Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Wọ́n Ń Sin Jèhófà Láìka Bí Nǹkan Ṣe Le Tó Lórílẹ̀-Èdè Fẹnẹsúélà

Wọ́n Ń Sin Jèhófà Láìka Bí Nǹkan Ṣe Le Tó Lórílẹ̀-Èdè Fẹnẹsúélà

 Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, orílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà dojú kọ ipò ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ gan-an àti àìsí àwọn ohun amáyédẹrùn ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Edgar sọ pé, “Láàárín ọdún díẹ̀, ṣe ni ipò ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ gan-an tí ọ̀pọ̀ sì di aláìní, ó wá dà bíi pé ńṣe la kó lọ sí orílẹ̀-èdè míì, bẹ́ẹ̀ sì rèé a ò kúrò lórílẹ̀-èdè wa o!”

 Kí ló ran Edgar lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro yìí? Ó sọ pé: “Èmi àti Carmen ìyàwó mi ronú lórí àpẹẹrẹ àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n ń sìn láwọn ilẹ̀ tí nǹkan ò ti fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ṣọ̀mù, tí wọ́n sì ti fi kọ́ra láti máa gbé láìsí àwọn ohun amáyédẹrùn. Ìyẹn ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bá a ṣe lè jẹ́ ẹni tó mọwọ́ yí pa dà nínú ipò tá a bá ara wa yìí. Bí àpẹẹrẹ, àwa là ń gbin àwọn oúnjẹ wa báyìí.”

Carmen àti Edgar

 Ohun míì tí Edgar àti ìyàwó ẹ̀ ṣe ni pé, wọ́n ń tu àwọn ará nínú títí kan àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì. (1 Tẹsalóníkà 5:11) Edgar tún sọ pé, “Yàtọ̀ sí pé à ń tù wọ́n nínú, a tún fún wọ́n níṣìírí káwọn náà lè máa ran àwọn míì lọ́wọ́ torí ìyẹn máa fún wọn láyọ̀.”​—Ìṣe 20:35.

Jèhófà Bù Kún Ìsapá Ẹ̀ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù

 Nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà bẹ̀rẹ̀, Argenis pinnu láti wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀, lára wọn sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látorí fóònù.

Argenis

 Ó tún wu Argenis káwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ tí ò ní Íńtánẹ́ẹ̀tì gbádùn àpéjọ agbègbè ọdún 2020. Arákùnrin kan tó ń gbé nílùú tí ò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà bá wọn wa ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà jáde sórí ẹ̀rọ, ó sì fún wọn. Àwọn mọ̀lẹ́bí Argenis wá lọ yá tẹlifíṣọ̀n ńlá kan àti ẹ̀rọ ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ láti fi wo àpéjọ náà. Kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà tó bẹ̀rẹ̀, Argenis gbàdúrà pẹ̀lú wọn látorí fóònù. Torí pé Argenis ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe, mẹ́rin lára àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ àtàwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) míì ló wo àpéjọ náà.

Ìgbàgbọ́ àti Ìfẹ́ Mú Kí Wọ́n Ran Àwọn Míì Lọ́wọ́

 Jairo àti ìyàwó ẹ̀ tó ń jẹ́ Johana nìkan ló ní mọ́tò nínú ìjọ wọn, wọ́n sì máa ń fi ran àwọn míì lọ́wọ́. Àmọ́ ìṣòro kan tí wọ́n dojú kọ ni àtirí epo rà sí mọ́tò náà torí kò fi bẹ́ẹ̀ sí epo. Jairo sọ pé, “Ọ̀pọ̀ wákàtí la fi máa wà lórí ìlà ká tó lè rí epo rà, nígbà míì ibẹ̀ la máa wà títí di àárọ̀ ọjọ́ kejì.”

Johana àti Jairo

 Jairo gbà pé ìsapá wọn láti ran àwọn míì lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó sọ pé: “Tá a bá gbé ohun tí àwọn ará nílò lọ fún wọn, a máa ń rí i bí wọ́n ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà ẹni tó ń fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ohun tí wọ́n nílò, èyí sì ń fún wa láyọ̀ gan-an.”​—2 Kọ́ríńtì 9:​11, 14.

Kò Sẹ́ni Tí Ò Lè Ṣèrànwọ́

 Arábìnrin Norianni tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọgbọ̀n (28) ọdún rò pé àwọn èèyàn á máa fi ojú ọmọdé wo òun tóun bá fẹ́ ran àwọn míì lọ́wọ́. Àmọ́, ó ka ohun tó wà nínú 1 Tímótì 4:12 tó sọ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fojú ọmọdé wò ọ́ rárá. Àmọ́, kí o jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn olóòótọ́.”

Norianni

 Ẹsẹ Bíbélì yẹn fún Norianni níṣìírí láti sún mọ́ àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ìjọ tó ń dara pọ̀ mọ́, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi lẹ́tà wàásù tàbí kí wọ́n jọ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń pè wọ́n, á sì fi ọ̀rọ̀ ìṣírí ránṣẹ́ sí wọn lórí fóònù. Norianni sọ pé, “Jèhófà ti jẹ́ kí n rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo lè ṣe.”

 Ọ̀pọ̀ ìṣòro làwọn ará wa ní lórílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà lásìkò tí nǹkan le gan-an yìí. Bó ti wù kó rí, wọ́n ń fìtara wàásù nìṣó, wọ́n sì jẹ́ “orísun ìtùnú” fún ara wọn.​—Kólósè 4:11; 2 Tímótì 4:2.