Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́ Lórí Ọ̀rọ̀ Ìsìnkú?

Kí Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́ Lórí Ọ̀rọ̀ Ìsìnkú?

 Tó bá dọ̀rọ̀ ìsìnkú, ohun tó wà nínú Bíbélì la máa ń tẹ̀ lé. Àwọn àpẹẹrẹ kan nìyí:

  •   Kò sóhun tó burú nínú ká ṣọ̀fọ̀ tẹ́ni tá a fẹ́ràn bá kú. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣọ̀fọ̀ nígbà táwọn ọ̀rẹ́ wọn kú. (Jòhánù 11:33-​35, 38; Ìṣe 8:2; 9:​39) Torí náà, a kì í ṣe àríyá níbi ìsìnkú. (Oníwàásù 3:​1, 4; 7:​1-4) Àsìkò téèyàn máa ń káàánú àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ la kà á sí.​—Róòmù 12:15.

  •   Àwọn òkú ò mọ nǹkan kan. Bíbélì ò fi kọ́ni pé àwọn òkú mọ nǹkan kan tàbí pé wọ́n lè ṣe ohunkóhun fáwọn alààyè. Torí náà, láìka ohun táwọn èèyàn ń ṣe níbi tá a ti wá tàbí tí wọ́n ti tọ́ wa dàgbà sí, a kì í lọ́wọ́ sí àwọn àṣà tó bá dá lé irú nǹkan bẹ́ẹ̀. (Oníwàásù 9:​5, 6, 10) Àwọn àpẹẹrẹ kan ni àìsùn òkú, ayẹyẹ ìsìnkú aláriwo àti ìrántí olóògbé, ètùtù òkú, kéèyàn máa bá òkú sọ̀rọ̀ tàbí kó máa wádìí lọ́dọ̀ òkú àti ààtò ilé opó. A kì í lọ́wọ́ sí gbogbo àṣà yìí torí pé a fẹ́ tẹ̀ lé àṣẹ tí Bíbélì pa pé: “Ẹ . . . ya ara yín sọ́tọ̀, . . . kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́.”​—2 Kọ́ríńtì 6:​17.

  •   Ìrètí wà fáwọn tó ti kú. Bíbélì kọ́ wa pé àjíǹde máa wà, ìgbà kan sì ń bọ̀ tí kò ní sí ikú mọ́. (Ìṣe 24:15; Ìṣípayá 21:4) Ìrètí yìí ran àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ lọ́wọ́, kì í sì í jẹ́ káwa náà ṣọ̀fọ̀ ju bó ṣe yẹ.​—1 Tẹsalóníkà 4:​13.

  •   Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa ṣe nǹkan níwọ̀n. (Òwe 11:2) A ò gbà pé ó yẹ kí ibi ìsìnkú jẹ́ ibi téèyàn á ti máa fi nǹkan ìní ẹ̀ àti bó ṣe jẹ́ láwùjọ ṣe “ṣekárími.” (1 Jòhánù 2:​16) A kì í náwó yàlà-yòlò níbi ìsìnkú tàbí ká náwó rẹpẹtẹ láti ra pósí tàbí ra aṣọ olówó ńlá ká lè fi ṣe fọ́rífọ́rí fáwọn èèyàn.

  •   A kì í fipá mú káwọn míì gba ohun tá a gbà gbọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìsìnkú. Ìlànà Bíbélì la máa ń tẹ̀ lé lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé: “Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Róòmù 14:12) Àmọ́ tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ, a máa ń gbìyànjú àti ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ “pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”​—1 Pétérù 3:​15.

Báwo ni ìsìnkú àwa Ẹlẹ́rìí ṣe máa ń rí?

 Ibi tá a ti máa ń ṣe é: Tí ẹbí ẹnì kan bá fẹ́ ṣe ààtò ìsìnkú èèyàn wọn kan tó kú, wọ́n lè ṣe é níbi tó bá wù wọ́n. Ó lè jẹ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, nílé tí wọ́n ń gbé òkú sí, nílé àdáni, níbi tí wọ́n ti ń sun òkú tàbí létí ibojì.

 Ìsìn: Ẹnì kan máa sọ àsọyé tó máa tu àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú, ó máa ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú àti ìrètí àjíǹde. (Jòhánù 11:25; Róòmù 5:​12; 2 Pétérù 3:​13) Lásìkò ìsìn yẹn, ẹni tó ń sọ àsọyé náà lè sọ̀rọ̀ lórí ìwà rere ẹni tó kú, ó tiẹ̀ lè sọ àwọn ohun tí àpẹẹrẹ rere ẹni náà kọ́ wa.—2 Sámúẹ́lì 1:​17-​27.

 Wọ́n lè kọ orin kan tó dá lórí Ìwé Mímọ́. (Kólósè 3:​16) Wọ́n á wá fi àdúrà tó ń tuni nínú parí ìsìn náà.​—Fílípì 4:​6, 7.

 Owó tàbí ọrẹ: A kì í gba owó lọ́wọ́ àwọn ará wa tá a bá ń ṣe ìsìn, títí kan ààtò ìsìnkú, bẹ́ẹ̀ la kì í gbégbá ọrẹ láwọn ìpàdé wa.​—Mátíù 10:8.

 Àwọn tó lè wá: Àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lè wá síbi ààtò ìsìnkú tá a bá ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bíi tàwọn ìpàdé wa míì ló rí, kò sẹ́ni tí ò lè wá.

Ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń lọ síbi ìsìnkú táwọn ẹlẹ́sìn míì bá ṣe?

 Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ọ̀kan ti fi Bíbélì kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, torí náà òun fúnra rẹ̀ ló máa pinnu bóyá òun á lọ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. (1 Tímótì 1:​19) Àmọ́ tá a bá rí i pé àwọn ayẹyẹ ìsìn kan ta ko Bíbélì, a kì í lọ́wọ́ sí i.​—2 Kọ́ríńtì 6:​14-​17.