Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run?

Ta Ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run?

Ọlọ́run darí àwọn tó kọ Bíbélì láti ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìsọfúnni pàtàkì kan tó máa jẹ́ ká mọ ẹni tó máa jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Ohun tí Bíbélì sọ nípa Alákòóso yẹn rèé:

  • Ọlọ́run ló máa yàn án. ‘Èmi fúnra mi ti fi ọba mi jẹ. Màá fi gbogbo ìkángun ayé ṣe ohun ìní fún ọ.’​—Sáàmù 2:6, 8.

  • Òun ló máa jogún ìtẹ́ Ọba Dáfídì. “A ti bí ọmọ kan fún wa, a ti fún wa ní ọmọkùnrin kan . . . Àkóso rẹ̀ á máa gbilẹ̀ títí lọ, àlàáfíà kò sì ní lópin, lórí ìtẹ́ Dáfídì àti lórí ìjọba rẹ̀, kó lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in.”​—Àìsáyà 9:6, 7.

  • Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n máa bí i sí. ‘Ìwọ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, inú rẹ ni ẹni tí mo fẹ́ kó ṣàkóso ti máa jáde wá. Àwọn èèyàn máa mọ̀ ní gbogbo ìkángun ayé pé ó tóbi lọ́ba.’​—Míkà 5:2, 4.

  • Àwọn èèyàn máa kórìíra rẹ̀, wọ́n á sì pa á. “Wọ́n kórìíra rẹ̀, a sì kà á sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan. . . . Wọ́n gún un torí àṣìṣe wa; wọ́n tẹ̀ ẹ́ rẹ́ torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”​—Àìsáyà 53:3, 5.

  • Ọlọ́run máa jí i dìde, ó sì máa ṣe é lógo. ‘Torí o ò ní fi mí sílẹ̀ nínú Isà Òkú. O ò ní jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí kòtò. Ìdùnnú wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ títí láé.’​—Sáàmù 16:10, 11.

Jésù Kristi Ló Kúnjú Ìwọ̀n Jù Lọ Láti Jẹ́ Alákòóso

Nínú gbogbo aráyé, ẹnì kan ṣoṣo ló bá ohun tí Bíbélì sọ mu nípa Alákòóso tó kúnjú ìwọ̀n jù lọ. Jésù Kristi ni ẹni náà. Kódà, áńgẹ́lì kan ti sọ fún Màríà ìyá Jésù pé: “Ọlọ́run máa fún [Jésù] ní ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀, . . . Ìjọba rẹ̀ ò sì ní lópin.”​—Lúùkù 1:31-33.

Jésù ò fìgbà kan rí ṣàkóso ayé yìí nígbà tó wà láyé. Àmọ́, ó máa ṣàkóso gbogbo ayé láti ọ̀run torí pé òun ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jésù Kristi ló kúnjú ìwọ̀n jù lọ láti jẹ́ Alákòóso? Jẹ́ ká wo àwọn ohun tó ṣe nígbà tó wà láyé.

  • Jésù bójú tó àwọn èèyàn. Jésù ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà, láìka ibi tí wọ́n ti wá sí àti ipò wọn láwùjọ. (Mátíù 9:36; Máàkù 10:16) Nígbà kan tí adẹ́tẹ̀ kan bẹ̀ ẹ́ pé: “Tí o bá ṣáà ti fẹ́, o lè jẹ́ kí n mọ́,” àánú rẹ̀ ṣe Jésù, ó sì mú un lára dá.​—Máàkù 1:40-42.

  • Jésù kọ́ wa bá a ṣe lè máa ṣèfẹ́ Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ẹ ò lè sin Ọlọ́run àti Ọrọ̀.” Ó tún sọ fún wa pé ohun tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣe sí wa ni ká máa ṣe sí wọn, èyí tá a lè pè ní Òfin Pàtàkì. Yàtọ̀ síyẹn, ó jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe ohun tí à ń ṣe nìkan ni Ọlọ́run ń wò, ó tún ń wo ohun tí à ń rò àti bọ́rọ̀ ṣe ń rí lára wa. Torí náà, ká lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, a gbọ́dọ̀ máa kó ara wa àti èrò wa níjàánu. (Mátíù 5:28; 6:24; 7:12) Jésù wá tẹnu mọ́ ọn pé ká tó lè láyọ̀ tòótọ́, a gbọ́dọ̀ mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ká sì máa ṣe é.​—Lúùkù 11:28.

  • Jésù kọ́ wa pé ká máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ọ̀rọ̀ Jésù wọ àwọn èèyàn lọ́kàn gan-an, ìwà rẹ̀ sì wú wọn lórí. Bíbélì sọ pé: “Bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ya àwọn èrò náà lẹ́nu, torí ṣe ló ń kọ́ wọn bí ẹni tó ní àṣẹ.” (Mátíù 7:​28, 29) Ó kọ́ wọn pé: “Ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín.” Kódà ó gbàdúrà fún àwọn kan lára àwọn tó pa á, ó ní: “Baba, dárí jì wọ́n, torí wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.”​—Mátíù 5:44; Lúùkù 23:34.

Jésù ló kúnjú ìwọ̀n jù lọ láti jẹ́ Alákòóso ayé torí pé ó láàánú, ó sì ń ranni lọ́wọ́. Àmọ́, ìgbà wo ló máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé?