Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Màríà Wúńdíá?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Màríà Wúńdíá?

 Ohun tí Bíbélì sọ

 Bíbélì sọ pé Màríà, tó jẹ́ ìyá Jésù, ní àǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti lóyún Jésù, kó sì bí i nígbà tó ṣì jẹ́ wúńdíá, ìyẹn láì tíì mọ ọkùnrin. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nínú ìwé Aísáyà pé iṣẹ́ ìyanu yìí máa ṣẹlẹ̀, ó sì sọ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ nínú ìwé Ìhìnrere Mátíù àti Lúùkù.

 Nígbà tí Aísáyà ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa bí Mèsáyà, ó sọ pé: “Wò ó! Omidan náà yóò lóyún ní tòótọ́, yóò sì bí ọmọkùnrin kan.” (Aísáyà 7:14) Ọlọ́run mí sí Mátíù tó wà lára àwọn tó kọ ìwé Ìhìnrere láti kọ ọ́ pé oyún Jésù tí Màríà ní ló mú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣẹ. Lẹ́yìn tí Mátíù kọ ọ́ pé Màríà lóyún lọ́nà ìyanu, ó fi kún un pé: “Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ ní ti gidi, kí a lè mú èyíinì tí Jèhófà sọ nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ ṣẹ, pé: ‘Wò ó! Wúńdíá a náà yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, wọn yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì,’ èyí tí, nígbà tí a bá túmọ̀ rẹ̀, ó túmọ̀ sí, ‘Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú Wa.’”​—Mátíù 1:22, 23.

 Lúùkù tóun náà wà lára àwọn tó kọ ìwé Ìhìnrere sọ̀rọ̀ nípa oyún ìyanu tí Màríà ní. Ó kọ ọ́ pé Ọlọ́run rán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì “sí wúńdíá kan tí ó jẹ́ àfẹ́sọ́nà ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jósẹ́fù ní ilé Dáfídì; orúkọ wúńdíá náà sì ni Màríà.” (Lúùkù 1:26, 27) Màríà jẹ́rìí sí i pé wúńdíá lòun, torí lẹ́yìn tó gbọ́ pé òun máa di ìyá Jésù tó jẹ́ Mèsáyà náà, Màríà béèrè pé: “Báwo ni èyí yóò ṣe rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí èmi kò ti ń ní ìbádàpọ̀ kankan pẹ̀lú ọkùnrin?”​—Lúùkù 1:34.

 Báwo lẹni tí kò mọ ọkùnrin ṣe lè bímọ?

 Ẹ̀mí mímọ́, tó jẹ́ agbára tí Ọlọ́run fi ń ṣiṣẹ́, ló jẹ́ kí Màríà lóyún. (Mátíù 1:18) Áńgẹ́lì náà sọ fún Màríà pé: “Ẹ̀mí mímọ́ yóò bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì ṣíji bò ọ́. Nítorí ìdí èyí pẹ̀lú, ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.” b (Lúùkù 1:35) Lọ́nà ìyanu, Ọlọ́run fi ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ sínú ilé ọlẹ̀ Màríà, bó ṣe di pé ó lóyún nìyẹn.

 Kí nìdí tó fi jẹ́ pé wúńdíá ló bí Jésù?

 Ọlọ́run lo wúńdíá láti bí Jésù torí kí Jésù lè ní ara èèyàn pípé, kó lè ṣeé ṣe fún un láti gba aráyé lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jòhánù 3:16; Hébérù 10:5) Ọlọ́run fi ẹ̀mí Jésù sínú ilé ọlẹ̀ Màríà. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó ṣe kedere pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run dáàbò bo ọlẹ̀ yẹn bó ṣe ń dàgbà kó má bàa kó àìpé kankan lára ìyá rẹ̀.​—Lúùkù 1:35.

 Bó ṣe di pé Màríà bí Jésù ní ẹni pípé nìyẹn, tó sì dọ́gba pẹ̀lú irú ẹni tí Ádámù jẹ́ kó tó dẹ́ṣẹ̀. Bíbélì sọ nípa Jésù pé: “Kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.” (1 Pétérù 2:22) Torí pé èèyàn pípé ni Jésù, ó lè san ìràpadà láti gba aráyé sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.​—1 Kọ́ríńtì 15:21, 22; 1 Tímótì 2:5, 6.

 Ṣé wúńdíá ni Màríà títí ó fi kú?

