Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Máa Gbé Ayé Rẹ Lọ Lẹ́yìn Ìkọ̀sílẹ̀

Bó O Ṣe Lè Máa Gbé Ayé Rẹ Lọ Lẹ́yìn Ìkọ̀sílẹ̀

“Ó ń ṣe mí bíi pé ọ̀rọ̀ mi ò lè lójú mọ́. Nǹkan ti ń lọ dáadáa tẹ́lẹ̀, àmọ́ ṣàdédé ni gbogbo ẹ̀ kàn yí pa dà.”—MARK, * ọdún kan rèé tí òun àti aya rẹ̀ ti kọ ara wọn.

“Obìnrin tí ọkọ mi bá ní àjọṣepọ̀ kò ju ọjọ́ orí ọmọbìnrin wa lọ. Nígbà tí a kọ ara wa sílẹ̀, inú mi dùn pé màá tiẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ bó ṣe máa ń bínú sódì, àmọ́ ìtìjú gbáà ló jẹ́ fún mi, ó wá ń ṣe mí bíi pé mi ò tiẹ̀ já mọ́ nǹkan.”—EMMELINE, ọdún kẹtàdínlógún [17] rèé tí òun àti ọkọ rẹ̀ ti kọ ara wọn.

Àwọn kan rò pé tí àwọn bá kọ ẹni tí àwọn ń fẹ́ sílẹ̀, ìyẹn á mú kí ayé àwọn dára sí i. Ní ti àwọn míì, kò wù wọ́n kí ìgbéyàwó wọn tú ká, síbẹ̀ wọn ò lè fipá mú ẹnì kejì wọn kó má lọ. Àmọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn tó kọ ara wọn sílẹ̀ ló pa dà wá rí i pé nǹkan le fún àwọn lẹ́yìn ìkọ̀sílẹ̀ ju bí àwọn ṣe rò lọ. Tó bá jẹ́ pé àìpẹ́ yìí ni ìwọ àti ẹni tí ò ń fẹ́ kọ ara yín sílẹ̀, ó ṣeé ṣe kí o ti rí i pé ìkọ̀sílẹ̀ wà lára ohun tó le jù láti fara dà. Á dáa ká jọ ṣàyẹ̀wò àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tí ìkọ̀sílẹ̀ máa ń fà.

ÌṢÒRO KÌÍNÍ: ÈRÒ ÒDÌ.

Ìdààmú tí ìṣòro owó, ọmọ títọ́ àti ìdánìkanwà máa ń fà fúnni kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ, irú èrò bẹ́ẹ̀ kì í sì í kúrò lọ́kàn bọ̀rọ̀. Judith Wallerstein tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìrònú àti ìwà ẹ̀dá sọ pé ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí tọkọtaya bá kọ ara wọn sílẹ̀ ni wọ́n á ṣì máa rò ó pé ẹnì kejì já àwọn jù sílẹ̀ tàbí pé ó dalẹ̀ àwọn. Wọ́n tiẹ̀ lè rò pé ṣe ni ìgbésí ayé kún fún ìjákulẹ̀, ìṣòro àti ìdánìkanwà.”

OHUN TÓ O LÈ ṢE

  • Má ṣe bo ìbànújẹ́ mọ́ra. Tí o bá ṣì nífẹ̀ẹ́ ẹni tí ẹ ti jọ kọ ara yín sílẹ̀, àárò rẹ̀ á ṣì máa sọ ẹ́. Kódà, kí àárín ẹ̀yin méjèèjì máà gún nígbà tí ẹ wà pa pọ̀, ó ṣì lè máa dùn ẹ́ gan-an pé o kò láyọ̀ bó o ṣe rò pé wàá ní nínú ìgbéyàwó. (Òwe 5:18) Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kí o sunkún má ṣe pa ẹkún yẹn mọ́ra nítorí ìtìjú, torí pé “ìgbà sísunkún” wà.—Oníwàásù 3:1, 4.

