Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Jòhánù 15:13—“Kò Sí Ẹnìkan Tí Ó Ní Ìfẹ́ Tí Ó Tóbi Ju Èyí Lọ”

Jòhánù 15:13—“Kò Sí Ẹnìkan Tí Ó Ní Ìfẹ́ Tí Ó Tóbi Ju Èyí Lọ”

 “Kò sí ẹni tí ìfẹ́ rẹ̀ ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.”​—Jòhánù 15:13, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Kò sí ẹnìkan tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.”​—Jòhánù 15:13, Bíbélì Mímọ́.

Ìtumọ̀ Jòhánù 15:13

 Jésù fẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ mọ̀ pé ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn gbọ́dọ̀ lágbára débi tí wọ́n á fi múra tán láti kú fún ara wọn.

 Nínú ẹsẹ tó ṣáájú, Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Àṣẹ mi nìyí, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín.” (Jòhánù 15:12) Irú ìfẹ́ wo ni Jésù ní sí wọn? Ó nífẹ̀ẹ́ wọn látọkàn wá, ó sì ṣe tán láti fi ẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀ fún wọn. Ní gbogbo ìgbà tó fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ó máa ń fi ire àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ àti tàwọn míì ṣáájú tiẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó wo àwọn èèyàn sàn, ó sì tún kọ́ wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run. a Kódà, o ṣe àwọn iṣẹ́ tó rẹlẹ̀ kó lè ran àwọn míì lọ́wọ́. (Mátíù 9:35; Lúùkù 22:27; Jòhánù 13:3-5) Àmọ́ ìfẹ́ tí Jésù ń sọ ní Jòhánù 15:13 ju gbogbo ìyẹn lọ. Kò ju wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn tó sọ ọ̀rọ̀ yẹn ló fi ìfẹ́ tó ga jù lọ yìí hàn nígbà tó “fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.” (Mátíù 20:28; 22:39) Ó tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn míì ju bí òun ṣe nífẹ̀ẹ́ ara òun lọ.

 Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an. Àmọ́ àwọn tó ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ rẹ̀ ló fẹ́ràn jù. Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni Jésù ka àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sí torí wọ́n máa ń tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀, wọ́n sì dúró tì í nígbà ìṣòro. (Lúùkù 22:28; Jòhánù 15:14, 15) Ìdí nìyẹn tó fi wù ú gan-an láti kú fún wọn.

 Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Jésù, ìyẹn sì mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn débi tí wọ́n fi ṣe tán láti kú fún ara wọn. (1 Jòhánù 3:16) Ká sòótọ́, ìfẹ́ tí Jésù fi hàn yìí ló wa di ohun tó gbawájú jù lọ tá a fi ń dá àwa Kristẹni tòótọ́ mọ̀.​—Jòhánù 13:34, 35.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Jòhánù 15:13

 Orí 13 sí 17 nínú ìwé Ìhìn rere Jòhánù jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀rọ̀ ìdágbére tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ mọ́kànlá (11) tó jẹ́ olóòótọ́ àti àdúrà tó gbà kẹ́yìn pẹ̀lú wọn. Wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ìdágbére náà ló kú. Ní orí 15, Jésù fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wé èso igi àjàrà kó lè fi ṣàlàyé ìdí tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ fi gbọ́dọ̀ wà níṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, kí wọ́n sì lè fi hàn pé ọmọlẹ́yìn ẹ̀ làwọn lóòótọ́. Ó wá rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa “so èso púpọ̀.” (Jòhánù 15:1-5, 8) Ọ̀nà kan tí wọ́n lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kí wọ́n máa fi ìfẹ́ tó dénú hàn sáwọn míì. Ìyẹn sì máa gba pé kí wọ́n máa wàásù “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run” bí Jésù ti ṣe.​—Lúùkù 4:43; Jòhánù 15:10, 17.

 Wo fídíò kékeré yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Jòhánù.

a Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àkóso kan tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ ní ọ̀run láti ṣàkóso ayé, kó sì mú kí ìfẹ́ rẹ̀ fún ayé ṣẹ. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?