 Bíbélì ò fi kọ́ wa pé wúńdíá ayérayé ni Màríà, pé kò mọ ọkùnrin títí ó fi kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì jẹ́ ká rí i pé Màríà bí àwọn ọmọ míì.​—Mátíù 12:46; Máàkù 6:3; Lúùkù 2:7; Jòhánù 7:5.

Bíbélì jẹ́ ká rí i pé Jésù ní àwọn àbúrò mélòó kan

 Ṣé wúńdíá tí kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ló bí Jésù?

 Rárá o. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé àwọn tó gba ẹ̀kọ́ yìí gbọ́ “gbà pé Màríà Wúńdíá ò JOGÚN Ẹ̀ṢẸ̀ látìbẹ̀rẹ̀ ayé ẹ̀, ìyẹn látìgbà tí wọ́n ti lóyún rẹ̀. Gbogbo èèyàn yòókù láyé ló jogún ẹ̀ṣẹ̀ . . . Àmọ́ Màríà ní tiẹ̀ rí OORE-Ọ̀FẸ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ gbà, a ò jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ ràn án rárá.” c

 Kò síbì kankan nínú Bíbélì tó sọ pé Màríà ò jogún ẹ̀ṣẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀. (Sáàmù 51:5; Róòmù 5:12) Kódà, Màríà fúnra ẹ̀ fẹ̀rí hàn pé ẹlẹ́ṣẹ̀ lòun nígbà tó mú ohun tí Òfin Mósè béèrè lọ́wọ́ àwọn ìyá ọlọ́mọ wá sí tẹ́ńpìlì láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. (Léfítíkù 12:2-8; Lúùkù 2:21-​24) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Ìwé Mímọ́ ò fi kọ́ni pé Màríà kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ . . . Ṣọ́ọ̀ṣì ló hùmọ̀ [ẹ̀kọ́ yìí].”

 Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo Màríà?

 Àpẹẹrẹ rere ni Màríà jẹ́ fún wa torí ó nígbàgbọ́, onígbọràn ni, ó nírẹ̀lẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an. Ó wà lára àwọn olóòótọ́ tó yẹ ká fara wé.​—Hébérù 6:12.

 Síbẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó láǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti jẹ́ ìyá Jésù, Bíbélì ò fi kọ́ wa pé ó yẹ ká máa jọ́sìn Màríà tàbí ká máa gbàdúrà sí i. Jésù ò bọlá tó ṣàrà ọ̀tọ̀ fún ìyá rẹ̀, kò sì sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, tó bá yẹ̀ lẹ́yìn àwọn ìwé Ìhìnrere tórúkọ rẹ̀ ti fara hàn àti ẹ̀ẹ̀kan tá a dárúkọ ẹ̀ nínú ìwé Ìṣe, a ò dárúkọ Màríà nínú àwọn ìwé méjìlélógún (22) tó kù nínú apá táwọn èèyàn mọ̀ sí Májẹ̀mú Tuntun.​—Ìṣe 1:14.

 Kò sí ẹ̀rí kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní pe àfíyèsí tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sí Màríà, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kí wọ́n jọ́sìn ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni Bíbélì kọ́ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa sìn.​—Mátíù 4:10.

a Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a pè ní “omidan” nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ni ʽal·mahʹ, tó lè tọ́ka sí obìnrin tó ti mọ ọkùnrin tàbí èyí tí kò tíì mọ ọkùnrin. Àmọ́ Ọlọ́run mí sí Mátíù láti lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túbọ̀ sojú abẹ níkòó, ìyẹn par·theʹnos, tó túmọ̀ sí “wúńdíá.”

b Àwọn kan ò fara mọ́ lílo ọ̀rọ̀ náà “Ọmọ Ọlọ́run,” wọ́n gbà pé ṣe nìyẹn túmọ̀ sí pé Ọlọ́run bá obìnrin kan lò pọ̀ ló fi bí ọmọ náà. Àmọ́ Ìwé Mímọ́ ò fi kọ́ wa bẹ́ẹ̀. Dípò ìyẹn, ṣe ni Bíbélì pe Jésù ní “Ọmọ Ọlọ́run” àti “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá” torí pé òun ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni kàn ṣoṣo tí Ọlọ́run fọwọ́ ara rẹ̀ dá. (Kólósè 1:13-​15) Bíbélì tún pe Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́ ní “ọmọ Ọlọ́run.” (Lúùkù 3:38) Ìdí ni pé Ọlọ́run ló dá Ádámù.

c Àtúnṣe Kejì, Ìdìpọ̀ 7, ojú ìwé 331.