  • Má ṣé máa dá wà. Lóòótọ́, ó lè wù ẹ́ pé kó o dá wà kí o lè dárò ohun tó ṣẹlẹ̀. Àmọ́ dídáwà yẹn kò tún gbọ́dọ̀ pọ̀ jù. (Òwe 18:1) Gbìyànjú kó o máa sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró tó o bá wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, torí bí o bá ń ṣàròyé ṣáá nípa ẹni tí ò ń fẹ́ tẹ́lẹ̀, o lè mú kí ọ̀rọ̀ náà sú àwọn tí ò ń rojọ́ fún, wọ́n tiẹ̀ lè máa yẹra fún ẹ tó bá yá. Tó bá pọn dandan kó o ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì kan lẹ́yìn ìkọ̀sílẹ̀, á dáa kó o kọ́kọ́ gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ ẹnì kan tí o fọkàn tán.

  • Máa tọ́jú ara rẹ. Ìkọ̀sílẹ̀ sábà máa ń fa àárẹ̀ síni lára, irú bí ẹ̀jẹ̀ ríru tàbí akọ ẹ̀fọ́rí, ìyẹn túúlu. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kí o máa jẹun déédéé, kí o máa ṣeré ìmárale, kí o sì máa sùn dáadáa.—Éfésù 5:29.

  • Kó àwọn nǹkan tó lè mú kí inú ẹni tí ẹ jọ kọ ara yín sílẹ̀ máa bí ẹ kúrò nítòsí, tó fi mọ́ àwọn nǹkan tí o kò nílò mọ́. Àmọ́, tọ́jú àwọn ìwé ìsọfúnni tó ṣe pàtàkì. Tí o bá mọ̀ pé gbogbo ìgbà tó o bá ń rí fọ́tò ìgbéyàwó rẹ ni ọkàn rẹ á máa bà jẹ́, á dáa kí o palẹ̀ rẹ̀ mọ́ kí o sì tọ́jú wọn fún àwọn ọmọ rẹ.

  • Yẹra fún èrò tí kò tọ́. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Olga kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ torí pé ó ṣe panṣágà. Ó ní: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń bi ara mi pé, ‘kí ló wà lára obìnrin yẹn tí kò sí lára mi?’” Àmọ́ Olga wá rí i pé tí òun bá ń gba èrò òdì yìí láyè òun á kàn máa fa ‘ìdààmú bá ẹ̀mí’ ara òun ni.—Òwe 18:14.

    Àwọn míì ti wá rí i pé tí àwọn bá ń kọ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn sínú ìwé, ọkàn àwọn máa ń balẹ̀, ara sì máa ń tu àwọn. Àmọ́ bí o bá pinnu láti máa kọ èrò rẹ sílẹ̀, á dáa kí o máa kọ èrò tó dáa tó o fẹ́ fi rọ́pò èrò òdì tó o ní tẹ́lẹ̀. (Éfésù 4:23) Gbé àpẹẹrẹ méjì yìí yẹ̀ wò:

    Èrò òdì: Èmi ni mo fà á ti ẹnì kejì mi fi lọ hùwà àìṣòótọ́.

    Èrò tó dáa: Ká ní mo tiẹ̀ níwà kan tí kò dáa, ẹnì kejì mi ò lẹ́tọ̀ọ́ láti tìtorí ìyẹn ṣèṣekúṣe.

    Èrò òdì: Ó dà bíi pé mo ṣi ọkọ fẹ́, mo kàn fi gbogbo àkókò tó yẹ kí n fi ṣe nǹkan gidi láyé mi ṣòfò lọ́dọ̀ rẹ̀ ni.

    Èrò tó dáa: Ohun tó lè múnú mi dùn ni pé kí n gbà pé ohun tó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀, kí n sì máa gbé ayé mi lọ.

  • Má ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ tó ń duni. Bí àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ wa bá tiẹ̀ fẹ́ràn wa, wọ́n lè sọ̀rọ̀ tó máa dùn wá. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè sọ pé: ‘Kò tiẹ̀ yẹ kí o fẹ́ irú obìnrin yẹn tẹ́lẹ̀,’ tàbí kí wọ́n sọ pé ‘Ọlọ́run kórìíra ìkọ̀sílẹ̀.’ * Ìmọ̀ràn Bíbélì ni pé: “Má fi ọkàn-àyà rẹ sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn lè máa sọ.” (Oníwàásù 7:21) Obìnrin kan tó ń jẹ́ Martina tí òun àti ọkọ rẹ̀ kọ ara wọn sílẹ̀ lọ́dún méjì sẹ́yìn, sọ pé: “Dípò kí n máa ro àròdùn lórí ọ̀rọ̀ tó ń duni tí wọ́n bá sọ sí mi, ṣe ni mo máa ń gbìyànjú láti máa wo nǹkan bí Ọlọ́run ṣe máa wò ó. Torí pé ìrònú tirẹ̀ ga ju tiwa lọ.”—Aísáyà 55:8, 9.

