Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

“Mo Fẹ́ràn Ìjà Kọnfú Gan-an”

“Mo Fẹ́ràn Ìjà Kọnfú Gan-an”
  • Ọdún Tí Wọ́n Bí Mi: 1962

  • Orílẹ̀-Èdè Mi: Amẹ́ríkà

  • Irú Ẹni Tí Mo Jẹ́ Tẹ́lẹ̀: Oníjà kọnfú

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ

 Mi ò mọ̀ pé mo lè ṣe ẹni tí mò ń kọ́ níjà kọnfú léṣe tó báyìí. Bí mo ṣe ní kí n fún un nípàá, mi ò mọ̀ rárá pé imú ẹ̀ ló máa bà. Ó dùn mí gan-an, mo wá ń ronú pé á dáa kí n má ja kọnfú mọ́. Kí nìdí náà gan-an tí mo fi ń ronú àtipa eré tí mo fẹ́ràn tì torí àṣìṣe tí mo ṣe yìí, tó sì jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni mo ti wà lẹ́nu ẹ̀? Ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ ṣàlàyé ohun tó jẹ́ kí n máa ja kọnfú.

 Ìtòsí ìlú Buffalo, ní New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni mo dàgbà sí. Inú ìdílé tí àlàáfíà wà, tí wọn ò sì fẹ̀sìn ṣeré ni wọ́n bí mi sí. Kátólíìkì làwọn òbí mi, torí náà, ilé ẹ̀kọ́ Kátólíìkì ni mo lọ, mo sì tún máa ń ran àwọn Fadá lọ́wọ́ nídìí pẹpẹ. Àwọn òbí mi fẹ́ kí èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin dẹni ńlá. Torí náà, wọ́n fún mi láyè láti kópa nínú àwọn eré ìdárayá tá a máa ń ṣe lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́, wọ́n sì gbà mí láyè láti ṣiṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́, àmọ́ wọ́n jẹ́ kí n mọ̀ pé mo gbọ́dọ̀ fakọ yọ nínú ẹ̀kọ́ mi. Ìyẹn wá mú kí n kọ́ béèyàn ṣe ń sẹ́ra ẹni láti kékeré.

 Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17), mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìjà kọnfú. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, mo máa ń fi wákàtí mẹ́ta lóòjọ́ kọ́ ìjà, mo sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ mẹ́fà lọ́sẹ̀. Mo tún máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti ronú lórí oríṣiríṣi ìjà àtàwọn ọ̀nà tuntun tí mo lè gbà gbé ọwọ́ ìjà, mo tún máa ń wo àwọn fídíò tó dá lórí bí mo ṣe lè sunwọ̀n sí i nínú ìjà. Mo fẹ́ràn kí n máa dánra wò pẹ̀lú ìbòjú lójú, kódà pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà lọ́wọ́. Mo máa ń fi ọwọ́ fọ́ pákó tàbí búlọ́ọ̀kù. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n kà mí mọ́ ara àwọn tó mọ kọnfú jà jù, mo sì gba oríṣiríṣi ife ẹ̀yẹ nínú àwọn ìdíje tí mo ti kópa. Nígbà tó yá, kọnfú di nǹkan tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé mi.

 Lójú tèmi, mo rò pé mo ti ṣàṣeyọrí nígbèésí ayé. Mo gboyè jáde ní yunifásítì, mo sì fakọ yọ pẹ̀lú èsì tó dára gan-an. Mo ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ ńlá kan gẹ́gẹ́ bí ẹnjiníà tó ń bójú tó àwọn kọ̀ǹpútà. Kódà, yàtọ̀ sí owó oṣù mi, ọ̀pọ̀ àjẹmọ́nú ni wọ́n fún mi nílé iṣẹ́ yẹn, mo ní ilé tara mi, mo tún ní ọ̀rẹ́bìnrin kan. Ẹni tó bá rí mi á rò pé mo láyọ̀, àmọ́ mi ò láyọ̀ torí pé onírúurú ìbéèrè ló ń jà gùdù lọ́kàn mi nípa ìgbésí ayé.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ

