Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

DEA/G. Dagli Orti/De Agostini via Getty Images

Bí Huldrych Zwingli Ṣe Wá Òtítọ́ Bíbélì

Bí Huldrych Zwingli Ṣe Wá Òtítọ́ Bíbélì

 Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run lè mọ̀ bóyá ohun táwọn gbà gbọ́ bá Bíbélì mu tàbí kò bá a mu. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò ní Bíbélì ní èdè wọn. Torí náà, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló lè fi ohun tí wọ́n ń kọ́ ní Ṣọ́ọ̀ṣì wé ohun tí Bíbélì sọ. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ò ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ìwé History of the Christian Church sọ pé: “Ìwà ìbàjẹ́ ló kún inú Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Switzerland, oníṣekúṣe làwọn àlùfáà wọn, wọn ò ka nǹkan sí, ẹ̀kọ́ èké ni wọ́n sì fi ń kọ́ni.”

 Bí nǹkan ṣe rí rèé lásìkò tí Huldrych Zwingli ń wá bó ṣe máa mọ òtítọ́ inú Bíbélì. Ṣé ó rí òtítọ́ tó ń wá? Báwo ló ṣe ṣàlàyé ohun tó kọ́ fáwọn míì? Kí la sì lè kọ́ nínú bó ṣe gbé ìgbésí ayé ẹ̀ àti nínú ohun tó gbà gbọ́?

Zwingli Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣèwádìí

 Nígbà tí Zwingli lé díẹ̀ lẹ́ni ogún (20) ọdún, ohun tó wù ú jù ni bó ṣe máa di àlùfáà Kátólíìkì. Nígbà yẹn, ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di àlùfáà Kátólíìkì gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ọgbọ́n orí, ààtò ṣọ́ọ̀ṣì, àti ìwé àwọn “Olùdásílẹ̀” dípò kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an.

 Báwo ni Zwingli ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í lóye òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì? Nígbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́ ní yunifásítì tó wà ní Basel, lórílẹ̀-èdè Switzerland, ó lọ síbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan tí Ọ̀gbẹ́ni Thomas Wyttenbach ṣe. Ọ̀gbẹ́ni yẹn bẹnu àtẹ́ lu bí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣe ń gbowó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ. a Òpìtàn kan sọ pé Zwingli “kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Wyttenbach pé Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (1 Pétérù 3:18) Nígbà tó yé Zwingli pé ikú Jésù nìkan ló lè mú ká rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ náà pé èèyàn gbọ́dọ̀ sanwó fáwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kó tó lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. (Ìṣe 8:20) Láìka èyí sí, Zwingli ń bá ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ, ó sì di àlùfáà Kátólíìkì lọ́mọ ọdún méjìlélógún (22).

 Nígbà tó yá, Zwingli kọ́ èdè Gíríìkì kó lè lóye èdè tí wọ́n fi kọ Májẹ̀mú Tuntun. Lẹ́yìn tó ka àwọn ìwé tí Erasmus kọ, ó wá rí i pé Jésù ni Alárinà tó wà láàárín Ọlọ́run àti èèyàn bí Bíbélì ṣe sọ. (1 Tímótì 2:5). Bó ṣe di pé Zwingli bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì lórí ẹ̀kọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fi ń kọ́ni pé àwọn ẹni mímọ́ ló lè mú ká sún mọ́ Ọlọ́run.

 Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Zwingli tẹra mọ́ ìwádìí tó ń ṣe láti mọ òtítọ́. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó tún ṣiṣẹ́ àlùfáà àwọn ọmọ ogun nígbà tí wọ́n ń ja ogun nílẹ̀ yúróòpù lórí ẹni tó máa ṣàkóso ilẹ̀ Ítálì. Nínú ìjà tó wáyé ní Marignano lọ́dún 1515, ó ri bí àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì ṣe ń pa ara wọn nípakúpa. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì, kódà ó tún há èyí tó pọ̀ nínú ẹ̀ sórí. Nígbà tó fi máa di ọdún 1519, ó ti ń gbé nílùú Zurich níbi táwọn abẹnugan olóṣèlú ń gbé ní Switzerland. Ibẹ̀ ló wà tó fi gbà pé, kò yẹ kí Ṣọ́ọ̀ṣì máa kọ́ni lóhun tí ò sí nínú Bíbélì. Àmọ́, báwo ló ṣe máa ṣe é táwọn míì fi máa gba òtítọ́ yìí?

