Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Watch Tower Bible and Tract Society?

Kí Ni Watch Tower Bible and Tract Society?

 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ni àjọ tí kì í ṣe fún ìṣòwò tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá sílẹ̀ lábẹ́ òfin àjọ Commonwealth of Pennsylvania ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1884. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà là ń lo àjọ yìí láti fi ti iṣẹ́ tí à ń ṣe kárí ayé lẹ́yìn, tó ní nínú títẹ Bíbélì àti àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

 Ìdí tí a fi dá àjọ yìí sílẹ̀ bó ṣe wà nínú ìwé àṣẹ ìjọba jẹ́ torí “ìjọsìn, ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù dé bá.” Ní pàtàkì jù lọ, à ń lo àjọ yìí láti “kọ́ àwọn èèyàn ká sì wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù Kristi máa ṣàkóso rẹ̀.” Kì í ṣe bí èèyàn bá ṣe dáwó tó la fi ń yan àwọn tó máa wà nínú àjọ yìí, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la máa ń fìwé pe àwọn tó máa wà níbẹ̀. Àwọn tó wà nínú àjọ yìí àtàwọn alábòójútó rẹ̀ máa ń ran Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́.

Àwọn Àjọ Tá A Dá Sílẹ̀ Lábẹ́ Òfin

 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjọ tá a dá sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yàtọ̀ sí àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. Àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Watch Tower” tàbí “Watchtower” máa ń wà lára orúkọ àwọn kan lára àjọ tá a dá sílẹ̀ yìí tàbí kí wọ́n tú àwọn ọ̀rọ̀ yìí sínú orúkọ tí wọn lò lábẹ́ òfin.

 Àwọn onírúurú àjọ tí à ń lò yìí ti jẹ́ ká lè ṣe ọ̀pọ̀ àṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ wa látìgbà tá a ti dá wọn sílẹ̀, díẹ̀ lára ohun tá a ti ṣe láṣeyọrí nìyí:

  •   Ìwé kíkọ àti ìwé títẹ̀. A ti tẹ nǹkan bí igba ó lé ogun [220] mílíọ̀nù Bíbélì àti àwọn ìwé tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì [40] bílíọ̀nù ní èdè tó lé ní ẹgbẹ̀rún dín ọgọ́rún-ún [900]. Ìkànnì jw.org/yo ti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lè ka Bíbélì lórí íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́fẹ̀ẹ́ ní èdè tó lé ní ọgọ́jọ [160], kí wọ́n sì rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè Bíbélì, irú bíi “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

  •   Ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Oríṣiríṣi ilé ẹ̀kọ́ la ní tí a ti máa ń dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1943, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án [9,000] ló ti jàǹfààní nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, èyí sì ti mú kí wọ́n lè máa sìn bíi Míṣọ́nárì tàbí kí wọ́n sìn níbi tí wọ́n á ti lè mú kí iṣẹ́ náà fìdí múlẹ̀ kó sì máa tẹ̀ síwájú kárí ayé. Ọ̀pọ̀ èèyàn títí kan àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń dara pọ̀ láti gba ìtọ́ni lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láwọn ìpàdé wa. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń lo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kan tá a tẹ̀ ní èdè tó tó ọgọ́fà [120] láti fi kọ́ àwọn tí kò mọ̀wé kọ tàbí mọ̀ọ́kà.

  •   Ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù dé bá. A ti pèsè àwọn ohun ìgbẹ́mìíró fún àwọn èèyàn tí àjálù dé bá, bóyá àjálù yẹn jẹ́ àfọwọ́fà irú ogun kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Rwanda lọ́dún 1994 tàbí èyí tó kàn ṣàdédé ṣẹlẹ̀ irú bí ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé lórílẹ̀-èdè Haiti lọ́dún 2010.

 Àwọn àjọ yìí ti mú kí iṣẹ́ wa gbòòrò sí i lóòótọ́, àmọ́ kò túmọ̀ sí pé a ò lè dá nǹkan kan ṣe láìsí àwọn àjọ yìí. Iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé gbogbo àwa Kristẹni lọ́wọ́ ni láti kọ́ àwọn èèyàn kí a sì wàásù ìhìn rere, ojúṣe gbogbo àwa Kristẹni lẹ́nìkọ̀ọ̀kan sì ni èyí jẹ́. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) A gbà pé Ọlọ́run ló ń ti iṣẹ́ wa lẹ́yìn, yóò sì “mú kí ó máa dàgbà.”—1 Kọ́ríńtì 3:6, 7.