Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ LÈ MÚ KÍ ÌDÍLÉ LÁYỌ̀

Bí Àwọn Tó Tún Ìgbéyàwó Ṣe Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí

Bí Àwọn Tó Tún Ìgbéyàwó Ṣe Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí

HERMAN: * “Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n tí èmi àti ìyàwó mi ti ń fẹ́ra ni àrùn jẹjẹrẹ pa á. Nígbà tí mo wá fẹ́ Linda, ó máa ń ronú pé gbogbo ìgbà ni mo máa ń fi òun wé ìyàwó tí mo kọ́kọ́ fẹ́. Èyí tó tún wá bọ̀rọ̀ jẹ́ ni pé àwọn tá a ti jọ ń ṣọ̀rẹ́ tipẹ́tipẹ́ kì í yéé sọ̀rọ̀ nípa ìwà dáadáa tí ìyàwó mi tó ti di olóògbé ní, gbogbo èyí sì máa ń bí Linda nínú.”

LINDA: “Lẹ́yìn tí èmi àti Herman ṣègbéyàwó, ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò lè dà bí ìyàwó tí ọkọ mi kọ́kọ́ fẹ́ láéláé. Ọkọ mi fẹ́ràn rẹ̀ gan-an ni, ó ní èèyàn jẹ́jẹ́ ni, ó sì níwà. Kódà nígbà míì, mo máa ń rò ó pé bóyá ni mo lè mọwọ́ ọkọ mi bíi ti ìyàwó rẹ̀ tó kọ́kọ́ fẹ́.”

Ṣe ni Linda kọ ọkọ to ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, àmọ́ inú òun àti Herman dùn pé wọ́n fẹ́ ara wọn. Síbẹ̀, àwọn méjèèjì ló gbà pé àwọn ìṣòro tó máa ń wáyé nínú ìgbéyàwó téèyàn tún ṣe lè máà sí nínú ìgbéyàwó àkọ́kọ́. *

Tó o bá ti fẹ́ ìyàwó tàbí ọkọ míì, báwo ni nǹkan ṣe rí láàárín ìwọ àti ẹni tó o fẹ́ báyìí? Ìyàwó ilé kan tó ń jẹ́ Tamara fẹ́ ẹlòmíì lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí òun àti ọkọ rẹ̀ ti kọ ara wọn sílẹ̀. Ohun tó sọ ni pé: “Nígbà àkọ́kọ́ téèyàn bá ṣègbéyàwó, ó máa ń ṣèèyàn bíi pé kò sí ohun tó lè da àárín ẹ̀yin méjèèjì rú. Ṣùgbọ́n téèyàn bá tún ìgbéyàwó ṣe, ọ̀rọ̀ lè máà rí bẹ́ẹ̀, ìdí ni pé ẹ̀rù lè máa ba èèyàn pé irú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ tún lè lọ ṣẹlẹ̀.”

Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló ń láyọ̀, tí ọkàn wọn sì balẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n tún ìgbéyàwó ṣe. Wọ́n mú kí ìgbéyàwó wọn ṣàṣeyọrí, ìgbéyàwó tìrẹ náà sì lè ṣàṣeyọrí! Báwo lo ṣe lè ṣe é? Wo àwọn ìṣòro mẹ́ta tó sábà máa ń jẹ yọ àti bí a ṣe lè fi ìlànà Bíbélì yanjú wọn. *

ÌṢÒRO KÌÍNÍ: KÒ RỌRÙN FÚN Ẹ LÁTI GBÉ Ọ̀RỌ̀ ẸNI TÍ Ò Ń FẸ́ TẸ́LẸ̀ KÚRÒ LỌ́KÀN.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Ellen, tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Kì í rọrùn fún mi rárá láti gbé ọ̀rọ̀ ọkọ mi àtijọ́ kúrò lọ́kàn, pàápàá tí a bá rìnrìn àjò lọ sí àwọn ibi tí èmi àti ọkọ mi àtijọ́ ti máa ń lọ gbafẹ́ lásìkò ìsinmi. Nígbà míì, mo máa ń fi ọkọ tí mó ń fẹ́ báyìí wé ọkọ mi àtijọ́.” Ohun míì tún ni pé, tí ọkọ tàbí aya rẹ bá ti fẹ́ ẹnì kan rí, inú lè máa bí ẹ tí kò bá yéé sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ yẹn.

