Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Lúùkù 1:37​—“Nítorí Kò Sí Ohun Tí Ọlọ́run Kò Le Ṣe”

Lúùkù 1:37​—“Nítorí Kò Sí Ohun Tí Ọlọ́run Kò Le Ṣe”

 “Torí pé kò sí ìkéde kankan tí kò ní ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”​—Lúùkù 1:37, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe.”​—Lúùkù 1:37, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

Ìtumọ̀ Lúùkù 1:37

 Ọlọ́run Olódùmarè lè ṣe ohun tó dà bíi pé kò ṣeé ṣe lójú èèyàn. Kò sí ohunkóhun tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó bá sọ tàbí tó ṣèlérí.

 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ìkéde” lè túmọ̀ sí “ọ̀rọ̀” tí Ọlọ́run sọ. Ó tún lè tọ́ka sí ohun tí Jèhófà a Ọlọ́run sọ tó ṣẹ. Torí pé gbogbo ohun tí Ọlọ́run bá sọ ló máa ń ṣẹ, a tún lè sọ ohun tó wà ní Lúùkù 1:37 lọ́nà yìí: “Àwọn ìlérí Ọlọ́run kò ní kùnà láé” tàbí “kò sí ohun tó ṣòro ṣe fún Ọlọ́run.” Ohun kan náà làwọn ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí. Ìyẹn ni pé kò sí ìkéde kankan tàbí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe tí kò ní ṣẹ torí pé kò sí ohun tó ṣòro ṣe fún Ọlọ́run.​—Àìsáyà 55:10, 11.

 Nínú Bíbélì ọ̀pọ̀ ìgbà ni irú àwọn ọ̀rọ̀ ìdánilójú yìí nípa àwọn ìlérí Ọlọ́run fara hàn. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà lo áńgẹ́lì rẹ̀ láti sọ tẹ́lẹ̀ pé Sérà ìyàwó Ábúráhámù tó yàgàn máa lóyún ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ọlọ́run fi kún un pé: “Ǹjẹ́ a rí ohun tó pọ̀ jù fún Jèhófà láti ṣe?” (Jẹ́nẹ́sísì 18:13, 14) Lẹ́yìn tí Jóòbù ronú lórí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, ó sọ pé: “Kò sí ohun tó wà lọ́kàn rẹ tí kò ní ṣeé ṣe fún ọ.” (Jóòbù 42:2) Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé bóyá làwọn máa lè ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run fẹ́, Jésù fi dá wọn lójú pé, “ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”​—Mátíù 19:25, 26. b

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Lúùkù 1:37

 Áńgẹ́lì kan tó ń jẹ́ Gébúrẹ́lì ló sọ ohun tó wà nínú Lúùkù 1:37 nígbà tó ń bá wúńdíá kan tó ń jẹ́ Màríà sọ̀rọ̀. Áńgẹ́lì yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún un pé ó máa bí ọmọkùnrin kan tó jẹ́ “Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ.” Ó wá ní kó pe “orúkọ rẹ̀ ní Jésù.” Òun ló sì máa jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run tó máa ṣàkóso títí láé.​—Lúùkù 1:26-33; Ìfihàn 11:15.

 Àmọ́ Màríà béèrè lọ́wọ́ áńgẹ́lì náà pé báwo ló ṣe máa ṣẹlẹ̀ torí kò tíì lọ́kọ, àti pé kò tíì “bá ọkùnrin lò pọ̀” rí. (Lúùkù 1:34, 35) Gébúrẹ́lì dá a lóhùn pé Ọlọ́run máa lo ẹ̀mí mímọ́ tàbí agbára ìṣiṣẹ́ rẹ̀. Lásìkò yẹn, ọ̀run ni Jésù wà. Torí náà, Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ láti mú kí Màríà lóyún Jésù Ọmọ rẹ̀. (Jòhánù 1:14; Fílípì 2:5-7) Bó ṣe di pé Màríà lóyún lọ́nà ìyanu nìyẹn. Kí Màríà lè ní ìgbàgbọ́ nínú agbára Ọlọ́run, áńgẹ́lì náà sọ fún un pé Èlísábẹ́tì mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ti lóyún ọmọkùnrin kan “ní ọjọ́ ogbó rẹ̀.” Torí àgàn ni Èlísábẹ́tì, òun àti Sekaráyà ọkọ rẹ̀ kò rọ́mọ bí. (Lúùkù 1:36) Nígbà tó yá, wọ́n bí ọmọkùnrin kan tí wọ́n pè ní Jòhánù. Òun ló sì di Jòhánù Arinibọmi tí Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ nípa ohun tó máa ṣe.​—Lúùkù 1:10-16; 3:1-6.

 Ọ̀rọ̀ nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Màríà àti Èlísábẹ́tì ni áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ní lọ́kàn nígbà tó sọ ohun tó wà nínú Lúùkù 1:37. Lónìí náà, àwọn ọ̀rọ̀ yìí ń fi àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́kàn balẹ̀ pé ó máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Èyí sì kan ìlérí tó ṣe pé, ìṣàkóso Jésù Kristi Ọmọ òun, tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run máa rọ́pò ìjọba èèyàn.​—Dáníẹ́lì 2:44; 7:13, 14.

 Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Lúùkù.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”