Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Ìròyìn Tó Ń Jáni Láyà

Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Ìròyìn Tó Ń Jáni Láyà

 Kò sí ìgbà tí a kì í gbọ́ ìròyìn tó ń jáni láyà lórí tẹlifíṣọ̀n, lórí fóònù, nínú àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé àti lórí kọ̀ǹpútà. Wọ́n sábà máa ń gbé fídíò ohun tó ń ṣẹlẹ̀ jáde nínú àwọn ìròyìn náà.

 Gbogbo ẹ̀ sì làwọn ọmọ ń wò.

 Kí lo lè ṣe tí ìròyìn tó ń jáni láyà ò fi ní máa dẹ́rù ba àwọn ọmọ rẹ?

 Ipa wo ni ìròyìn máa ń ní lórí àwọn ọmọdé?

  •   Ìṣẹ̀lẹ̀ búburú táwọn ọmọdé ń rí lórí tẹlifíṣọ̀n tí wọ́n bá ń gbọ́ ìròyìn máa ń já wọn láyà. Àwọn ọmọdé kan lè má sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn o, ṣùgbọ́n tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn pé ohun búburú kan ṣẹlẹ̀, àyà wọn máa ń já gan-an ni. a Tí wọ́n bá wá rí i pé ọkàn àwọn òbí àwọn ò balẹ̀ nítorí ìròyìn náà, ṣe ni ìbẹ̀rù tiwọn náà á tún pọ̀ sí i.

  •   Àwọn ọmọdé lè ṣi ìròyìn tí wọ́n gbọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n lóye. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan sọ pé ohun táwọn rí yẹn á ṣẹlẹ̀ sí ìdílé àwọn. Àwọn ọmọdé tó bá sì ń wo fídíò ìṣẹ̀lẹ̀ búburú kan tó wáyé lọ́pọ̀ ìgbà lè rò pé ṣe ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ń wáyé léraléra.

  •   Àwọn ọmọdé ò ní mọ̀ bóyá àwọn oníròyìn tí ṣe àbùmọ́ ohun tó ṣelẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Wọ́n lè má mọ̀ pé ohun tó ń mówó wọlé fáwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ni pé kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa tẹ́tí sí ohun tí wọ́n ń sọ. Torí náà, wọn lè ṣe àbùmọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ kó lè wu àwọn tó ń tẹ́tí sí wọn láti máa gbọ́ ìròyìn náà lọ.

 Kí lo lè ṣe táwọn ọmọ rẹ ò fi ní máa jáyà tí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn?

  •   Má ṣe jẹ́ kí wọ́n máa tẹ́tí sí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tí ìròyìn bá gbé jáde. Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé káwọn ọmọ rẹ má mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé o. Ṣùgbọ́n kò dára kí wọ́n máa tẹ́tí sí ìròyìn tó ń jáni láyà léraléra, yálà lórí rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n.

     “Nígbà míì, èmi àti ọkọ mi máa ń sọ̀rọ̀ gan-an nípa ohun tá a gbọ́ nínú ìròyìn, láì kíyè sí i pé ó ń dẹ́rù ba àwọn ọmọ wa bó ṣe ń ta sí wọn létí.”—Maria.

     Ìlànà Bíbélì: “Ọ̀pọ̀ ìpayà máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá eniyan.”​—⁠Òwe 12:​25, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.

  •   Fara balẹ̀ gbọ́ wọn, rọra fèsì. Tí ọmọ rẹ ò bá lè ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀, sọ pé kó yà á sórí ìwé. Tó o bá ń bá ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀, èdè tó máa yé e ni kó o lò, ṣùgbọ́n má ṣe bá a sọ ohun tí kò yẹ kó mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

     “Ó jọ pé tá a bá jókòó tá a sì gbọ́ ohun tí ọmọ wa fẹ́ sọ ni ara rẹ̀ máa ń balẹ̀. Ẹ̀rù á ṣì máa bà á tá a bá wulẹ̀ sọ pé, ‘Kò sí ohun tá a lè ṣe nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà báyìí, àfi ká yáa máa bá a yí.’”—Sarahi.

     Ìlànà Bíbélì: ‘Yára láti gbọ́rọ̀, lọ́ra láti sọ̀rọ̀.’​—Jémíìsì 1:⁠19.

  •   Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí ìròyìn má bàa máa kó o láyà sókè. Ká sọ pé wọ́n jí ọmọ kan gbé, bí wọ́n ṣe sọ ọ́ nínú ìròyìn lè mú kò dà bíi pé àwọn gbọ́mọgbọ́mọ ti kún ìgboro, tí ọ̀rọ̀ ò sì rí bẹ́ẹ̀. Ṣàlàyé ohun tó o ti ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ fún wọn. Kó o sì tún fi sọ́kàn pé kì í ṣe torí pé ìṣẹ̀lẹ̀ búburú kan wọ́pọ̀ ni wọ́n ṣe gbé e jáde lórí rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n, ìdí tí wọ́n fi gbé e jáde ni pé irú ìròyìn bẹ́ẹ̀ ṣọ̀wọ́n.

     Má ṣe dá àwọn ọmọ rẹ dá bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun téèyàn ń rò ló ń pinnu bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹni, torí náà, tá a bá ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí ohun tó dára, wọn ò ní bẹ̀rù mọ́.”​—Lourdes.

     Ìlànà Bíbélì: “Ọkàn ọlọ́gbọ́n ń fún ẹnu rẹ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye ó sì ń fi ìyíniléròpadà kún ọ̀rọ̀ rẹ̀.”​—Òwe 16:23.

a Ìbẹ̀rù máa ń mú káwọn ọmọdé tọ̀ sára nígbà tí wọ́n ń sùn tàbí kí ẹ̀rù máa bà wọ́n láti lọ síléèwé níbi tí ojú àwọn òbí wọn ò ti ní tó wọn.