“A Ò Gbọ́ Irú Ìwàásù Yìí Rí”

 Zwingli gbà pé táwọn èèyàn bá rí òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, wọn ò ní gba irọ́ táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń pa fún wọn gbọ́ mọ́. Lẹ́yìn tó di àlùfáà ní ṣọ́ọ̀ṣì ńlá kan tí wọ́n ń pè ní Grossmünster ní Zurich, ó gbé ìgbésẹ̀ kan láìbẹ̀rù. Ó pinnu pé òun ò ní máa ka àyọkà ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ní èdè Latin b tí wọ́n yàn fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí àwọn àlùfáà ti máa ń k fún ọ̀pọ̀ ọdún. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì lòun á fi máa wàásù Ìhìn Rere. Tó bá ti bẹ̀rẹ̀ orí Bíbélì kan, á ṣàlàyé àwọn ẹsẹ tó wà níbẹ̀ kó tó bọ́ sí orí tó tẹ̀ lé e, bó sì ṣe ń ṣe é nìyẹn. Dípò kó jẹ́ kí ìwé àwọn Olùdásílẹ̀ ṣàlàyé Ìwé Mímọ́, ṣe ló máa ń fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé Ìwé Mímọ́. Ohun tó máa ń ṣe ni pé á fi ẹsẹ Bíbélì tó rọrùn lóye ṣàlàyé èyí tó ta kókó.​—2 Tímótì 3:16.

Sergio Azenha/Alamy Stock Photo

Ṣọ́ọ̀ṣì Grossmünster ní Zurich

 Tí Zwingli bá ń wàásù, ó máa ń jẹ́ káwọn èèyàn rí bí Bíbélì ṣe wúlò tó. Ó kọ́ àwọn èèyàn ní ìlànà ìwà rere tó wà nínú Bíbélì, ó sì ń wàásù pé kò yẹ kí wọ́n máa jọ́sìn Màríà ìyá Jésù. Kò tán síbẹ̀ o, ó sọ pé kò yẹ kí wọ́n máa gbàdúrà sáwọn ẹni mímọ́, kò yẹ káwọn èèyàn máa san owó ìdáríjí ẹ̀ṣẹ̀, kò sì yẹ káwọn àlùfáà máa lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe. Báwo lohun tó ń kọ́ni yìí ṣe rí lára àwọn èèyàn? Lẹ́yìn tó parí ìwàásù rẹ̀ àkọ́kọ́, àwọn kan sọ pé: “A ò gbọ́ irú ìwàásù yìí rí.” Òpìtàn kan sọ nípa àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì tó gbọ́ ìwàásù Zwingli pé: “Àwọn tó ti pa ṣọ́ọ̀ṣì tì torí ìwà pálapàla àti ìṣekúṣe àwọn àlùfáà ló bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà.”

 Nígbà tó di ọdún 1522, àwọn àlùfáà lẹ̀dí àpọ̀ pọ̀ mọ́ àwọn olóṣèlú ìlú Zurich, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fìyà jẹ àwọn tó bá ń ṣe ohun tó ta ko ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì. Torí náà, wọ́n fẹ̀sùn kan Zwingli pé apẹ̀yìndà ni. Torí pé Zwingli ò ṣe tán láti yí èrò ẹ̀ pa dà, ó kọ̀wé fi ipò àlùfáà Kátólíìkì tó wà sílẹ̀.

Kí Ni Zwingli Ṣe?

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Zwingli kì í ṣe àlùfáà mọ́, kò ṣíwọ́ àtimáa wàásù, ó sì ń gbìyànjú láti jẹ́ káwọn èèyàn gba èrò ẹ̀. Ìwàásù ẹ̀ ti jẹ́ kó gbajúmọ̀, ìyẹn sì mú kó lẹ́nu láwùjọ àwọn olóṣèlú Zurich. Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n á ṣe yí ìjọsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì pa dà ní Zurich. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1523, ó mú káwọn aláṣẹ ìlú Zurich fòfin de ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì èyíkéyìí tí ò bá ti bá Ìwé Mímọ́ mu. Lọ́dún 1524, ó mú kí wọ́n fòfin de ìbọ̀rìṣà. Ìyẹn wá mú káwọn adájọ́ ìlú, àwọn oníwàásù àdúgbò àtàwọn aráàlú ba àwọn pẹpẹ òrìṣà jẹ́, wọ́n sì ba ère àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà jẹ́. Ìwé Zwingli​—God’s Armed Prophet sọ pé: “Yàtọ̀ sígbà táwọn ẹ̀yà Vikings wá jí gbogbo ohun tó wà nínú ilé ìjọsìn kó, ohun tí Zwingli mú káwọn èèyàn ṣe yìí, ni ìgbà kan ṣoṣo táwọn kan máa dìídì wá ba Ṣọ́ọ̀ṣì jẹ́.” Nígbà tó fi máa di ọdún 1525, ó ti mú káwọn aláṣẹ ṣòfin pé kí wọ́n sọ àwọn ilé tí ṣọ́ọ̀ṣì ní di ilé ìwòsàn, káwọn àlùfáà àtàwọn mọdá sì máa ṣègbéyàwó. Ó tún dábàá pé kí wọ́n yí bí wọ́n ṣe ń ṣe ààtò Máàsì pa dà, kí wọ́n sì máa ṣe é lọ́nà ránpẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì. (1 Kọ́ríńtì 11:23-25) Àwọn òpìtàn tiẹ̀ sọ pé ohun tí Zwingli ṣe yìí ló mú káwọn olóṣèlú àtàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ìlú Zurich bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Ó sì mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í yí àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì pa dà, káwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì náà sì fìdí múlẹ̀.

