Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ọ̀rọ̀ Sísọ

Ẹ Máa Wáyè fún Ara Yín

Tọkọtaya lè wà nínú yàrá kan náà síbẹ̀ kí wọ́n má máa bára wọn sọ̀rọ̀. Báwo ni tọkọtaya ṣe lè máa lo àkókò tí wọ́n bá fi wà pa pọ̀ lọ́nà tó dára jù lọ?

Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Kí Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Gbà Ẹ́ Lọ́kàn

Bó o ṣe ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé lè ṣe ìgbéyàwó rẹ láǹfààní tàbí kó ṣàkóbá fún un. Kí ló ń ṣe fún ìgbéyàwó rẹ?

Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Yanjú Ọ̀rọ̀

Ọ̀nà tí ọkùnrin àti obìnrin ń gbà sọ̀rọ̀ yàtọ̀ síra. Tá a bá lóye àwọn ìyàtọ̀ yìí, aáwọ̀ ò ní máa ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.

Bí Ẹ Ṣe Lè Gbà Fún Ara Yín

Àwọn nǹkan mẹ́rin tó lè ràn ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ lọ́wọ́ láti paná àríyànjiyàn, kẹ́ ẹ sì jọ wá ojútùú sí ìṣòro yín.

Bí Ẹ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Wà Nínú Ilé

Ṣé àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì lè mú kí àlàáfíà wà níbi tí kò sí tẹ́lẹ̀? Wo ohun táwọn tó ti fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò sọ.

Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Bíbá Ara Yín Yan Odì

Báwo làwọn tọkọtaya kan ṣe máa ń bá a débi tí wọn ò fi ní bá ara wọn sọ̀rọ̀, kí ni wọ́n lè ṣe láti yanjú èdèkòyédè náà?

Bó o Ṣe Lè Kápá Ìbínú Rẹ

Tó o bá ń gbaná jẹ, ó lè ṣàkóbá fún ìlera rẹ, tó o bá tún lọ ń di ìbínú sínú ìyẹn náà máa ṣàkóbá fún ẹ. Torí náà kí lo lè ṣe tí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ bá múnú bí ẹ gan-an?

Bí Ẹ Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Bíbá Ara Yín Jiyàn

Ṣé ìwọ àti ẹnì kejì rẹ máa ń jiyàn ní gbogbo ìgbà? Wo bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ran ìdílé yín lọ́wọ́.

Bí Ẹ Ṣe Lè Yẹra Fún Sísọ Ọ̀rọ̀ Líle Síra Yín

Kí lo lè ṣe tí ọ̀rọ̀ líle bá ti nípa lórí àjọṣe àárín ìwọ àti ẹnìkejì rẹ?

Bó O Ṣe Lè Tọrọ Àforíjì

Tó bá jẹ́ èmi kọ́ ni mo jẹ̀bi ńkọ́?

Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Dárí Ji Ara Yín

Kí nìdí tó fi lè ṣòro fún wa láti dárí jini? Wo bí àwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́.

Bí Àárín Àwọn Tó Tún Ìgbéyàwó Ṣe àti Àwọn Ẹlòmí ì Ṣe Lè Tòrò

Báwo ni àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè mú kí ọkùnrin tàbí obìnrin tó lọ fẹ́ ẹlòmí ì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́, àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àti ẹni tí wọ́n ń fẹ́ tẹ́lẹ̀?