  • Máa Gbàdúrà sí Ọlọ́run. Ọlọ́run rọ àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘kó gbogbo àníyàn wọn lé òun,’ pàápàá lákòókò tí wọ́n bá ní ìdààmú ọkàn.—1 Pétérù 5:7.

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè gbé ẹ ró, kó o sì lẹ̀ wọ́n mọ́ ibi tí wàá ti máa rí i déédéé. Yàtọ̀ sí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a ti mẹ́nu bà tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ti kọ ara wọn sílẹ̀ ti jàǹfààní gan-an nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì bíi: Sáàmù 27:10; 34:18; Aísáyà 41:10; Róòmù 8:38, 39.

Jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tù ẹ́ nínú lásìkò ìṣòro

ÌṢÒRO KEJÌ: KÒ RỌRÙN FÚN Ẹ LÁTI MÁA BÁ ẸNI TÍ Ò Ń  FẸ́ TẸ́LẸ̀ SỌ̀RỌ̀.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Juliana, tó lo ọdún mọ́kànlá [11] nílé ọkọ sọ pé: “Mo bẹ ọkọ mi pé kó má kọ̀ mí sílẹ̀, àmọ́ ó kọ̀ mi. Inú òun àti obìnrin tí ó lọ fẹ́ ń bí mi gan-an ni.” Bí ọ̀pọ̀ àwọn tó ti kọ ara wọn ṣe máa ń bínú sí ara wọn nìyẹn, kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n bá ti fi ara wọn sílẹ̀. Àmọ́ tí ọmọ bá ti wà láàárín àwọn méjèèjì, kò sí bí wọn ò ṣe ní máa bá ara wọn sọ̀rọ̀.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

  • Máa bá ẹni tó o fẹ́ tẹ́lẹ̀ sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àwọn ohun tó bá pọn dandan nìkan ni kẹ́ ẹ máa sọ, sì jẹ́ kó mọ níwọ̀n. Ọ̀pọ̀ tí rí i pé ìmọ̀ràn yìí mú kí àlàáfíà wà láàárín àwọn.—Róòmù 12:18.

  • Má ṣe máa sọ̀rọ̀ burúkú sí ẹni tó o fẹ́ tẹ́lẹ̀. Tó bá ṣe ohun tó múnú bí ẹ, máa rántí ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fawọ́ àwọn àsọjáde rẹ̀ sẹ́yìn kún fún ìmọ̀.” (Òwe 17:27) Tí ẹ bá jọ ń sọ̀rọ̀, tí ó sì ti ń di àríyànjiyàn, tọ́rọ̀ náà ò sì fẹ́ lójú mọ́, o lè sọ pé: “Màá lọ ronú sí ọ̀rọ̀ yẹn, àá tún máa ríra nígbà míì.”

  • Rí i pé gbogbo àkọsílẹ̀ tó dà yín pọ̀ tẹ́lẹ̀ lo fòpin sí, irú bí ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òfin, ìnáwó àti àkọsílẹ̀ ní ilé ìwòsàn.

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Nígbà míì tó o bá tún bá ẹni tó o fẹ́ tẹ́lẹ̀ sọ̀rọ̀, fara balẹ̀ kíyè sí i bóyá ẹnì kan nínú ẹ̀yin méjèèjì ti le koko jù tàbí ń wí àwíjàre. Tó bá gba pé kí ẹ fúnra yín láyè díẹ̀, ẹ lè pinnu láti máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ara yín lórí fóònù tàbí íńtánẹ́ẹ̀tì dípò kí ẹ bá ara yín sọ̀rọ̀ lójú kojú.—Òwe 17:14.

