Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

“Gbára Dì Pátápátá fún Gbogbo Iṣẹ́ Rere”!

A Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Tún Ṣe Jáde

“Gbára Dì Pátápátá fún Gbogbo Iṣẹ́ Rere”!

Lọ́jọ́ Saturday January 12, 2019, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti méjìléláàádọ́rin (60,672) làwọn tó gbádùn àkànṣe ìpàdé tá a ṣe àtagbà rẹ̀ láti Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà ní Benin City ní Nigeria, nígbà tí Arákùnrin Geoffrey Jackson, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe jáde lédè Yorùbá.

Ọdún 1997 ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń sọ èdè Yorùbá kọ́kọ́ rí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun gbà lódindi ní èdè wọn. * Látìgbà yẹn, a ti tẹ ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rùn-ún lé nírínwó (490,000) ẹ̀dà Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Yorùbá. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìlélógójì (42,000) tó ń sọ èdè Yorùbá, tí wọ́n wà kárí ayé ló sì ti lò ó. Àmọ́, kí nìdí tá a fi tún ìtumọ̀ Bíbélì yìí ṣe? Ta ló ṣe é jáde? Kí ló lè mú kó dá ẹ lójú pé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe yìí ṣeé gbára lé? Àwọn nǹkan wo ló wà nínú àtúnṣe yìí tó máa jẹ́ kó o lè “gbára dì pátápátá fún gbogbo iṣẹ́ rere”?​—2 Tímótì 3:​16, 17.

Kí nìdí tá a fi ṣàtúnṣe Bíbélì yìí?

Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, èdè máa ń yí pa dà, torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàtúnṣe àwọn ìtumọ̀ Bíbélì, kí àwọn èèyàn lè lòye ọ̀rọ̀ inú rẹ̀. Tá a bá fi àwọn ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn ò lò mọ́ túmọ̀ Bíbélì, kò ní fi bẹ́ẹ̀ wúlò fún ọ̀pọ̀ èèyàn.

Èdè táwọn èèyàn ń sọ, tó sì yé wọn dáadáa ni Jèhófà Ọlọ́run mú kí wọ́n fi kọ àwọn ìwé inú Bíbélì lọ́kọ̀ọ̀kan. Ìdí nìyẹn tí Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun fi mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì jáde ní oṣù October 2013. Ọ̀rọ̀ ìṣáájú inú ẹ̀dà Bíbélì yẹn lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Àfojúsùn wa ni pé ká túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lọ́nà tó bá àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ́kọ́ fi kọ Bíbélì mu, tó ṣe kedere, tó sì rọrùn láti kà.”

Bíbélì New World Translation of the Holy Scriptures​—⁠With References tá a ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 1984 la fi túmọ̀ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a kọ́kọ́ mú jáde lédè Yorùbá. Àwọn àtúnṣe tí wọ́n ṣe sí ìtumọ̀ Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì yẹn la ti wá ṣe sí ti èdè Yorùbá báyìí. A sì tún mú kí Bíbélì náà túbọ̀ rọrùn láti kà ní èdè Yorùbá.

Yàtọ̀ síyẹn, látìgbà tá a ti kọ́kọ́ mú Bíbélì yìí jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì, ọ̀pọ̀ ìyípadà ló ti dé bá bí a ṣe lóye èdè Hébérù, Árámáíkì àti èdè Gíríìkì tí wọ́n kọ́kọ́ fi kọ Bíbélì. Wọ́n tún ti ṣàwárí àwọn Bíbélì àfọwọ́kọ tó wà ṣáájú àwọn èyí tí a rí nígbà tá a kọ́kọ́ tẹ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde; àwọn Bíbélì àfọwọ́kọ yìí ti jẹ́ kí àwọn tó ń túmọ̀ Bíbélì lóye bí wọ́n ṣe ń ka àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀.