Ẹ jọ máa ṣe àwọn nǹkan tuntun míì tí á túbọ̀ jẹ́ kí ẹ mọwọ́ ara yín

ÀBÁ: Má kàn rò pé ìwọ tàbí ẹni tí ò ń fẹ́ báyìí máa yára gbọ́kàn kúrò lára ẹni tí ẹ ń fẹ́ tẹ́lẹ̀, pàápàá tó bá jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ni ìwọ àti ẹni tó ò ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ fi jọ wà pọ̀ bíi tọkọtaya. Kódà, àwọn kan sọ pé nígbà míì tí àwọn bá fẹ́ pe ọkọ tàbí aya àwọn, orúkọ ẹni tí àwọn ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ ló máa kó sí àwọn lẹ́nu. Kí lo lè ṣe tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ? Bíbélì sọ pé, “Ẹ ní inú kan sí ara yín.”—1 Pétérù 3:8, Ìròhìn Ayọ̀.

Má ṣe jẹ́ kí owú mú kó o máa da ọ̀rọ̀ sí ìbínú ní gbogbo ìgbà tí ẹni tí ò ń fẹ́ báyìí bá sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó ń fẹ́ tẹ́lẹ̀. Tí ẹni tí o ń fẹ́ bá rí i pé ó yẹ kí òun sọ nǹkan kan fún ẹ nípa bí àárín òun àti ẹni tí òun ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ ṣe rí, fi sùúrù tẹ́tí sí i, kí o sì jẹ́ kó mọ̀ pé àánú rẹ̀ ṣe ọ́ gan-an. Bákan náà, má kàn yára ronú pé ṣe ló ń fi ẹ́ wé ẹni tó ń fẹ́ tẹ́lẹ̀. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ian tó fẹ́ ìyàwó míì ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn sọ pé, “Kaitlyn ìyàwó mi kì í bínú tí mo bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìyàwó mi tó di olóògbé. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ló kà á sí ọ̀nà tí òun fi lè mọ àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi kí èmi àti òun tó pàdé.” Ó ṣeé ṣe kó o tiẹ̀ wá rí i pé irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa mú kí o túbọ̀ mọwọ́ ọkọ tàbí aya rẹ tuntun dáadáa.

Àwọn ìwà tó dáa, tó sì ṣàrà ọ̀tọ̀ tí ẹni tí o ń fẹ́ báyìí ní ni kí o máa fọkàn sí. Lóòótọ́, ó ṣeé ṣe kó máà ní àwọn ìwà kan tàbí kó má lè ṣe àwọn nǹkan kan tí ẹni tí ò ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ ń ṣe. Síbẹ̀, òun náà máa ní ibi tó dáa sí. Nítorí náà, tí o bá fẹ́ kí àjọṣe àárín ìwọ àti ẹni tí ò ń fẹ́ báyìí túbọ̀ ṣe tímọ́tímọ́, má fi wé ẹni tí ò ń fẹ́ tẹ́lẹ̀, àmọ́ ṣe ni kí o máa fọkàn sí àwọn nǹkan tó mú kí o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, èyí sì máa jẹ́ kí o túbọ̀ mọyì irú ẹni tó jẹ́. (Gálátíà 6:4) Ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Edmond, tó ti tún ìgbéyàwó ṣe sọ pé: “Bó ṣe jẹ́ pé téèyàn bá bá ẹni méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣọ̀rẹ́, kò lè rí bákan náà, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ń rí pẹ̀lú ẹni tó ti fẹ́ ẹnì kan rí kó tó lọ fẹ́ ẹlòmíì, àwọn méjèèjì ò lè rí bákan náà.”

Kí lo lè ṣe tí ìrònú ẹni tí ò ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ kò fi ní máa gbà ẹ́ lọ́kàn ju àjọṣe tó o ní pẹ̀lú ẹni tí ò ń fẹ́ báyìí lọ? Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jared sọ pé: “Nígbà kan, mo ṣàlàyé fún ìyàwó mi pé, ọ̀rọ̀ èmi àti ìyàwó tí mo kọ́kọ́ fẹ́ dà bí eré inú fídíò kan tí èmi àti ìyàwó mi tẹ́lẹ̀ jọ ṣe. Látìgbàdégbà, tí mo bá rántí àwọn nǹkan dáadáa tá a ti jọ ṣe sẹ́yìn, ṣe ni ó máa ń dà bí pé mo ń wo fídíò yẹn. Ṣùgbọ́n o, mi ò sí nínú fídíò yẹn mọ́ báyìí. Inú fídíò tí èmi àti ìyàwó tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ jọ ń ṣe báyìí ni mo wà, mo sì ń láyọ̀ bí a ṣe jọ wà pa pọ̀.”

