Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Éfésù 3:20—“[Ọlọ́run] Lè Ṣe Lọ́pọ̀lọpọ̀ Ju Gbogbo Èyí Tí A Ń Béèrè Tàbí Tí A Ń Rò Lọ”

Éfésù 3:20—“[Ọlọ́run] Lè Ṣe Lọ́pọ̀lọpọ̀ Ju Gbogbo Èyí Tí A Ń Béèrè Tàbí Tí A Ń Rò Lọ”

 “Ní báyìí, fún ẹni tó lè ṣe ọ̀pọ̀ yanturu ju ohun tó ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a ronú kàn, gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ nínú wa, òun ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀.”​—Éfésù 3:20, 21, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa. Òun ni kí a máa fi ògo fún.”​—Éfésù 3:20, 21, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

Ìtumọ̀ Éfésù 3:20

 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ bó ṣe dá a lójú tó pé Ọlọ́run lè dáhùn àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà tí wọn ò lérò rárá. Kódà, Ọlọ́run tiẹ̀ lè ṣe ju ohun tí wọ́n lérò tàbí tí wọ́n ń retí.

 “Ní báyìí, fún ẹni tó lè ṣe . . . gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ nínú wa.” Ẹsẹ 21 jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run a ni “ẹni” náà. Níbẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “òun ni kí ògo jẹ́ tirẹ̀ nípasẹ̀ ìjọ àti nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Jòhánù 20:31) Bákan náà, Ọlọ́run lè fún wa ní agbára tá a nílò ká lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀.​—Fílípì 4:13.

 Ní ẹsẹ 20, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa agbára tí Jèhófà ní láti ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ náà “ẹni tó lè ṣe.” Ó ní: “Ohun tí ẹsẹ yìí ń sọ kì í ṣe bóyá Ọlọ́run lè ṣe ohun kan. Dípò bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé ó lágbára láti ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́ ṣe.” Bíi ti ọ̀rẹ́ kan tó nífẹ̀ẹ́ ẹni dénú, gbogbo ìgbà ni Jèhófà lágbára láti ṣe ohun tó bá yẹ, kó lè ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, kó sì dáhùn àdúrà wọn. Òun nìkan lẹni tí àṣẹ rẹ̀ kò láàlà, tó sì lágbára láti ṣe ohunkóhun tó bá pinnu.​—Àìsáyà 40:26.

 “[Ọlọ́run] lè ṣe ọ̀pọ̀ yanturu ju ohun tó ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a ronú kàn.” Jèhófà lè ṣe ọ̀pọ̀ yanturu, kódà ó lè ṣe “ọ̀pọ̀ yanturu ju ohun tó ré kọjá” ohun táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nílò. Jèhófà lè ṣe kọjá ohun táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbà pé àwọn nílò.

 Ọ̀rọ̀ náà “ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a ronú kàn” tún jẹ́ ká mọ bọ́rọ̀ náà ṣe jinlẹ̀ tó. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ pé “ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a ronú kàn,” ṣe ló fẹ́ káwọn Kristẹni mọ̀ pé Ọlọ́run lè ṣe kọjá ohun tí wọ́n ń retí. Nínú Bíbélì Yoruba Bible, apá ìbẹ̀rẹ̀ ẹsẹ 20 kà pé: “Ẹni tí ó lè ṣe ju gbogbo nǹkan tí à ń bèèrè, ati ohun gbogbo tí a ní lọ́kàn lọ.” Nígbà míì, àwọn Kristẹni lè ronú pé ìṣòro àwọn ti pọ̀ jù tàbí pé kò lè yanjú. Kódà, wọ́n lè má mọ ohun tí wọ́n máa sọ nínú àdúrà. Àmọ́, arínúróde ni Jèhófà, ó sì lágbára láti ràn wá lọ́wọ́. Ọlọ́run lè bá wa yanjú ìṣòro èyíkéyìí lásìkò tó tọ́ lójú rẹ̀, ó sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí a ò lérò. (Jóòbù 42:2; Jeremáyà 32:17) Àmọ́ ní báyìí ná, ó máa ń fún wa lókun láti fara dà á, ká sì máa láyọ̀!​—Jémíìsì 1:2, 3.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Éfésù 3:20

 Àwọn Kristẹni tó ń gbé ní ìlú Éfésù tó wà ní Éṣíà Kékeré, tó jẹ́ apá kan ìlú Tọ́kì òde òní ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ́ lẹ́tà sí, ìyẹn ìwé Éfésù. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú àdúrà tó gbà fún wọn ló wà nínu lẹ́tà yìí. (Éfésù 3:14-21) Ó gbàdúrà pé kí àwọn ará Éfésù àti gbogbo Kristẹni lápapọ̀ mọ ìfẹ́ Kristi, kí wọ́n máa sapá láti fara wé e, kí wọ́n sì ní irú èrò tó ní. Ní ìparí àdúrà Pọ́ọ̀lù, ó yin Ọlọ́run, ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ní Éfésù 3:20, 21.

 Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Éfésù.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?