Torí náà, a tún àwọn ọ̀rọ̀ kan ṣe kó lè gbé ìtumọ̀ tí àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé ó bá àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nígbà tí wọ́n kọ́ Bíbélì mu. Bí àpẹẹrẹ, nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ kan, Mátíù 7:​13 kà pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé, torí ẹnubodè tó lọ sí ìparun fẹ̀, ọ̀nà ibẹ̀ gbòòrò.” Nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí à ń lò tẹ́lẹ̀, a ò mẹ́nu ba “ẹnubodè” lẹ́ẹ̀kejì, ṣe la kàn sọ pé “aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun.” Àmọ́, ìwádìí tá a tún ṣe látinú àwọn ìwé àfọwọ́kọ náà jẹ́ ká rí i pé “ẹnubodè tó lọ sí ìparun” ló wà nínú ìwé tí wọ́n kọ́kọ́ kọ. Torí náà, a fi ọ̀rọ̀ náà sí i nínú ẹ̀dà tí a tún ṣe. Irú àwọn àtúnṣe yìí tó bíi mélòó kan nínú Bíbélì náà. Àmọ́ ìkankan nínú àwọn àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tá a ṣe yìí kò yí kókó pàtàkì tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa dà.

Àwọn ìwádìí míì tí a ṣe tún jẹ́ ká rí àwọn ibi mẹ́fà míì tó yẹ kí Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run wà nínú Bíbélì. Ìyẹn nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́ 19:18 àti 1 Sámúẹ́lì 2:​25; 6:3; 10:26; 23:14, 16. Torí náà, ní báyìí orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, fara hàn nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì ní ìgbà ẹgbẹ̀rún méje ó lé igba àti mẹ́rìndínlógún (7,216). Iye ìgbà tí orúkọ náà fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì nìkan jẹ́ igba àti mẹ́tàdínlógójì (237).

Ta ló ṣe ìtumọ̀ Bíbélì náà jáde?

Àjọ tó ń ṣojú fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin, ìyẹn Watch Tower Bible and Tract Society ló ṣe Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde. Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń fún àwọn èèyàn kárí ayé ní Bíbélì. Ọdún 1950 sí 1960 ni Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun kọ́kọ́ mú ẹ̀dà Bíbélì náà jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà ò fẹ́ káwọn èèyàn kan sárá sí wọn, torí náà wọ́n ní kí wọ́n má jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ àwọn, kódà lẹ́yìn táwọn bá kú.​—1 Kọ́ríńtì 10:31.

Lọ́dún 2008, Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yan àwọn arákùnrin míì tó máa wà nínú Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun. Ojú ẹsẹ̀ ni ìgbìmọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí àtúnṣe náà lédè Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n ṣàyẹ̀wò àwọn ìyípadà tó ti bá èdè Gẹ̀ẹ́sì látìgbà tí wọ́n ti kọ́kọ́ mú Bíbélì náà jáde láti fi ṣe àwọn àtúnṣe náà. Wọ́n tún fara balẹ̀ wo àwọn ìdáhùn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin (70,000) tí wọ́n ti fún àwọn atúmọ̀ èdè tí wọ́n ti túmọ̀ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sí èdè tó lé ní ọgọ́fà (120).

Báwo la ṣe ṣàtúnṣe Bíbélì yìí lédè Yorùbá?

A kọ́kọ́ yan àwọn Kristẹni mélòó kan tí wọ́n ti yara wọn sí mímọ́ pé kí wọ́n jẹ́ ìgbìmọ̀ atúmọ̀ èdè. Àwọn ìrírí tá a ní ti jẹ́ ká rí i pé tí àwọn atúmọ̀ èdè bá jọ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ dípò kí ẹnì kan máa dá ṣiṣẹ́, èyí á mú kí iṣẹ́ wọn túbọ̀ dáa, kó má sì fì sápá kan. (Òwe 11:14) Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà ti ní ìrírí lẹ́nu iṣẹ́ ìtúmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, wọ́n gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó jíire nípa àwọn ìlànà tí a máa ń tẹ̀ lé tí a bá ń túmọ̀ Bíbélì àti bí wọ́n ṣe máa lo àwọn ètò orí kọ̀ǹpútà tá a dìídì ṣe fún iṣẹ́ ìtumọ̀ náà.

Bí àwọn atúmọ̀ èdè náà ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń lo ìmọ̀ ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà láti ṣe iṣẹ́ náà. Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Ìtúmọ̀, tó wà nílùú New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tún ran àwọn atúmọ̀ èdè lọ́wọ́. Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lo Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé tó wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀ láti darí iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì náà. Àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe ṣiṣẹ́ náà gan-an?

