Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ẹ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Wà Nínú Ilé

Bí Ẹ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Wà Nínú Ilé

ǸJẸ́ o rò pé Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ kí àlàáfíà lè wà nínú ìdílé wa? Jọ̀wọ́ ronú lórí ohun tí Bíbélì sọ, kó o wá fi wéra pẹ̀lú ohun táwọn tá a béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn ṣe kí ìdílé wọn lè wà níṣọ̀kan. Nínú àwọn kókó tó wà nísàlẹ̀ yìí, ronú lórí èyí tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún àríyànjiyàn, tó máa mú kí àlàáfíà jọba, tí àárín yín sì máa gún.

ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ TÓ LÈ MÚ KÍ ÀLÀÁFÍÀ JỌBA NÍNÚ ILÉ

KA ẸNÌ KEJÌ RẸ SÍ PÀTÀKÌ.

“Láìṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ, kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.”Fílípì 2:3, 4.

“A ti rí i pé ohun tó dáa jù ni pé kó o ka ẹnì kejì rẹ sí pàtàkì ju ara rẹ àtàwọn míì lọ.”—Obìnrin kan tó ti ṣègbéyàwó láti ọdún mọ́kàndínlógún [19] sẹ́yìn.

TẸ́TÍ SÍLẸ̀ DÁADÁA, KÓ O SÌ GBA ÈRÒ ẸNÌ KEJÌ.

“Máa bá a lọ ní rírán wọn létí . . . láti má ṣe jẹ́ aríjàgbá, láti jẹ́ afòyebánilò, kí wọ́n máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo.”Títù 3:1, 2.

“Wàhálà máa dín kù tí a kò bá fi ìkanra bá ẹnì kejì wa sọ̀rọ̀. Ohun tó dáa ni pé ká tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa láì bẹnu àtẹ́ lu ẹni náà. Tí a kò bá tiẹ̀ fara mọ́ ohun tó sọ, kò yẹ ká kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ dànù.”—Obìnrin kan tó ti ṣègbéyàwó láti ogún [20] ọdún sẹ́yìn.

MÁA ṢE SÙÚRÙ, KÓ O SÌ NÍWÀ TÚTÙ.

“Sùúrù ni a fi ń rọ aláṣẹ lọ́kàn, ahọ́n pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sì lè fọ́ egungun.”Òwe 25:15.

“Èdèkòyédè á máa ṣẹlẹ̀, àmọ́ ọwọ́ tẹ́ ẹ bá fi mú un ló máa pinnu bóyá èdèkòyédè náà máa di rannto. Sùúrù ṣe pàtàkì gan-an. Tá a bá ń ṣe sùúrù, kò sí èdèkòyédè tí kò ní yanjú.”—Obìnrin kan tó ti ṣègbéyàwó láti ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] sẹ́yìn.

MÁ ṢE SỌ̀KÒ Ọ̀RỌ̀ SÍ ẸNÌ KEJÌ RẸ TÀBÍ KÓ O LÙ Ú.

“Ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn kúrò lẹ́nu yín.”Kólósè 3:8.

“Mo mọyì bí ọkọ mi ṣe máa kó ara rẹ̀ níjàánu. Ńṣe ló máa ń fara balẹ̀, kì í sì jágbe mọ́ mi tàbí kó bú mi.”—Obìnrin kan tó ti ṣègbéyàwó láti ogún [20] ọdún sẹ́yìn.

LẸ́MÌÍ ÌDÁRÍJÌ, KÓ O SÌ TÈTÈ MÁA YANJÚ AÁWỌ̀.

“Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.”Kólósè 3:13.

“Kì í rọrùn láti fara balẹ̀ tara bá ń kan ẹ́, o sì lè sọ ọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun kan tó máa dun ẹnì kejì rẹ. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn lẹ́mìí ìdáríjì. Dídáríjini ló máa jẹ́ kó o gbádùn ìgbéyàwó rẹ.”—Obìnrin kan tó ti ṣègbéyàwó láti ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] sẹ́yìn.

LẸ́MÌÍ Ọ̀LÀWỌ́.

“Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín. . . . Nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n padà fún yín.”Lúùkù 6:38.

“Ọkọ mi mọ ohun tí mo nífẹ̀ẹ́ sí, ó sì máa ń rà wọ́n wálé fún mi. Èyí máa ń mú kí èmi náà ronú pé, ‘Kí ni mo lè ṣe láti múnú ọkọ mi dùn?’ Èyí máa ń jẹ́ ká pa ara wa lẹ́rìn-ín, a sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ títí dòní.”—Obìnrin kan tó ti ṣègbéyàwó láti ọdún mẹ́rìnlélógójì [44] sẹ́yìn.

MÁ ṢE JẸ́ KÓ SÚ Ẹ LÁTI MÁA WÁ ÀLÀÁFÍÀ NÍNÚ ILÉ

Àwọn tá a béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn jẹ́ díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn kárí ayé tí Bíbélì ti ràn lọ́wọ́ láti ní àwọn ìwà tó ń mú kí àlàáfíà jọba nínú ilé. * Kódà táwọn yòókù nínú ilé kò bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, àǹfààní ṣì wà nínú kéèyàn jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà torí Bíbélì sọ pé: “Àwọn tí ń gbani nímọ̀ràn àlàáfíà ń yọ̀.”—Òwe 12:20.

^ ìpínrọ̀ 23 Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i nípa ohun tó lè mú kí ìdílé láyọ̀, wo orí 14 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. Ó sì wà lórí ìkànnì www.pr418.com/yo. Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ.