Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LIBRARY

Ohun Tó Wà Lórí JW Library

Ohun Tó Wà Lórí JW Library

Lílo Bíbélì

  • Yan ọ̀kan nínú oríṣiríṣi ìtumọ̀ Bíbélì tó wà níbẹ̀.

  • Tó o bá tẹ nọ́ńbà tó wà níwájú ẹsẹ Bíbélì kan, wàá lè fi gbogbo ìtumọ̀ Bíbélì tó wà wéra.

  • Tó o bá tẹ àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tàbí atọ́ka tó wà lórí ẹsẹ Bíbélì kan, wàá rí àwọn ìsọfúnni tó bá a rìn.

 

Bí Wàá Ṣe Máa Lò Ó

  • Tó o bá ṣí ìwé kan, fi ìka fa ojú fóònù ẹ sápá ọ̀tún tàbí sápá òsì bí ẹni ṣí ìwé, kó o lè rí ojú ìwé tó kàn tàbí èyí tó ṣáájú.

  • Sàmì sí ẹsẹ Bíbélì tàbí orí Bíbélì tó o bá ń kà lọ́wọ́, kó o lè pa dà bẹ̀rẹ̀ níbi tó o dé.

  • Lọ sí apá tá a pè ní history kó o lè rí àwọn ìwé tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán.

  • Fi apá tá a pè ní Search wá ọ̀rọ̀ nínú ìwé tó ò ń kà lọ́wọ́.

  • Wo àwọn ìwé tí wàá lò nípàdé.