Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LIBRARY

Bó O Ṣe Lè Kun Ọ̀rọ̀​—Lórí iOS

Bó O Ṣe Lè Kun Ọ̀rọ̀​—Lórí iOS

Bó o ṣe ń kàwé, tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ lórí JW Library, ó lè máa kún ọ̀rọ̀.

Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè máa kun ọ̀rọ̀:

 Kun Ọ̀rọ̀

Ọ̀nà méjì lo lè gbà kun ọ̀rọ̀.

Fìka tẹ ọ̀rọ̀ kan mọ́lẹ̀ fún ìṣẹ́jú àáyá mélòó kan. Ó máa gbé igi sí ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ọ̀rọ̀ náà. O lè fa igi náà sọ́tùn-ún tàbí sósì kó lè mú àwọn ọ̀rọ̀ míì mọ́ ọn. Nínú àpótí tó bá hàn lókè, wá tẹ bọ́tìnì Highlight, kó o sì yan kọ́lọ̀ tó o máa fẹ́ kó fi kun ọ̀rọ̀ náà.

Ọ̀nà míì ni pé kó o fìka tẹ ọ̀rọ̀ kan mọ́lẹ̀ fún ìṣẹ́jú àáyá mélòó kan, kó o wá fa ìka ẹ sọ́tùn-ún. Bó o ṣe ń fà á lo láá máa kun àwọn ọ̀rọ̀ tó o fa ìka kọjá lórí ẹ̀. Tó o bá ti fà á débi tó o fẹ́, àpótí kan máa hàn lókè. O lè yí kọ́lọ̀ tó o fi kun ọ̀rọ̀ náà pa dà níbẹ̀, tàbí kó o pa á rẹ́.

 Yí Ohun Tó O Kùn Pa Dà

Tó o bá fẹ́ yí kọ́lọ̀ tó o fi kun ọ̀rọ̀ pa dà, tẹ ọ̀rọ̀ tó o ti kùn tẹ́lẹ̀ yẹn, kó o wá yan kọ́lọ̀ míì tó o fẹ́. Tó o bá fẹ́ yọ ọ́ kúrò, tẹ ohun tó o kùn, kó o wá tẹ Delete.

November 2015 la gbé àwọn àtúnṣe yìí jáde, ó bá JW Library 1.6 wá. Ó máa ṣiṣẹ́ lórí iOS 7.0 sókè. Tó ò bá rí i lórí fóònù ẹ, jọ̀ọ́ tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú àpilẹ̀kọ “Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library​—Lórí iOS,” lábẹ́Rí Àwọn Ohun Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé.