Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Tí Ọmọ Kan Bá Fẹ́ Pa Ara Rẹ̀

Tí Ọmọ Kan Bá Fẹ́ Pa Ara Rẹ̀

 Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, iye àwọn ọ̀dọ́ tó ń pa ara wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i láwọn orílẹ̀-èdè kan. Kí ló ń fà á? Ṣé ọmọ rẹ náà nírú ìṣòro yìí?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

 Ọwọ́ wo ló yẹ kí àwọn òbí fi mú ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ tó ń ronú láti pa ara wọn?

 Láti ọdún 2009 sí 2019, iye àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n ní ìdààmú ọkàn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì. Iye àwọn tó sì fẹ́ pa ara wọn lákòókò yẹn náà pọ̀ sí i. a

 “Ìṣòro tó ń kojú àwọn ọ̀dọ́ ìwòyí kò ṣe é fẹnu sọ . . . Àwọn ìṣòro yìí ò sì jẹ́ kí wọ́n lè máa ronú bó ṣe tọ́.”​—Vivek H. Murthy, U.S. Surgeon General.

 Ìlànà Bíbélì: “Ẹ̀mí tí ìdààmú bá máa ń tánni lókun.”​—Òwe 17:22.

 Báwo lo ṣe máa mọ̀ tí ọmọ rẹ bá nírú ìṣòro yìí?

 Jẹ́ ká gbé àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.

  •   Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀. Èwo ló ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ẹ nínú àwọn ìṣoro yìí; àwọn èèyàn pa á tì, òun àti ẹni tí wọ́n ń fẹ́ra sọ́nà fira wọn sílẹ̀, àwọn ìjákulẹ̀ míì ṣẹlẹ̀ sí i tàbí ẹni tó fẹ́ràn kú? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé àwọn nǹkan yìí ò ti máa ní ipa tí ò dáa lórí ẹ̀ ju bó o ṣe rò lọ?

  •   Ìwà. Ṣé ọmọ ẹ ò bá àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ àtàwọn mọ̀lẹ́bí yín ṣeré mọ́ àbí àwọn nǹkan tó máa ń fẹ́ràn láti ṣe tẹ́lẹ̀ ti wá di ohun tí kò wù ú mọ́? Ṣé ó ti fi àwọn nǹkan tó fẹ́ràn láti máa lò tọrẹ fáwọn míì?

  •   Ọ̀rọ̀ tó ń sọ. Ṣé ọmọ rẹ máa ń sọ̀rọ̀ nípa ikú tàbí kó máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ bí, “Ó sàn kí n kú.” Bákan náà, ṣé ó máa ń sọ pé ó máa ń ṣe mí bíi pé mo ti ń dà yín láàmú jù?

     Ká sòótọ́, àwọn ọ̀rọ̀ míì tí ọmọ rẹ máa sọ lè dà bí “ọ̀rọ̀ ẹhànnà.” (Jóòbù 6:3) Síbẹ̀, àwọn nǹkan míì tó bá sọ lè fi hàn pé ó fẹ́ kẹ́ ẹ ran òun lọ́wọ́. Torí náà, tọ́mọ rẹ bá sọ pé ó ń ṣe òun bíi kóun kú, má ṣe fojú kéré ohun tó sọ.

 Tí ọmọ rẹ bá sọ pé ó ti ṣe òun rí bíi pé kóun para òun, o lè bi í pé, “Àwọn ìgbà wo ló ti wá sí ẹ lọ́kàn rí, àti pé kí lo máa ń ronú pé wàá fi para rẹ?” Ohun tó bá sọ máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe máa tètè bójú tó ọ̀rọ̀ náà.

 “Nígbà míì, kì í rọrùn fáwa òbí láti bi àwọn ọmọ wa ní ìbéèrè torí a ò mọ ohun tá a máa bá lẹ́nu wọn. Àmọ́, nígbà tó jẹ́ pé ohun tó wà lọ́kàn wọn ni wọ́n fẹ́ sọ, àfi ká tẹ́tí sí wọn.”​—Sandra.

 Ìlànà Bíbélì: “Ète ọkàn ènìyàn dàbí omi jíjìn, ṣùgbọ́n ènìyàn olóye á wá wọn jáde.”​—Òwe 20:5, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

 Kí lo máa ṣe tí ọmọ rẹ bá nírú ìṣòro yìí?

  •   Sapá láti mọ ohun tó ń ṣe é gan-an. Kọ́kọ́ gbóríyìn fún un pé ó sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. Lẹ́yìn náà, o lè sọ pé: “Jọ̀ọ́, sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an fún mi. Màá fẹ́ kó o sọ gbogbo bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún mi.”

     Fara balẹ̀ tẹ́tí sí nǹkan tó bá sọ. Má sọ pé ohun tó ń ṣe é kò tó nǹkan, kódà tó o bá mọ ohun tó jẹ́ ojútùú sí ìṣòro ẹ̀, má já lu ọ̀rọ̀ ẹ̀.

     Ìlànà Bíbélì: ‘Yára láti gbọ́rọ̀, lọ́ra láti sọ̀rọ̀, má sì tètè máa bínú.’​—Jémíìsì 1:19.

  •   Ṣe ohun tí wàá fi dáàbò bo ọmọ rẹ. Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ àwọn nǹkan tó wà nísàlẹ̀ yìí kó sì kọ wọ́n sílẹ̀:

     Àwọn àmì. Kí làwọn nǹkan tó ń ṣe tàbí tó ń rò kó tó di pé ó fẹ́ para ẹ̀?

     Ohun tó o lè ṣe. Àwọn nǹkan wo ló máa ń ṣe tó ń jẹ́ kára tù ú, tí kì í jẹ́ kó máa ro àròkàn?

     Ìrànlọ́wọ́. Ṣé ọmọ rẹ rí ẹni fojú jọ, ìyẹn àwọn tó lè lọ bá tó bá nílò ìrànlọ́wọ́. Ó lè jẹ́ ìwọ, àgbàlagbà míì tó fọkàn tán, ẹnìkan tó mọ̀ nípa àìlera ọpọlọ tàbí àjọ kan tó ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ń ronú láti pa ara wọn.

    Ṣe ohun tí wàá fi dáàbò bo ọmọ rẹ

     Ìlànà Bíbélì: “Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.”​—Òwe 21:5.

  •   Wà lójúfò. Máa kíyè sí ọmọ rẹ dáadáa tó bá tiẹ̀ jọ pé èrò yẹn ò wá sí i lọ́kàn mọ́.

     “Nígbà tí ọmọ mi sọ fún mi pé òun ò ronú láti pa ara òun mọ́, ṣe ni mo rò pe ibẹ̀ lọ̀rọ̀ náà parí sí. À ṣé mo kàn ń tan ara mi ni, torí tí ẹni náà bá kojú ìṣòro lójijì, ó tún lè padà ronú láti para rẹ̀.”​—Daniel.

     Ran àwọn ọmọ rẹ tí ò tíì pé ogun ọdún lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ pé: Bí nǹkan ṣe ń rí lára àwa èèyàn máa ń wà fúngbà díẹ̀. Ìwé The Whole-Brain Child sọ pé “Ṣe ni wọ́n dà bí ojú ọjọ́. Bí àpẹẹrẹ, tójò bá ń rọ̀ ìwà òmùgọ̀ gbáà ló máa jẹ́ tí ẹnì kan bá dúró sínú òjò tó wá ń ṣe bíi pe òjò ò rọ̀. Bákan náà kò ní bójú mu kí ẹnì kan máa ronú pé oòrùn ò ní pa dá yọ mọ́.”

  •   Fi í lọ́kàn balẹ̀: Fi dá ọmọ rẹ lójú pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an àti pé o ṣe tán láti ràn án lọ́wọ́ nígbàkigbà tó bá nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ. O tiẹ̀ tún lè sọ fún un pé, “Màá ṣe gbogbo nǹkan tí mo bá lè ṣe láti tì ẹ́ lẹ́yìn kó o lè borí ìṣoro náà.”

     Ìlànà Bíbélì: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”​—Òwe 17:17.

a Ọ̀pọ̀ àwọn tó ní ìṣòro ìdààmú ọkàn kì í gbẹ̀mí ara wọn. Síbẹ̀, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ń gbẹ̀mí ara wọn làwọn tó ní ìṣòro ìdààmú ọkàn.