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Béèrè lọ́wọ́ ọkọ tàbí aya rẹ bó ṣe máa ń rí lára rẹ̀ tí o bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tí ò ń fẹ́ tẹ́lẹ̀. Mọ àwọn ìgbà tí kò yẹ kó o dá ọ̀rọ̀ ẹni tí o ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ sílẹ̀.

ÌṢÒRO KEJÌ: KÒ RỌRÙN FÚN Ẹ̀YIN MÉJÈÈJÌ LÁTI MỌWỌ́ ÀWỌN Ọ̀RẸ́ ẸNI TÍ Ẹ Ń FẸ́ BÁYÌÍ.

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Javier, tó fẹ́ ẹlòmíì lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tí òun àti ìyàwó rẹ̀ kọ ara wọn sílẹ̀ sọ pé: “Fún ìgbà díẹ̀ lẹ́yìn tí mo fẹ́ ìyàwó mi tuntun, ṣe ló ń rò pé àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi ń ṣọ́ òun lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀, tí wọ́n sì ń dán òun wò.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Leo yàtọ̀ ní tiẹ̀. Ó ní: “Ìṣojú mi báyìí ni àwọn kan ti ń sọ fún ìyàwó mi bí wọ́n ṣe ń ṣàárò ọkọ tó ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ àti bí wọ́n ṣe fẹ́ràn rẹ̀ tó.”

ÀBÁ: Gbìyànjú láti mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ian tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Mo ronú pé ó máa ń ká àwọn ọ̀rẹ́ àtijọ́ yẹn lára, ó sì lè má rọrùn fún wọn láti máa ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú ẹnì kan tí wọ́n ń wò ó pé ó kàn dédé wá gba ipò ẹnì kan nínú àwọn méjì tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀.” Torí náà, ó máa dára kí o ‘jẹ́ afòyebánilò, kí o sì máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo.’ (Títù 3:2) Má retí pé kíákíá ni àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtàwọn ìbátan rẹ máa gbé ọ̀rọ̀ ẹni tí o ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ kúrò lára. Bó ṣe jẹ́ pé ọ̀tọ̀ lẹni tí ò ń fẹ́ báyìí, àwọn ọ̀rẹ́ tó o máa ní náà lè yàtọ̀. Javier tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé nígbà tó yá òun àti ìyàwó òun sapá láti mú kí ọ̀rọ̀ àwọn àti àwọn ọ̀rẹ́ àtijọ́ tí wọ́n ti ní wọ̀ pa dà. Javier sọ pé: “A tún gbìyànjú láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun míì, èyí sì ti ràn wá lọ́wọ́ gidigidi.”

Máa kíyè sí bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹni tí ò ń fẹ́ báyìí nígbà tí ẹ bá wà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtijọ́. Bí àpẹẹrẹ, tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá dá ọ̀rọ̀ ẹni tí ò ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, lo ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀, kí ẹni tó ò ń fẹ́ báyìí má lọ rò pé ẹ ti pa òun tì. Bíbélì sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.”—Òwe 12:18.

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Mọ irú àwọn àpèjẹ tó lè kó ìtìjú bá ìwọ tàbí ẹni tí ò ń fẹ́. Ó máa dáa kí ẹ ti jọ sọ bí ẹ ó ṣe máa dá àwọn ọ̀rẹ́ yín lóhùn nígbà tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ nípa ẹni tí ẹ ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ tàbí tí wọ́n bá béèrè àwọn nǹkan kan nípa rẹ̀.

ÌṢÒRO KẸTA: KÒ RỌRÙN FÚN Ẹ LÁTI FỌKÀN TÁN ỌKỌ TÀBÍ AYA RẸ TORÍ PÉ ẸNI TÍ Ò Ń FẸ́ TẸ́LẸ̀ JÁ Ẹ KULẸ̀.

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Andrew, tí ìyàwó rẹ̀ já a sílẹ̀ sọ pé: “Mo máa ń bẹ̀rù pé kí ẹlòmíì máà tún lọ já mi kulẹ̀.” Nígbà tó yá, ó fẹ́ ìyàwó míì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Riley. Andrew sọ pé: “Mo máa ń rò ó pé bóyá ni mo lè ṣe dáadáa tó ọkọ tí Riley kọ́kọ́ fẹ́. Nígbà míì, ọkàn mi kì í balẹ̀ torí mo máa ń wò ó pé lọ́jọ́ kan ó lè sọ pé mi ò dáa tó fún òun, tí á sì fi mí sílẹ̀ lọ fẹ́ ẹlòmíì.”