Bíbélì Zurich ti ọdún 1536 ní Oríléeṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Warwick, New York

 Iṣẹ́ tó dáa jù tí Zwingli ṣe ni iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì. Láwọn ọdún 1520 sí 1529, òun àtàwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì bíi mélòó kan lo Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì. Àwọn Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n lò lèyí tó wà lédè Hébérù àti Gíríìkì, Bíbélì Septuagint tó wà lédè Gíríìkì pa pọ̀ pẹ̀lú ìwé Vulgate tó wà lédè Gíríìkì àti Latin. Ọ̀nà tó rọrùn ni wọ́n gbà ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ náà. Bí wọ́n ṣe ṣe é ni pé, wọ́n á kọ́kọ́ ka ẹsẹ kan látinú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀, wọ́n á fi wéra pẹ̀lú ìtumọ̀ Bíbélì míì tí wọ́n gbà pé ìtumọ̀ ẹ̀ péye. Lẹ́yìn náà, wọ́n á jíròrò ohun tí ẹsẹ yẹn túmọ̀ sí, wọ́n á wá kọ èrò wọn sílẹ̀. Àwọn àlàyé tí wọ́n ṣe lórí Bíbélì àti iṣẹ́ ìtumọ̀ wọn ló para pọ̀ di Bíbélì Zurich èyí tí wọ́n mú jáde lọ́dún 1531.

 Òótọ́ ni pé Zwingli fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òtítọ́, àmọ́ ó le koko jù kò sì gba tàwọn míì rò. Bí àpẹẹrẹ lọ́dún 1525, ó wà lára àwọn tó fojú pọ́n àwọn onísìn tí wọ́n ń pè ní Anabaptist. Ìdí sì ni pé àwọn yẹn ò fara mọ́ ẹ̀kọ́ tí Zwingli fi ń kọ́ni pé kí wọ́n máa ṣe ìrìbọmi fún àwọn ìkókó tàbí àwọn ọmọdé. Kódà, nígbà tí ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún àwọn tí ò fara mọ́ pé kí wọ́n ṣe ìrìbọmi fún àwọn ìkókó tàbí àwọn ọmọdé, Zwingli ò ta kò ó. Ó tún rọ àwọn abẹnugan lára àwọn olóṣèlú pé kí wọ́n lo àwọn ológun láti fi pá mú àwọn èèyàn láti gba ohun tí òun kọ́ni gbọ́. Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó wà ní Switzerland kọ̀ láti fara mọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ pàápàá láwọn ibi tí ẹ̀sìn Kátólíìkì ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ gan-an, èyí sì yọrí sí ogun abẹ́lé. Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí Zwingli ṣe? Ó tẹ̀ lé àwọn sójà lọ sójú ogun, ó sì kú síbẹ̀ lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta (47).

Ohun Táwọn Èèyàn Mọ̀ Nípa Zwingli

 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ṣe àyípadà sí àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ọ̀kan pàtàkì ni Huldrych Zwingli jẹ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò lókìkí bíi Martin Luther àti John Calvin. Zwingli ò dà bí Luther ní ti pé kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nígbà tó ń fi hàn pé òun ò fara mọ́ ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, ìyẹn mú kó rọrùn fáwọn èèyàn láti gba ẹ̀kọ́ Calvin. Ìdí nìyẹn táwọn èèyàn fi gbà pé òun ni ẹni kẹta tó yí àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì pa dà.

 Òótọ́ ni pé Zwingli gbìyànjú, síbẹ̀ ó níbi tó kù sí. Bí àpẹẹrẹ, ó tara bọ òṣèlú, ó sì jagun torí káwọn èèyàn lè gba èrò ẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, kò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi torí pé Jésù ò lọ́wọ́ sí òṣèlú, ó sì kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn, kò sọ pé kí wọ́n pa àwọn ọ̀tá wọn.​—Mátíù 5:43, 44; Jòhánù 6:14, 15.

 Síbẹ̀, àwọn èèyàn gbà pé Zwingli máa ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣe tán láti kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tó mọ̀. Ọ̀pọ̀ òtítọ́ inú Bíbélì ló rí, ó sì kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ yìí.

a Àwọn àlùfáà máa ń gbowó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ìjọ torí wọ́n gbà pé owó yẹn ò ní jẹ́ kí wọ́n jìyà púpọ̀ tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ jìyà rárá torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, tí wọ́n bá dé pọ́gátórì lẹ́yìn tí wọ́n bá kú.

b Ìwé yìí ti ní àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n ti yàn fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì máa ń kà á jálẹ̀ ọdún.