Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ KARÙN-ÚN

Bí Ẹ Ṣe Lè Jẹ́ Kí Àlàáfíà Jọba Láàárín Ẹ̀yin Àtàwọn Mọ̀lẹ́bí Yín

Bí Ẹ Ṣe Lè Jẹ́ Kí Àlàáfíà Jọba Láàárín Ẹ̀yin Àtàwọn Mọ̀lẹ́bí Yín

“Ẹ fi . . . inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.”Kólósè 3:12

Ìdílé tuntun ni ìgbéyàwó máa ń dá sílẹ̀. Òótọ́ ni pé o gbọ́dọ̀ fẹ́ràn àwọn òbí rẹ, kí o sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn, àmọ́ ní báyìí, ọkọ tàbí aya rẹ lẹni tó ṣe pàtàkì jù sí ẹ láyé. Ó lè má rọrùn fún àwọn kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ láti fara mọ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́ àwọn ìlànà Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí o má bàa ṣàṣejù, kí o sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ bí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ ṣe ń sapá kí ẹ lè túbọ̀ mọwọ́ ara yín.

1 MÁA FI OJÚ TÓ YẸ WO ÀWỌN MỌ̀LẸ́BÍ RẸ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” (Éfésù 6:2) Kò sí bí o ṣe lè dàgbà tó, o ṣì gbọ́dọ̀ máa bọlá fún àwọn òbí rẹ, kí o sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. O tún gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn pé ọkọ tàbí aya rẹ kò ní pa àwọn òbí rẹ̀ tì torí pé ọmọ wọn ló ṣì jẹ́. “Ìfẹ́ kì í jowú,” torí náà má ṣe jẹ́ kí àjọṣe tí ọkọ tàbí aya rẹ ní pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ dẹ́rù bà ọ́.1 Kọ́ríńtì 13:4; Gálátíà 5:26.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Má ṣe sọ ọ̀rọ̀ tó máa mú kó dà bíi pé ẹlòmí ì kò ṣe ohunkóhun tó dáa rí. Irú bíi: “Àwọn èèyàn ẹ ò fìgbà kankan kà mí sí” tàbí “Kò sóhun tí mo ṣe tó dáa lójú màmá ẹ”

  • Gbìyànjú láti lóye ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ ní lọ́kàn

2 DÚRÓ LÓRÍ Ọ̀RỌ̀ RẸ NÍGBÀ TÓ BÁ YẸ

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: ‘Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.’ (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Lẹ́yìn tí o ti ní ìyàwó tàbí ọkọ, àwọn òbí rẹ lè máa wò ó pé ojúṣe àwọn ṣì ni láti máa bójú tó ẹ, wọ́n sì lè fẹ́ máa dá sí ọ̀rọ̀ yín ju bó ṣe yẹ lọ.

Ọwọ́ yín ló kù sí láti jọ pinnu irú àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹ kò ní jẹ́ kí wọ́n máa bá yín dá sí, kí ẹ sọ ọ́ fún wọn tìfẹ́tìfẹ́. Ẹ ṣì lè sọ tinú yín fún wọn, kí ẹ sì jẹ́ kí wọ́n mọ bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an láìjẹ́ pé ẹ yájú sí wọn. (Òwe 15:1) Ìrẹ̀lẹ̀, ìwà tútù àti sùúrù máa jẹ́ kí àárín ẹ̀yin àti àwọn mọ̀lẹ́bí yín gún, kí ẹ sì lè máa ‘fara dà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́.’Éfésù 4:2.

OHUN TÍ O LÈ ṢE:

  • Tí o bá wò ó pé àwọn mọ̀lẹ́bí yín ń dá sí ọ̀rọ̀ ìdílé yín ju bó ṣe yẹ lọ, wá àyè láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ nígbà tí ara bá tù yín

  • Ẹ jọ fẹnu kò lórí ohun tí ẹ máa ṣe sí ọ̀rọ̀ náà