ÀBÁ: Rí i pé gbogbo ohun tó bá ń jẹ ọ́ lọ́kàn ni ò ń sọ fún ọkọ tàbí aya rẹ. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.” (Òwe 15:22) Nígbà tí Andrew àti Riley bẹ̀rẹ̀ sí í finú han ara wọn, wọ́n wá fọkàn tán ara wọn. Andrew sọ pé: “Mo sọ fún Riley pé mi ò ní jẹ́ ronú kan ìkọ̀sílẹ̀ bí ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro, òun náà sì fi dá mi lójú pé òun kò ní kọ̀ mí sílẹ̀. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, mo wá fọkàn tán an pátápátá.”

Tó bá jẹ́ pé ṣe ni ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ já a kulẹ̀, rí i dájú pé o ṣe gbogbo ohun tí o bá lè ṣe láti jẹ́ kó fọkàn tán ẹ. Wo àpẹẹrẹ tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Michel àti Sabine. Ìyàwó tí Michel kọ́kọ́ fẹ́ já a kulẹ̀, ọkọ tí Sabine sì kọ́kọ́ fẹ́ já òun náà kulẹ̀. Ohun tí àwọn méjèèjì máa ń ṣe báyìí ni pé, gbogbo ìgbà tí wọ́n bá pàdé ẹni tí wọ́n ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ tàbí tí wọ́n gbúròó rẹ̀ ni wọ́n máa ń sọ fún ara wọn. Sabine sọ pé: “Bó ṣe jẹ́ pé a kì í fọ̀rọ̀ pamọ́ fún ara wa ti mú kí ọkàn wa balẹ̀ pé kò séwu.”—Éfésù 4:25.

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Kí ọkọ máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ níwọ̀n tí òun nìkan bá ń bá ẹni tí kì í ṣe aya rẹ̀ sọ̀rọ̀ yálà lójúkojú, lórí fóònù tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kí aya máa ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.

Ọ̀pọ̀ àwọn tó tún ìgbéyàwó ṣe ló ti ṣàṣeyọrí, ó sì dájú pé ìgbéyàwó tìẹ náà lè ṣàṣeyọrí. Ó ṣe tán, o ti mọ ara rẹ dáadáa nísinsìnyí ju tìgbà tí o kọ́kọ́ ṣe ìgbéyàwó lọ. Andrew tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Látìgbà tí mo ti fẹ́ Riley, ìtùnú tí mo ti rí kọjá àfẹnusọ. Ó ti lé lọ́dún mẹ́tàlá báyìí ti a ti ṣègbéyàwó, àwa méjèèjì sì ti mọwọ́ ara wa débi pé a ò fẹ́ kí nǹkan kan da àárín wa rú láéláé!”

^ ìpínrọ̀ 3 A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.

^ ìpínrọ̀ 5 Ohun kan tó ṣe kedere ni pé, bí nǹkan ṣe máa rí lára ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kú tó wá lọ fẹ́ ẹlòmíì máa yàtọ̀ sí bó ṣe máa rí lára ẹni tó kọ ọkọ tàbí aya rẹ̀ sílẹ̀ tó wá lọ fẹ́ ẹlòmíì. Àpilẹ̀kọ yìí lè ran àwọn tó bá wà nínú irú ipò yìí lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí nínú ìgbéyàwó wọn tuntun.

^ ìpínrọ̀ 7 Tí o bá fẹ́ àlàyé lórí ọgbọ́n tí ọkọ tàbí aya kan lè dá sí àwọn ìṣòro tó máa ń wà nínú títọ́ ọmọ ẹni téèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́, lọ wo Ilé Ìṣọ́ March 1, 1999 tó ní àkòrí náà “Ìdílé Onígbeyàwó Àtúnṣe Bí Wọ́n Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí.” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

BI ARA RẸ PÉ . . .

  • Àwọn ìwà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo ni ẹni tí mò ń fẹ́ báyìí ní tó wú mi lórí gan-an?

  • Tí ọ̀rọ̀ ẹni tí mò ń fẹ́ tẹ́lẹ̀ bá jẹ yọ, ọgbọ́n wo ni mo lè dá tí máa fi fi ọkàn ẹni tí mò ń fẹ́ báyìí balẹ̀ tí màá sì pọ́n ọn lé?