Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

1 Kọ́ríńtì 10:13—“Olódodo Ni Ọlọ́run”

1 Kọ́ríńtì 10:13—“Olódodo Ni Ọlọ́run”

 “Kò sí àdánwò kankan tó ti bá yín àfi èyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn. Àmọ́ Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́, kò ní jẹ́ kí a dán yín wò kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n nínú àdánwò náà, yóò ṣe ọ̀nà àbáyọ kí ẹ lè fara dà á.”​—1 Kọ́ríńtì 10:13, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Kò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á.”​—1 Kọ́ríńtì 10:13, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

Ìtumọ̀ 1 Kọ́ríńtì 10:13

 Ẹsẹ yìí jẹ́ ká rí ìwà kan tó ń tuni lára tí Ọlọ́run ní, ìyẹn bó ṣe jẹ́ olóòótọ́. Torí náà, ó dá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lójú pé ó máa ran àwọn lọ́wọ́, pàápàá lásìkò tí àdánwò tàbí ìṣòro èyíkéyìí bá dé bá wọn.

 “Kò sí àdánwò kankan tó ti bá yín àfi èyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn.” Àdánwò lè dá bá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, kó sì máa ṣe wọ́n bíi kí wọ́n ṣe ohun tínú Ọlọ́run ò dùn sí. Àwọn àdánwò yìí lè le lóòótọ́, àmọ́ kò ṣàrà ọ̀tọ̀ torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni irú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí rí tí wọ́n sì fara dà á. a Torí náà, ọkàn àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè balẹ̀ pé àwọn náà máa lè fara da ìṣòro náà.

 “Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́.” Ẹni tó ṣeé gbára lé ni Jèhófà b Ọlọ́run, a sì lè fọkàn tán an. Ìdí ni pé gbogbo ìgbà ló máa ń mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ pé òun máa wà pẹ̀lú àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ òun, tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí òun. (Diutarónómì 7:9; Sáàmù 9:10; 37:28) Torí náà, ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lè balẹ̀ pé ó máa mú àwọn ìlérí méjì tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ṣẹ.

 “Kò ní jẹ́ kí a dán yín wò kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra.” Ọlọ́run tún fi hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́ ní ti pé kì í jẹ́ káwọn àdánwò wa le débi tí kò fi ní ṣeé ṣe fún wa láti fara dà á. Ohun kan ni pé ó mọ ibi tí agbára gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mọ.​—Sáàmù 94:14.

 “Nínú àdánwò náà, yóò ṣe ọ̀nà àbáyọ kí ẹ lè fara dà á.” Ọlọ́run lè yanjú ìṣòro àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tàbí kó fún wọn lókun láti fara dà á. Bí àpẹẹrẹ, ó lè fi ẹ̀mí mímọ́ tọ́ wa sọ́nà, kó fi Bíbélì tù wá nínú tàbí kó mú káwọn ará nínú ìjọ ràn wá lọ́wọ́.​—Jòhánù 14:26; 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4; Kólósè 4:11.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé 1 Kọ́ríńtì 10:13

 Inú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì ni ẹsẹ Bíbélì yìí wà. Ní apá yìí nínú lẹ́tà náà, Pọ́ọ̀lù lo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ láti kìlọ̀ fáwọn Kristẹni tó ń gbé nílùú Kọ́ríńtì. (1 Kọ́ríńtì 10:11) Pọ́ọ̀lù sọ onírúurú àwọn nǹkan tó dán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wò nígbà yẹn, bí ìbọ̀rìṣà àti ìṣekúṣe. (1 Kọ́ríńtì 10:6-10) Ó dunni pé àwọn kan nínú wọn lọ́wọ́ nínú ìwà burúkú yìí. Pọ́ọ̀lù wá fi àpẹẹrẹ wọn tẹ̀ ẹ́ mọ́ àwọn Kristẹni lọ́kàn pé kí wọ́n má ṣe máa dá ara wọn lójú pé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ sáwọn. (1 Kọ́ríńtì 10:12) Ẹ̀yìn ìyẹn ni Pọ́ọ̀lù wá sọ ohun tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 10:13 kó lè fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Torí náà, ó dájú pé àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà lè borí àdánwò èyíkéyìí tó bá dé bá wọn.

 Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé 1 Kọ́ríńtì.

a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “àdánwò” tún lè túmọ̀ sí ìṣòro.

b Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?