Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣàkóso Ayé?

Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣàkóso Ayé?

Àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ fẹ́ mọ ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé. Jésù dá wọn lóhùn pé wọn ò lè mọ àkókò pàtó tí Ìjọba náà máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé. (Ìṣe 1:​6, 7) Àmọ́, ó ti sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tẹ́lẹ̀ pé tí wọ́n bá rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò kan náà, kí wọ́n “mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé” àti pé àkókò tó máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé ti dé.​—Lúùkù 21:31.

ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ WO NI JÉSÙ SỌ PÉ Ó MÁA ṢẸLẸ̀? 

Jésù sọ pé: “Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba. Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára máa ṣẹlẹ̀, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.” (Lúùkù 21:​10, 11) Gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lápapọ̀, tó sì ń ṣẹlẹ̀ lákòókò kan náà jẹ́ àmì tó hàn kedere pé “Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé.” Ṣé lóòótọ́ làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ń ṣẹlẹ̀ lákòókò kan náà, tó sì kárí ayé? Jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀rí tó fi hàn bẹ́ẹ̀.

1. OGUN

Lọ́dún 1914, ogun kan jà kárí ayé tá ò rí irú rẹ̀ rí! Àwọn òpìtàn sábà máa ń tọ́ka sí ọdún 1914 pé ó jẹ́ ọdún tí gbogbo nǹkan yí pa dà láyé, torí pé ìgbà yẹn ni ogún àgbáyé kìíní bẹ̀rẹ̀. Ìgbà yẹn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn nǹkan ìjà lọ́nà tó bùáyà, àwọn nǹkan bí ọkọ̀ ogun tó ń rọ̀jò bọ́ǹbù, bọ́ǹbù tí wọ́n ń jù látojú òfúrufú, ẹ̀rọ arọ̀jò ọta, gáàsì gbẹ̀mígbẹ̀mí àtàwọn ohun ìjà afẹ̀míṣòfò míì. Lẹ́yìn ìyẹn ni ogun àgbáyé kejì jà, ìgbà yẹn sì ni wọ́n kọ́kọ́ ṣe bọ́ǹbù runlérùnnà. Láti ọdún 1914 ni aráyé ti ń ti inú ogun kan bọ́ sínú òmíràn, àìmọye èèyàn ni àwọn ogun náà sì ti pa.

2. ÌMÌTÌTÌ ILẸ̀

Ìwé Britannica Academic sọ pé nǹkan bí ọgọ́rùn-ún (100) ìmìtìtì ilẹ̀ tó ń fa “jàǹbá tó pọ̀” ló ń ṣẹlẹ̀ lọ́dọọdún. Ìròyìn kan tí àjọ tó ń bójú tó ilẹ̀ àtohun tó wà nínú ilẹ̀, ìyẹn United States Geological Survey, gbé jáde sọ pé “àwọn àkọsílẹ̀ tó ti wà tipẹ́ (láti nǹkan bí ọdún 1900) fi hàn pé nǹkan bí ìmìtìtì ilẹ̀ mẹ́rìndínlógún (16) tó kàmàmà láá máa ṣẹlẹ̀ lọ́dọọdún.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan rò pé ohun tó mú kó jọ pé ìmìtìtì ilẹ̀ ń pọ̀ sí i ni pé àwọn ẹ̀rọ ti wà báyìí tó ń jẹ́ kí wọ́n tètè mọ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà fẹ́ ṣẹlẹ̀. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ìmìtìtì ilẹ̀ tó kàmàmà ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé, wọ́n ń fa ìpalára, wọ́n sì ń gbẹ̀mí èèyàn ju ti ìgbàkígbà rí lọ.

3. ÀÌTÓ OÚNJẸ

Àwọn ohun tó máa ń fa àìtó oúnjẹ kárí ayé ni ogun, ìwà ìbàjẹ́, ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀, àìfọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ àgbẹ̀ tàbí àìsí ètò tó yẹ nípa ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà. Ìròyìn kan tí Àjọ Tó Ń Bójútó Ọ̀rọ̀ Oúnjẹ Lágbàáyé gbé jáde lọ́dún 2018 sọ pé: “Kárí ayé, àwọn èèyàn tí ó tó mílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé mọ́kànlélógún (821,000,000) ni kò rí oúnjẹ tí ó tó jẹ, mílíọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gọ́fà (124,000,000) nínú wọn ni kò sì rí oúnjẹ jẹ rárá.” Àìjẹunrekánú wà lára ohun tó ń ṣekú pa nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (3,100,000) ọmọdé lọ́dọọdún. Ìyẹn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó nǹkan bí ìdajì iye àwọn ọmọdé tó kú kárí ayé lọ́dún 2011.

4. ÀÌSÀN ÀTI ÀJÀKÁLẸ̀ ÀRÙN

Ìwé kan látọwọ́ Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé:  “Àwọn àjàkálẹ̀ àrùn ńláńlá ti han aráyé léèmọ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkànlélógún yìí. Àwọn àìsàn tá ò fi bẹ́ẹ̀ gbúròó mọ́ bíi kọ́lẹ́rà, ibà pọ́njú àtàwọn àìsàn burúkú míì tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í jà ràn-ìn báyìí, àwọn àìsàn tuntun míì bí Ebola, ibà Zika, MERS, SARS àti àjàkálẹ̀ àrùn kan tí wọ́n ń pè ní pandemic influenza, ti bẹ́ sílẹ̀.” Àrùn kòrónà náà tún wá fọba lé e. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn dókítà mọ ohun tó pọ̀ nípa àìsàn, síbẹ̀ wọn ò tíì lè wo gbogbo àìsàn.

5. IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ KÁRÍ AYÉ

Jésù mẹ́nu kan apá míì nínú àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn nígbà tó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.” (Mátíù 24:14) Láìka bí ìṣòro ṣe ń pọ̀ sí i láyé, ohun tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè ló ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ogójì (240) ilẹ̀, tí wọ́n sì ń fi èdè tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000) wàásù. Èyí ò tíì ṣẹlẹ̀ rí nínú ìtàn aráyé.

KÍ NI ÀMÌ YÌÍ TÚMỌ̀ SÍ?

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Jésù sọ pé ó máa jẹ́ àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ti ń ṣẹlẹ̀ lónìí. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ̀ nípa wọn? Ìdí ni pé Jésù sọ pé: “Tí ẹ bá rí i tí àwọn nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé.”​—Lúùkù 21:31.

Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ láyé

Bá a ṣe ń rí àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ àti bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì sọ ṣe ń ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra, wọ́n jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ti gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ ní ọ̀run lọ́dún 1914. a Ìgbà yẹn ló fi Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ jẹ Ọba. (Sáàmù 2:2, 4, 6-9) Láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run yóò máa ṣàkóso ayé, ó máa mú gbogbo ìjọba tó wà lónìí kúrò, á sì sọ ayé di Párádísè táwọn èèyàn á máa gbé títí láé.

Láìpẹ́, Àdúrà Olúwa tí Jésù kọ́ wa máa ṣẹ, èyí tó sọ pé: “Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run.” (Mátíù 6:10) Kí ni Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣe látìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́dún 1914? Kí ni ká máa retí nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso gbogbo ayé?

a Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i nípa ọdún 1914, wo ẹ̀kọ́ 32 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.