 Kí n lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ ṣọ́ọ̀ṣì lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀, mo sì ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́. Bó ti wù kó rí, ìjíròrò kan tó wáyé láàárín èmi àti ọ̀rẹ́ mi kan ló yí ìgbésí ayé mi pa dà. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ohun tí mo bi í ò ju pé: “Ǹjẹ́ o ti ronú nípa ìdí tá a fi wà láyé?” Mo wá fi kún un pé: “Bí ìṣòro ṣe pọ̀ gan-an náà ni ìwà ìrẹ́jẹ ṣe pọ̀!” Ọ̀rẹ́ mi yẹn dáhùn pé òun náà ti béèrè irú àwọn ìbéèrè yẹn, òun sì ti rí ìdáhùn tó tẹ́ òun lọ́rùn nínú Bíbélì. Ló bá fún mi ní ìwé kan tó ní àkọlé náà, Ìwọ Lè Wàláàyè Títí Láé Nínú Párádísè Lórí Ilẹ̀ Ayé. a Ó sọ pé òun ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mi ò kọ́kọ́ fẹ́ gbàwé yẹn, torí mo ronú pé kò yẹ kí n máa ka ìwé àwọn ẹlẹ́sìn míì àyàfi ẹ̀sìn mi. Àmọ́, torí pé mo fẹ́ mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè mi, mo gbà láti ka ìwé náà kí n lè wò ó bóyá ọ̀rọ̀ wọn máa tà létí mi.

 Ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí mo rí àwọn ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún wa látìbẹ̀rẹ̀ ni pé ká máa gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rí bẹ́ẹ̀ báyìí, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn yẹn ò yí pa dà. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ohun míì tó yà mí lẹ́nu ni orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, mo rí i nínú ẹ̀dà Bíbélì Mímọ́ tèmi fúnra mi, bẹ́ẹ̀ sì rèé, orúkọ yẹn ni mo ti ń gbàdúrà nípa ẹ̀ nínú Àdúrà Olúwa tí mo máa ń kà. (Sáàmù 83:18; Mátíù 6:⁠9) Bákan náà, mo rí ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé, ó sì wá yé mi pé fúngbà díẹ̀ ni. Gbogbo ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ pátá ló nítumọ̀, wọ́n sì bọ́gbọ́n mu. Inú mi dùn gan-an.

 Mi ò lè gbàgbé bó ṣe rí lára mi nígbà tí mo kọ́kọ́ lọ sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ara gbogbo wọn yá mọ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń béèrè orúkọ mi. Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tí mo lọ sípàdé, mo gbọ́ àsọyé pàtàkì kan nípa irú àdúrà tí Ọlọ́run máa ń gbọ́. Ohun tí wọ́n sọ lọ́jọ́ yẹn wọ̀ mí lọ́kàn torí ó ti pẹ́ tí mo ti ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, mo lọ sí Ìrántí Ikú Kristi tí wọ́n ṣe. Ohun tó yà mí lẹ́nu láwọn ìpàdé yẹn ni báwọn ọmọdé tó wà níbẹ̀ ṣe ń ṣí Bíbélì, tí wọ́n sì ń fojú bá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ń kà lọ. Níbẹ̀rẹ̀, mi ò mọ bí mo ṣe lè wá ẹsẹ Bíbélì, àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ gan-an, wọ́n kọ́ mi bí màá ṣe máa lo Bíbélì.

 Bí mo ṣe túbọ̀ ń lọ sáwọn ìpàdé yẹn, bẹ́ẹ̀ ni mo túbọ̀ ń mọyì àwọn ojúlówó ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni. Kódà, kò sígbà tí mo lọ sípàdé wọn tí mi ò kì í rí ìṣírí àti okun gbà. Nígbà tó yá, wọ́n rọ̀ mí pé kí n máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

 Ohun tí mo rí lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sóhun tí mo ti máa ń rí ní ṣọ́ọ̀ṣì mi. Mo rí i pé àwọn èèyàn tó lóòótọ́ ọkàn, tó sì wà níṣọ̀kan ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ń sa gbogbo ipá wọn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Mo wá gbà pé àwọn gan-an ló ń ṣe ohun tó fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni wọ́n, ìyẹn bí wọ́n ṣe ní ìfẹ́ láàárín ara wọn.—Jòhánù 13:35.

