ń tọ́jú ìsọfúnni nípa àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn orí Bíbélì tó o ti kà. Ó máa wúlò, bí àpẹẹrẹ, tó o bá fẹ́ pa dà lọ ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó o ti kà tẹ́lẹ̀.

Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè wo àwọn ohun tó o ti kà tẹ́lẹ̀:

 Pa Dà sí Ìwé Tó O Ti Kà Tẹ́lẹ̀

Fìka tẹ Bible mọ́lẹ̀ fún bí ìṣẹ́jú àáyá mélòó kan kó o lè rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà. Tó bá ti gbé wọn wá, tẹ èyí tó o fẹ́, á gbé ẹ pa dà sí ẹsẹ yẹn nínú Bíbélì gangan.

Fìka tẹ Publications mọ́lẹ̀ fún bí ìṣẹ́jú àáyá mélòó kan kó o lè rí àwọn àpilẹ̀kọ tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà nínú gbogbo ìwé tó wà. Wá yan àpilẹ̀kọ tó o fẹ́ kó o lè pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í kà á.

 Pa Ìsọfúnni Nípa Ohun Tó O Ti Kà Tẹ́lẹ̀ Rẹ́

Fìka tẹ Bible tàbí Publications mọ́lẹ̀ fún bí ìṣẹ́jú àáyá mélòó kan kó o lè rí àwọn ohun tó o ti kà tẹ́lẹ̀. Wá tẹ Clear kó o lè pa gbogbo ẹ̀ rẹ́.

May 2014 la gbé àwọn àtúnṣe yìí jáde, ó bá JW Library 1.2 wá. Ó máa ṣiṣẹ́ lórí iOS 6.0 sókè. Tó ò bá rí i lórí fóònù ẹ, jọ̀ọ́ tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú àpilẹ̀kọ “Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library​—Lórí iOS,” lábẹ́ Rí Àwọn Ohun Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé.