Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Pọ́gátórì Wà Nínú Bíbélì?

Ṣé Pọ́gátórì Wà Nínú Bíbélì?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Rárá, kò sí níbẹ̀. A ò lè rí ọ̀rọ̀ náà, “pọ́gátórì” nínú Bíbélì, Bíbélì ò sì fi kọ́ni pé a máa ń yọ́ ọkàn àwọn tó ti kú mọ́ ní pọ́gátórì. a Wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, àti bí ohun tó sọ ṣe ta ko ẹ̀kọ́ pọ́gátórì.

  •   Ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù ló máa ń wẹ èèyàn mọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀, kì í ṣe pọ́gátórì. Bíbélì sọ pé “ẹ̀jẹ̀ Jésù Ọmọ [Ọlọ́run] . . . ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀” àti pé “Jésù Kristi . . . dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (1 Jòhánù 1:7; Ìṣípayá 1:5, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Jésù fi “ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọpọlọpọ eniyan” láti gbà wọ́n kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.​—Mátíù 20:28, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀.

  •   Àwọn tó ti kú kò mọ nǹkan mọ́. “Nítorí alààyè mọ̀ pé òun óo kú, ṣugbọn òkú kò mọ nǹkankan mọ́.” (Oníwàásù 9:5, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Ẹni tó ti kú ò lè mọ nǹkan kan lára, torí náà, kò sí nǹkan tó ń jẹ́ pé iná pọ́gátórì kan ń yọ́ ẹni tó ti kú mọ́.

  •   Téèyàn bá ti kú, ó ti jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nìyẹn. Bíbélì sọ pé “ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀” àti pé “ẹni tí ó ti kú ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.” (Róòmù 6:7, 23, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀) Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, téèyàn bá ti kú, ó ti jìyà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nìyẹn.

a Ìwé Orpheus: A General History of Religions sọ̀rọ̀ nípa pọ́gátórì, ó ní “kò sírú ọ̀rọ̀ yẹn nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere.” Bákan náà, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Ibi tá a parí èrò sí ni pé, ọ̀rọ̀ pọ́gátórì tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fi ń kọ́ni kò sí nínú Ìwé Mímọ́, inú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ló ti wá.”​—Ẹ̀dà Kejì, Ìdìpọ̀ 11, ojú ìwé 825.

b Wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia, Ẹ̀dà Kejì, Ìdìpọ̀ 11, ojú ìwé 824.