Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Lúùkù 2:14—“Alaafia ní Ayé fún Àwọn Tí Inú Ọlọrun Dùn Sí”

Lúùkù 2:14—“Alaafia ní Ayé fún Àwọn Tí Inú Ọlọrun Dùn Sí”

 “Ògo ni fún Ọlọ́run ní ibi gíga lókè àti àlàáfíà fún àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà ní ayé.”​—Lúùkù 2:14, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Ògo fún Ọlọrun lókè ọ̀run, alaafia ní ayé fún àwọn tí inú Ọlọrun dùn sí.”​—Lúùkù 2:14, Yoruba Bible.

Ìtumọ̀ Lúùkù 2:14

 Àwọn ọ̀rọ̀ táwọn áńgẹ́lì fi yin Jèhófà nígbà tí wọ́n bí Jésù yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù máa rí ojú rere Ọlọ́run, ọkàn wọn á sì balẹ̀.

 “Ògo ni fún Ọlọ́run ní ibi gíga lókè.” Ọ̀rọ̀ táwọn áńgẹ́lì sọ yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé Ọlọ́run ló lẹ́tọ̀ọ́ láti gba gbogbo ògo. Ọ̀rọ̀ yìí tún jẹ́ ká mọ̀ pé bí wọ́n ṣe bí Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ṣe lórí ilẹ̀ ayé máa túbọ̀ mú ògo bá orúkọ Jèhófà a Ọlọ́run. Gbogbo ìgbà tí Jésù bá ń kọ́ni ló máa ń fi ògo fún Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tó sọ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, àmọ́ ó jẹ́ ti ẹni tó rán mi.” (Jòhánù 7:16-18) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí Jésù bá ṣe iṣẹ́ ìyanu, àwọn tó wà níbẹ̀ máa ń “yin Ọlọ́run lógo.” (Lúùkù 5:18, 24-26; Jòhánù 5:19) Kódà ikú Jésù fi ògo fún Ọlọ́run. Ìdí ni pé, ikú rẹ̀ ló máa mú kí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ṣeé ṣe, ìyẹn ni pé kí àwọn olóòótọ́ èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà kún ayé.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.

 “Àlàáfíà . . . ní ayé.” Àlàáfíà tí ibí yìí ń sọ kọjá pé kò sí ogun mọ́. Ó tún kan ìbàlẹ̀ ọkàn tí èèyàn máa ń ní torí pé ó rí ojú rere Ọlọ́run. Jésù ló mú kó ṣeé ṣe fáwa èèyàn láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. (Jémíìsì 4:8) Torí pé Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó máa mú kí àlááfíà wà kárí ayé, àlàáfíà náà sì máa wà pẹ́ títí.​—Sáàmù 37:11; Lúùkù 1:32, 33.

 “Àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà.” Àwọn tó rí ojú rere tàbí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run ni ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí, torí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run àti Jésù ẹni tí Ọlọ́run rán wá sáyé. Ọ̀rọ̀ yìí kò túmọ̀ sí pé gbogbo èèyàn ló máa rí ojú rere Ọlọ́run láìka ìwà àti ìṣe wọn sí, kò sì túmọ̀ sí ojú rere tí àwa èèyàn ń ṣe sí ara wa. Nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì, irú bí Bibeli Mimọ, wọ́n lo ọ̀rọ̀ náà “ifẹ inu rere si enia.” Àmọ́, ọ̀rọ̀ náà àlàáfíà fún àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà tí wọ́n lò nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun àtàwọn ìtumọ̀ Bíbélì òde òní míì bá èyí tí wọ́n lò nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ lédè Gíríìkì mu.​—Wo “ Bí Wọ́n Ṣe Túmọ̀ Lúùkù 2:14 Nínú Àwọn Ìtumọ̀ Bíbélì Míì.”

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Lúùkù 2:14

 Lúùkù orí 2 ṣàlàyé ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù, áńgẹ́lì kan yọ sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn yìí “ń gbé níta, wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru.” b (Lúùkù 2:4-8) Áńgẹ́lì náà sọ fáwọn olùṣọ́ àgùntàn pé “mò ń kéde ìhìn rere ayọ̀ ńláǹlà fún yín . . . lónìí, a bí olùgbàlà kan fún yín ní ìlú Dáfídì, òun ni Kristi Olúwa.” (Lúùkù 2:9-11) Áńgẹ́lì yẹn tún sọ ibi táwọn olùṣọ́ àgùntàn ti máa rí ọmọ jòjòló náà, lẹ́yìn náà ni wọ́n rí ọ̀pọ̀ àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n ń yin Ọlọ́run lógo. Nígbà táwọn olùṣọ́ àgùntàn náà dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, wọ́n rí Jósẹ́fù, Màríà àti ọmọ kékeré náà Jésù. (Lúùkù 2:12-16) Lẹ́yìn táwọn olùṣọ́ àgùntàn náà ti sọ ohun tí wọ́n gbọ́ nípa ọmọ kékeré náà fún wọn, wọ́n pa dà síbi iṣẹ́ wọn, “wọ́n ń fògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì ń yìn ín torí gbogbo ohun tí wọ́n gbọ́, tí wọ́n sì rí.”​—Lúùkù 2:17-20.

 Bí Wọ́n Ṣe Túmọ̀ Lúùkù 2:14 Nínú Àwọn Ìtumọ̀ Bíbélì Míì

 “Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run, àti ní ayé Àlàáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.”​—Lúùkù 2:14, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

 “Ògo fún Ọlọrun lókè ọ̀run, alaafia ní ayé fún àwọn tí inú Ọlọrun dùn sí!”​—Lúùkù 2:14, Ìròyìn Ayọ̀.

 “Ogo ni fun Ọlọrun loke ọrun, ati li aiye alafia, ifẹ inu rere si enia!”​—Lúùkù 2:14, Bibeli Mimo.

 Wo fídíò kékeré yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Lúùkù.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?

b Bí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ṣe wà níta lóru ọjọ́ yẹn fi hàn pé ìgbà òtútù kọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Ìgbà Wo Ni Wọ́n Bí Jésù?