 Bí mo ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni mò ń ṣe àwọn àyípadà tó yẹ kí ìgbésí ayé mi lè bá àwọn ìlànà Bíbélì mu. Àmọ́, ó ṣe mí bí ẹni pé mi ò lè jáwọ́ nínú kọnfú. Mo fẹ́ràn kí n máa dánra wò, kí n sì máa báwọn èèyàn díje. Nígbà tí mo sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lọ́kàn mi fún ẹni tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó fi sùúrù sọ fún mi pé: “Máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ lọ, mo mọ̀ pé ìpinnu tó dáa lo máa ṣe.” Ohun tí mo fẹ́ gbọ́ gan-an nìyẹn. Bí mo ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ ló ń wù mí láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run.

 Ìgbà tí ohun tí mo sọ níbẹ̀rẹ̀ yẹn ṣẹlẹ̀, tí mo ṣèèṣì fi ìpá fọ́ ẹni tí mò ń kọ́ ní kọnfú nímú ni mo wá rí i pé á dáa kí n tún èrò mi pa. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kí n ronú pé bóyá ni màá lè di ọmọ ẹ̀yìn Kristi tí mo bá ṣì ń ja kọnfú. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Àìsáyà 2:​3, 4 ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn tó bá ṣe tán láti jọ́sìn Jèhófà ò ní “kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” Jésù náà kọ́ni pé a ò gbọ́dọ̀ bá àwọn èèyàn jà kódà tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ. (Mátíù 26:52) Bó ṣe di pé mo jáwọ́ nínú eré ìdárayá tí mo fẹ́ràn gan-an nìyẹn.

 Lẹ́yìn náà, mo fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò tó sọ pé, “kọ́ ara rẹ láti fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣe àfojúsùn rẹ.” (1 Tímótì 4:⁠7) Gbogbo àkókò àti okun tí mo máa ń lò tẹ́lẹ̀ nídìí kọnfú ni mo wá ń lò fún ìjọsìn Ọlọ́run àtàwọn ohun tó máa jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Torí pé ọ̀rẹ́bìnrin mi ò fara mọ́ àwọn ohun tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì, a pinnu pé a ò fẹ́ra mọ́. Ní January 24, 1987 mo ṣèrìbọmi, mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, mo di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, mo sì ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Látìgbà yẹn ni mo ti ń ṣe iṣẹ́ alákòókò kíkún, mo sì tún sìn fúngbà díẹ̀ ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ

 Ní báyìí tí mo ti mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, mo ti wá rí ohun tó sọ nù láyé mi, ọkàn mi sì ti balẹ̀. Ìgbésí ayé mi nítumọ̀, mo nírètí tó dájú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, mo sì ti wá ní ojúlówó ayọ̀. Mo ṣì máa ń ṣe eré ìmárale déédéé, àmọ́ òun kọ́ ni mo kà sí pàtàkì jù. Bí màá ṣe múnú Jèhófà dùn lohun tó ṣe pàtàkì jù láyé mi báyìí.

 Nígbà tí mò ń ja kọnfú, mo sábà máa ń fura sáwọn èèyàn bíi pé wọ́n lè yọwọ́ ìjà sí mi. Torí náà, mo máa ń ronú bí màá ṣe gbèjà ara mi. Títí dòní, mo ṣì máa ń wà lójúfò láti kíyè sí àwọn tó wà níbi tí mo wà, àmọ́ kì í ṣe torí àtigbèjà ara mi, bí kò ṣe torí àtiràn wọ́n lọ́wọ́. Ká sòótọ́, ẹ̀kọ́ Bíbélì ti jẹ́ kí n máa lawọ́ sáwọn èèyàn, ó ti mú kí n di ọkọ rere fún Brenda, òrékelẹ́wà aya mi.

 Mo fẹ́ràn ìjà kọnfú gan-an tẹ́lẹ̀. Àmọ́, mo ti fi nǹkan míì tó dáa gan-an rọ́pò ẹ̀. Ìmọ̀ràn tó dáa jù ni Bíbélì gbà wá, ó ní: “Àǹfààní díẹ̀ wà nínú eré ìmárale, àmọ́ ìfọkànsin Ọlọ́run ṣàǹfààní fún ohun gbogbo, ní ti pé ó ní ìlérí ìwàláàyè ní báyìí àti ìlérí ìwàláàyè ti ọjọ́ iwájú.”—1 Tímótì 4:8.

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.