Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LIBRARY

Wo Àwọn Ohun Tó O Ti Kà Tẹ́lẹ̀​—Lórí Android

Wo Àwọn Ohun Tó O Ti Kà Tẹ́lẹ̀​—Lórí Android

JW Library máa ń tọ́jú ìsọfúnni nípa àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn orí Bíbélì tó o ti kà. Ó máa wúlò, bí àpẹẹrẹ, tó o bá fẹ́ pa dà lọ ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó o ti kà tẹ́lẹ̀.

Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè wo àwọn ohun tó o ti kà tẹ́lẹ̀:

 Pa Dà sí Ìwé Tó O Ti Kà Tẹ́lẹ̀

Tẹ bọ́tìnì History kó o lè rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àtàwọn àpilẹ̀kọ tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà. Tó o bá tẹ ọ̀kan lára wọn, ó máa gbé ẹ pa dà sínú Bíbélì tàbí àpilẹ̀kọ yẹn gangan.

 Pa Ìsọfúnni Nípa Ohun Tó O Ti Kà Tẹ́lẹ̀ Rẹ́

Tẹ bọ́tìnì History kó o lè rí àwọn ohun tó o ti kà tẹ́lẹ̀. Wá tẹ Clear kó o lè pa gbogbo ẹ̀ rẹ́.

May 2014 la gbé àwọn àtúnṣe yìí jáde, ó bá JW Library 1.2 wá. Ó máa ṣiṣẹ́ lórí Android 2.3 sókè. Tó ò bá rí i lórí fóònù ẹ, jọ̀ọ́ tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú àpilẹ̀kọ “Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library​—Lórí Android,” lábẹ́ Rí Àwọn Ohun Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé.