Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Sáàmù 37:4—“Jẹ́ Kí Inú Rẹ Máa Dùn Ninu OLUWA”

Sáàmù 37:4—“Jẹ́ Kí Inú Rẹ Máa Dùn Ninu OLUWA”

 “Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn jọjọ nínú Jèhófà, yóò sì fún ọ ní àwọn ohun tí ọkàn rẹ fẹ́.”​—Sáàmù 37:4, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ninu OLUWA; yóo sì fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́.”​—Sáàmù 37:4, Yoruba Bible.

Ìtumọ̀ Sáàmù 37:4

 Onísáàmù náà gba àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run níyànjú pé, wọ́n máa láyọ̀ tí wọ́n bá sún mọ́ Ọlọ́run. Ó sì dájú pé Jèhófà a Ọlọ́run máa ṣe ohun tó dáa tí ọkàn wọn bá fẹ́.

 “Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn jọjọ nínú Jèhófà.” Ọ̀rọ̀ yìí tún lè túmọ̀ sí “ní ayọ̀ tó kọyọyọ nínú Jèhófà,” “jẹ́ kí inú rẹ máa dùn nínú OLÚWA,” tàbí “Ṣe inú dídùn sí OLÚWA pẹ̀lú.” Ní kúkúrú, ohun tí gbólóhùn yìí túmọ̀ sí ni pé, ‘a máa ní ayọ̀ tó pọ̀’ tá a bá ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótó. (Sáàmù 37:4, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

 Bíbélì jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn nǹkan. Ojú yìí náà làwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ fi ń wo àwọn nǹkan náà. Kì í ṣe pé wọ́n mọ Ọlọ́run nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún gbà pé ó bọ́gbọ́n mu pé ká máa ṣègbọràn sí i. Èyí ló jẹ́ kí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, kí wọ́n sì lè máa ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. (Òwe 3:5, 6) Bí àpẹẹrẹ, wọn kì í banú jẹ́ tàbí jowú tí nǹkan bá ń lọ dáadáa fáwọn ẹni burúkú. (Sáàmù 37:1, 7-9) Inú wọn tún ń dùn bí wọ́n ṣe mọ̀ pé láìpẹ́ ó máa fòpin sí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù, ó sì máa san àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lẹ́san fún iṣẹ́ rere wọn. (Sáàmù 37:34) Bákan náà, wọ́n ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe mọ̀ pé inú Baba wọn ọ̀run ń dùn sí àwọn.​—Sáàmù 5:12; Òwe 27:11.

 “Yóò sì fún ọ ní àwọn ohun tí ọkàn rẹ fẹ́.” Àwọn ọ̀rọ̀ yìí tún lè túmọ̀ sí “yóò dáhùn àwọn àdúrà rẹ” tàbí “yóò fún ọ ní ohun tó wù ọ́ jù lọ.” Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ohun tá a bá béèrè náà ni Jèhófà máa ṣe. Bíi ti òbí tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀, Jèhófà mọ ohun tó dáa jù lọ fún àwọn tó bẹ̀rù Rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kí àwọn ohun tá à ń béèrè àti bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (Òwe 28:9; Jémíìsì 4:3; 1 Jòhánù 5:14) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn wa máa balẹ̀ láti bá Jèhófà tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà” sọ̀rọ̀, ó sì máa dá wa lójú pé ó ń gbọ́ wa.​—Sáàmù 65:2; Mátíù 21:22.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Sáàmù 37:4

 Dáfídì tó jẹ́ ọba Ísírẹ́lì àtijọ́ ló kọ Sáàmù 37. Ó sì kọ ọ́ ní ṣísẹ̀ n tẹ̀ lé. b

 Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn hùwà ìkà sí Dáfídì. Àwọn ìgbà kán tiẹ̀ wà tó ní láti sá lọ nígbà tí Ọba Sọ́ọ̀lù àtàwọn míì fẹ́ pa á. (2 Sámúẹ́lì 22:1) Síbẹ̀, Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tọkàntọkàn torí ó dá a lójú pé Jèhófà máa fìyà jẹ àwọn èèyàn burúkú náà. (Sáàmù 37:10, 11) Kódà tí nǹkan bá tiẹ̀ ń lọ dáadáa fún àwọn èèyàn burúkú, tí wọ́n sì dà bíi “koríko tútù,” ó dájú pé wọ́n á kọjá lọ, wọ́n á sì ṣègbé.​—Sáàmù 37:2, 20, 35, 36.

 Sáàmù 37 sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run àtàwọn tó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 37:16, 17, 21, 22, 27, 28) Torí náà, àwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù yìí jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè hùwà ọgbọ́n, ká sì tún jẹ́ ẹni tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà.

 Wo fídíò kékeré yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Sáàmù.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run bó ṣe wà nínú èdè Hébérù. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i lórí ohun tó fà á tí àwọn atúmọ̀ Bíbélì kan fi lo orúkọ oyè náà Olúwa dípò orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an, wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?

b Nínú ọ̀nà ìgbà ìkọ̀wé yìí, lẹ́tà àkọ́kọ́ nínú èdè Hébérù ni wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ ẹsẹ kìíní tàbí àpapọ̀ àwọn ẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀, lẹ́tà Hébérù kejì ni wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ àpapọ̀ ẹsẹ tó tẹ̀ lé e, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ ìwé yìí máa jẹ́ kó rọrùn fáwọn èèyàn láti tètè rántí àwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù náà.