Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Nìdí Tẹ́ Ẹ Fi Ń Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Èèyàn Tó Ti Lẹ́sìn Tiwọn?

Kí Nìdí Tẹ́ Ẹ Fi Ń Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Èèyàn Tó Ti Lẹ́sìn Tiwọn?

 A ti rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn tó lẹ́sìn tí wọ́n ń ṣe ló máa ń gbádùn ìjíròrò nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. A gbà pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti gba ohun tó yàtọ̀ sí ti wa gbọ́, torí náà a kì í fipá mú àwọn ẹlòmíì láti gba ẹ̀kọ́ wa.

 Tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, a máa ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, tó sọ pé ká máa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú “inú tútù” ká sì ní “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pétérù 3:15) A mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa fara mọ́ ohun tá a fẹ́ sọ fún wọn. (Mátíù 10:14) Àmọ́, a ò lè mọ́ ohun tẹ́nì kan máa sọ àfi tá a bá bá a sọ̀rọ̀. A sì tún mọ̀ pé ipò tẹ́nì kan wà lè yí pa dà.

 Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè má ráyè bá wa sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ kan nítorí ọwọ́ rẹ̀ dí gan-an, àmọ́ kó wù ú láti bá wa sọ̀rọ̀ nígbà míì. Àwọn èèyàn sì lè dojú kọ àwọn ìṣòro kan tàbí ipò kan tó máa mú kí wọ́n fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì. Torí náà, a máa ń fẹ́ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìgbà tá a bá ti rí wọn.