Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ KẸTA

Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Yanjú Ìṣòro

Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Yanjú Ìṣòro

“Ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.”1 Pétérù 4:8

Onírúurú ìṣòro ló máa ń yọjú bí tọkọtaya bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í jọ gbé. Ó lè jẹ́ nítorí ìyàtọ̀ tó wà nínú bí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ṣe ń ronú, bí nǹkan ṣe ń rí lára yín tàbí ọ̀nà tí ẹ ń gbà ṣe nǹkan. Àwọn ẹlòmíì tàbí ohun kan tí ẹ kò rò tẹ́lẹ̀ sì tún lè fa ìṣòro.

Ó lè ṣe ẹ́ bíi pé kó o má ṣe sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro náà, àmọ́ Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká má ṣe gbójú fo ìṣòro wa. (Mátíù 5:23, 24) Tí o bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, o máa rí ojútùú tó dára jù sí àwọn ìṣòro rẹ.

1 Ẹ JỌ SỌ̀RỌ̀ NÍPA ÌṢÒRO NÁÀ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: ‘Ìgbà sísọ̀rọ̀ wà.’ (Oníwàásù 3:1, 7) Ẹ rí i pé ẹ fara balẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro náà. Má ṣe fi ọ̀rọ̀ pa mọ́, sọ bó ṣe rí lára rẹ fún ẹnì kejì rẹ, sì jẹ́ kó mọ èrò rẹ nípa ìṣòro náà. “Òtítọ́” ni kí ẹ máa bá ara yín sọ nígbà gbogbo. (Éfésù 4:25) Tí ọ̀rọ̀ náà bá tiẹ̀ ká ọ lára gan-an, rí i dájú pé o kò bá ọkọ tàbí aya rẹ jà. Tí ẹ bá ń fi ohùn pẹ̀lẹ́ fún ara yín lésì, èyí kò ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tó yẹ kí ẹ fi ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ yanjú wá di ìjà.Òwe 15:4; 26:20.

Kódà, bí o kò bá fara mọ́ èrò ẹnì kejì rẹ, má ṣe sọ̀rọ̀ tí kò dáa. Máa fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí aya rẹ, kí o sì máa bọ̀wọ̀ fún un. (Kólósè 4:6) Ẹ tètè máa yanjú ọ̀rọ̀ tó bá yọjú, ẹ má sì ṣe bára yín yodì.Éfésù 4:26.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Wá àyè sígbà tó máa rọrùn fún ẹ̀yin méjèèjì láti jọ sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro náà

  • Fetí sílẹ̀, má ṣe dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọkọ tàbí aya rẹ lẹ́nu nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́. Ìwọ náà ṣì máa sọ tìẹ

2 FETÍ SÍLẸ̀ KÍ O SÌ LÓYE Ọ̀RỌ̀ NÁÀ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Bí o ṣe ń fetí sílẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an. Gbìyànjú láti mọ èrò ẹnì kejì rẹ, kí o lo ‘ojú àánú àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.’ (1 Pétérù 3:8; Jákọ́bù 1:19, Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀) Má kàn díbọ́n bíi pé ò ń gbọ́ ohun tó ń sọ. Tó bá ṣeé ṣe, pa ohun tí ò ń ṣe lọ́wọ́ tì kí o lè fetí sílẹ̀ dáadáa sí ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ fẹ́ sọ, o sì lè bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí ẹ sọ ọ̀rọ̀ náà nìgbà míì. Tí ẹ bá jọ ń yanjú ìṣòro dípò kí ẹ máa bára yín fa ọ̀rọ̀, ẹ kò ní máa ‘yára bínú.’Oníwàásù 7:9, Bíbélì Mímọ́.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Rí i dájú pé ò ń fọkàn sí ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ bá ń sọ, kódà bí ohun tí ò ń gbọ́ kò bá tẹ́ ọ lọ́rùn

  • Ohun tó ní lọ́kàn gan-an ni kí o fọkàn sí, kì í wulẹ̀ ṣe bó ṣe sọ̀rọ̀. Máa kíyè sí ohùn rẹ̀, ìṣesí rẹ̀ àti ìrísí ojú rẹ̀

3 Ẹ MÁA ṢIṢẸ́ LÓRÍ OHUN TÍ Ẹ JỌ SỌ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Nípasẹ̀ onírúurú làálàá gbogbo ni àǹfààní fi máa ń wà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ [ẹnu] lásán-làsàn máa ń [já] sí àìní.” (Òwe 14:23) Ẹ má wulẹ̀ fi ọ̀rọ̀ mọ sí wíwá ojútùú nìkan. Ó yẹ kí ẹ máa ṣiṣẹ́ lórí ohun tí ẹ bá jọ pinnu. Èyí lè gba pé kí ẹ ṣiṣẹ́ kára, kí ẹ sì sapá gan-an, àmọ́ ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. (Òwe 10:4) Tí ẹ bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú ohun gbogbo, ẹ máa “ní ẹ̀san rere fún iṣẹ́ àṣekára” yín.Oníwàásù 4:9.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Ẹ pinnu ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín máa ṣe kí ẹ lè yanjú ìṣòro náà

  • Ẹ máa ṣàyẹ̀wò àtúnṣe tí ẹ̀ ń ṣe látìgbàdégbà