Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Jeremáyà 11:11—“Èmi Yóò Mu Ibi . . . Wá Sórí Wọn”

Jeremáyà 11:11—“Èmi Yóò Mu Ibi . . . Wá Sórí Wọn”

“Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Wò ó, màá mú àjálù tí wọn kò ní lè bọ́ nínú rẹ̀ wá bá wọn. Nígbà tí wọ́n bá ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, mi ò ní fetí sí wọn.’”​—Jeremáyà 11:11, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

“Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi yóò mu ibi tí wọn kò ní le è yẹ̀ wá sórí wọn, bí wọ́n tilẹ̀ ké pè mí èmi kì yóò fetí sí igbe wọn.”​—Jeremáyà 11:11, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

Ìtumọ̀ Jeremáyà 11:11

 Àwọn Júù ìgbà ayé wòlíì Jeremáyà ni Ọlọ́run ń bá sọ ọ̀rọ̀ yìí. Jèhófà a sọ fún wọn pé òun ò ní dáàbò bò wọ́n, kò sì ní gbà wọ́n lọ́wọ́ àbájáde ìwà burúkú wọn torí pé wọn ò pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, wọn ò sì fetí sí ìkìlọ̀ tó fún wọn nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀.​—Òwe 1:24-32.

 “Torí náà ohun tí Jèhófà sọ nìyí.” Ṣe ni “torí náà” tó bẹ̀rẹ̀ ẹsẹ yìí ń so àwọn ọ̀rọ̀ tó wà láwọn ẹsẹ tó ṣáájú mọ́ àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e. Ní Jeremáyà 11:1-10, Jèhófà sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé wọ́n ti da májẹ̀mú tàbí àdéhùn tó wà láàárín òun àtàwọn baba ńlá wọn. (Ẹ́kísódù 24:7) Òrìṣà ni wọ́n ń bọ dípò kí wọ́n máa sin Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ ìwà burúkú làwọn Júù yìí hù torí pé wọ́n kọ Ọlọ́run sílẹ̀, ó tiẹ̀ le débi pé wọ́n fi àwọn ọmọ wọn rúbọ!​—Jeremáyà 7:31.

 “Wò ó màá mú àjálù . . . bá wọn.” Lọ́pọ̀ ìgbà tí Bíbélì bá sọ pé Ọlọ́run ṣe ohun kan, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ṣe ni Ọlọ́run kàn fàyè gba ohun náà kó ṣẹlẹ̀. Ṣé bọ́rọ̀ àwọn Júù yìí náà ṣe rí nìyẹn? Ní tiwọn, bí wọ́n ṣe mọ̀ọ́mọ̀ pa àwọn ìlànà Ọlọ́run tó lè ṣe wọ́n láǹfààní tì, tí wọ́n sì ń bọ òrìṣà ló mú kí àjálù bá wọn. Torí pé Ọlọ́run ò dáàbò bò wọ́n mọ́, ọba Bábílónì tó jẹ́ ọ̀tá wọn gbógun jà wọ́n, ó sì kó wọn lẹ́rú. Ó ṣeni láàánú pé àwọn òrìṣà tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé kò le gbà wọ́n sílẹ̀.​—Jeremáyà 11:12; 25:8, 9.

 Bí Ọlọ́run ṣe fàyè gba àjálù tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn rẹ̀ kò fi hàn pé Ọlọ́run ò ṣe ìdájọ́ òdodo tàbí pé ó jẹ́ ẹni burúkú. Jémíìsì 1:13 sọ pé “A ò lè fi ibi dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnikẹ́ni wò.” Lóòótọ́, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní sọ pé Ọlọ́run “yóò mu ibi . . . wá sórí [àwọn Júù].” Àmọ́, ọ̀rọ̀ Hébérù b tí wọ́n tú sí “ibi” ní Jeremáyà 11:11 la tún lè pè ní “àjálù” tàbí “wàhálà,” ìyẹn sì lọ̀rọ̀ tó dáa jù lọ tá a lè fi sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Júù yẹn.

 “Nígbà tí wọ́n bá ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, mi ò ní fetí sí wọn.” Jèhófà kì í gbọ́ àdúrà àwọn tí ‘ẹ̀jẹ̀ kún ọwọ́ wọn’ tàbí àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ọlọ́run èké. (Àìsáyà 1:15; 42:17) Àmọ́ ó máa ń tẹ́tí sí àwọn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tí wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀.​—Àìsáyà 1:16-19; 55:6, 7.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Jeremáyà 11:11

 Lọ́dún 647 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jèhófà yan Jeremáyà láti di wòlíì rẹ̀. Odindi ogójì (40) ọdún ni wòlíì yìí fi kìlọ̀ fáwọn èèyàn Júdà nípa ìdájọ́ Ọlọ́run. Àmọ́ wọn ò fetí sí ìkìlọ̀ náà. Àkókò yẹn ni wòlíì náà kọ ọ̀rọ̀ tó wà ní Jeremáyà 11:11. Nígbà tó di ọdún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ nígbà táwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run.​—Jeremáyà 6:6-8; 39:1, 2, 8, 9.

 Àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fúnni nírètí tún wà nínú ìwé Jeremáyà. Jèhófà tiẹ̀ sọ níbẹ̀ pé: ‘Tó bá ti pé àádọ́rin (70) ọdún tí ẹ ti wà ní Bábílónì, màá mú ìlérí mi ṣẹ láti mú yín pa dà wá sí ibí yìí [ìyẹn ìlú ìbílẹ̀ àwọn Júù].’ (Jeremáyà 29:10) Jèhófà mú ìlérí náà “ṣẹ” lọ́dún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà táwọn ará Mídíà àti Páṣíà ṣẹ́gun Bábílónì. Jèhófà jẹ́ kí àwọn èèyàn ẹ̀ tó wà káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà pa dà sílùú ìbílẹ̀ wọn kí wọ́n lè máa jọ́sìn rẹ̀ bó ṣe tọ́.​—2 Kíróníkà 36:22, 23; Jeremáyà 29:14.

 Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Jeremáyà.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run bó ṣe wà nínú lẹ́tà mẹ́rin tí wọ́n fi kọ orúkọ náà lédè Hébérù. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tó fà á tí àwọn atúmọ̀ Bíbélì kan fi lo orúkọ oyè náà “Olúwa” dípò orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an, ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?

b Èdè Hébérù àti Árámáíkì ni wọ́n fi kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù táwọn èèyàn ń pè ní “Májẹ̀mú Láéláé.”