ÌṢÒRO KẸTA: KÒ RỌRÙN FÁWỌN ỌMỌ LÁTI GBÀGBÉ ÌṢẸLẸ̀ YẸN.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Maria sọ bí nǹkan ṣe rí lẹ́yìn tí òun àti ọkọ rẹ̀ kọ ara wọn sílẹ̀, ó ní: “Gbogbo ìgbà ni ọmọbìnrin mi kékeré máa ń sunkún, bó ṣe tún bẹ̀rẹ̀ sí í tọ̀ sílé nìyẹn. Ọmọbìnrin mi àgbà náà kì í fẹ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún mi.” Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé ìgbà tí àwọn ọmọ rẹ máa nílò rẹ gan-an ni wàá máa rò ó pé o kò ráyè tàbí pé kò sí ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

  • Rọ àwọn ọmọ rẹ kí wọ́n máa bá ẹ sọ̀rọ̀ kódà tó o bá tiẹ̀ wò ó pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ ju ẹnu wọn lọ.—Jóòbù 6:2, 3.

  • Má gbàgbé bí o ṣe jẹ́ sí àwọn ọmọ rẹ. Ó lè wù ẹ́ pé kí o rí ẹni fọ̀rọ̀ lọ̀, àwọn ọmọ rẹ sì lè fẹ́ kó o fi àwọn ṣe alábàárò rẹ. Àmọ́, ìyẹn kò bá a mu rárá, torí pé kò dáa kí àwọn ọmọ kéékèèké máa kó ìṣòro àgbàlagbà lé ọkàn. (1 Kọ́ríńtì 13:11) Má sẹ sọ àwọn ọmọ rẹ tó ṣì kéré di alábàárò rẹ tàbí kí ìwọ àti ẹni tó o fẹ́ tẹ́lẹ̀ wá máa rán ọmọ sí ara yín.

  • Jẹ́ kí ayé ọmọ rẹ ní ìtumọ̀. Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, o ṣì lè wà nílé tí ẹ̀ ń gbé tẹ́lẹ̀, kó o sì máa bá ìgbòkègbodò tẹ́ ẹ máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ lọ. Ó tún ṣe pàtàkì pé kó o má ṣe jáwọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run, kí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ máa ka Bíbélì kẹ́ ẹ sì máa jọ́sìn Ọlọ́run pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé.—Diutarónómì 6:6-9.

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Láàárín ọ̀sẹ̀ yìí, ṣe ohun tó máa jẹ́ kó dá àwọn ọmọ rẹ lójú pé o nífẹ̀ẹ́ wọn. Ó tún yẹ kó o jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn kọ́ ló fa ìkọ̀sílẹ̀ tó wáyé láàárín ìwọ àti bàbá tàbí ìyá wọn. Gbogbo ìbéèrè tí wọ́n bá bi ẹ́ ni kó o dáhùn, má ṣe sọ̀rọ̀ ìyá tàbí bàbá wọn láìdáa.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti kọ ara yín sílẹ̀, o ṣì lè máa gbé ayé rẹ lọ. Ọdún mẹ́rìndínlógún [16] ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Melissa fi wà nílé ọkọ, ó sọ pé: “Nígbà tí èmi àti ọkọ mi kọ ara wa sílẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé, ‘kì í ṣe báyìí ni mo fẹ́ kí ayé mi rí.’” Àmọ́ ní báyìí, ó ń gbé ayé rẹ̀ nìṣó láìka ti ipò tó wà sí. Ó tún sọ pé: “Mi ò yọ ara mi lẹ́nu mọ́, mo ti gbà pé ohun tó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀, látìgbà yẹn ni ọkàn mi ti fúyẹ́.”

^ ìpínrọ̀ 2 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

^ ìpínrọ̀ 18 Ọlọ́run kórìíra kí tọkọtaya fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kọ ara wọn sílẹ̀. Ṣùgbọ́n tí ẹnì kan nínú wọn bá ṣe panṣágà, Ọlọ́run fún ẹnì kejì lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu bóyá kí òun kọ̀ ọ́ sílẹ̀. (Málákì 2:16; Mátíù 19:9) Àlàyé síwájú sí i wà nínú àkòrí náà “Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀ àti Ìpínyà” nínú àfikún tó wà ní apá ìparí ìwé Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run, ojú ìwé 219-221. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

BI ARA RẸ PÉ . . .

  • Ǹjẹ́ mo ti fún ara mi ní àkókò tó pọ̀ tó láti ronú lórí bí ìkọ̀sílẹ̀ náà ṣe dùn mí?

  • Kí ni mo lè ṣe tí mi ò fi ní máa bínú sí ẹni tí mò ń fẹ́ tẹ́lẹ̀?