Wọ́n sọ fún àwọn atúmọ̀ èdè náà pé kí wọ́n rí i dájú pé (1) ìtumọ̀ Bíbélì náà péye, ó sì yé àwọn èèyàn títí kan àwọn tí kò mọ̀wé, (2) kí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ bára mu látòkè délẹ̀, (3) kó sì bá èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu tó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe àwọn nǹkan yìí? Jẹ́ ká wo ohun tí wọ́n ṣe nínú Bíbélì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde yìí. Àwọn atúmọ̀ èdè náà kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ èdè Yorùbá tó wà nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí à ń lò tẹ́lẹ̀. Ètò orí kọ̀ǹpútà tí à ń lò fún ìtumọ̀ èdè, ìyẹn Watchtower Translation System máa gbé àwọn ọ̀rọ̀ tó jọra àtàwọn èyí tó ní ìtumọ̀ kan náà jáde. Ó tún máa gbé àwọn ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tàbí ti Hébérù jáde, kí àwọn atúmọ̀ èdè lè wo bí wọ́n ṣe túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ náà nínú àwọn ẹsẹ míì. Gbogbo èyí ran àwọn atúmọ̀ èdè náà lọ́wọ́ gan-an láti mọ bí wọ́n ṣe máa túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ náà lédè Yorùbá. Yàtọ̀ sí èyí, bí àwọn atúmọ̀ èdè náà ṣe ń túmọ̀ ẹsẹ kan tẹ̀ lé òmíràn, wọ́n ń rí i dájú pé àwọn lo àwọn ọ̀rọ̀ tí kò lọ́jú pọ̀, tó sì máa tètè yé àwọn èèyàn lédè Yorùbá.

Torí náà, iṣẹ́ ìtumọ̀ kì í kàn ṣe pé ká máa fi ọ̀rọ̀ kan rọ́pò òmíràn. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ la ṣe ká lè rí i dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá tá a lò bá ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́ mu láwọn ibi tí a ti lò wọ́n. Iṣẹ́ àṣekára tí a ṣe láti túmọ̀ Bíbélì yìí hàn kedere nínú rẹ̀ lóòótọ́. Nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Yorùbá, a túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó bá àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ́kọ́ fi kọ Bíbélì mu, tó ṣe kedere, tó sì rọrùn láti kà.

A rọ̀ ẹ́ pé kó o fúnra rẹ ṣàyẹ̀wò Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. O lè kà á lórí ìkànnì wa tàbí lórí ètò ìṣiṣẹ́ JW Library, o sì lè ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí rẹ fún ẹ ní èyí tá a tẹ̀ sórí ìwé. Bó o ṣe ń kà á, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a túmọ̀ lọ́nà tó péye lò ń kà lédè rẹ̀.

Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Tún Ṣe

Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: Àwọn ẹsẹ Bíbélì mélòó kan wà níbẹ̀ tó dáhùn ogún (20) ìbéèrè tó dá lórí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí: Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé kọ̀ọ̀kan nínú Bíbélì, ó sọ àwọn ohun tó wà nínú àwọn ìwé náà ní ṣókí, ó sì máa jẹ́ kó o lè tètè rí àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì. Apá yìí la fi rọ́pò àwọn àkọlé tó máa ń wà lójú ìwé kọ̀ọ̀kan nínú Bíbélì tí à ń lò tẹ́lẹ̀

Atọ́ka Àárín Ìwé: Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó máa wúlò jù lóde ẹ̀rí nìkan ló wà níbẹ̀ báyìí

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé: Ó jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀rọ̀ míì tá a tún lè lò fún ọ̀rọ̀ tí a tọ́ka sí, àwọn ọ̀rọ̀ míì tó bá a mu tàbí ìsọfúnni nípa ọ̀rọ̀ tí a tọ́ka sí

Atọ́ka Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì: Àwọn ọ̀rọ̀ àtàwọn ẹsẹ Bíbélì tá a sábà máa ń lò fún iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni nìkan ló wà níbẹ̀ báyìí

Àlàyé Ọ̀rọ̀: Ó sọ ìtumọ̀ ṣókí nípa ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì

Àfikún A: Ó ṣàlàyé àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì tí a tún ṣe yìí, irú bí ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ ọ́ àtàwọn ọ̀rọ̀ tó ti yí pa dà àti bí ìtumọ̀ Bíbélì yìí ṣe lo orúkọ Ọlọ́run

Àfikún B: Ó ní apá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) tó ní àwọn àwòrán aláwọ̀ mèremère àtàwọn àwòrán ilẹ̀

^ ìpínrọ̀ 4 A mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Griki jáde lédè Yorùbá lọ́dún 1994.