Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ta Ló Ń Darí Ayé Yìí?

Ta Ló Ń Darí Ayé Yìí?

Ṣé o rò pé . . .

  • Ọlọ́run ni?

  • àbí àwọn èèyàn?

  • àbí ẹlòmíì?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Gbogbo ayé patapata wà lábẹ́ Èṣù.”​—1 Jòhánù 5:19.

“Ọmọ Ọlọrun . . . wá, kí ó lè pa àwọn iṣẹ́ Èṣù run.”​—1 Jòhánù 3:8, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ O MÁA RÍ

Á jẹ́ kó o mọ àlàyé tó bọ́gbọ́n mu nípa ohun tó fa ìṣòro tó kún inú ayé yìí.​—Ìfihàn 12:12.

Wàá mọ ìdí tó fi yẹ kó o gbà gbọ́ pé ayé yìí ṣì ń bọ̀ wá dáa.​—1 Jòhánù 2:17.

ṢÉ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Mẹ́ta lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:

  • Ọlọ́run máa fòpin sí àkóso Èṣù. Jèhófà ti pinnu pé òun ò ní jẹ́ kí Sátánì máa darí àwọn èèyàn mọ́. Ó ṣèlérí pé òun máa “sọ agbára Satani . . . di asán,” òun sì máa tún gbogbo ohun tí Sátánì ti bà jẹ́ ṣe.​—Hébérù 2:14, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.

  • Ọlọ́run ti yan Jésù pé òun ló máa ṣàkóso ayé. Jésù yàtọ̀ pátápátá sí alákòóso ayé yìí tó jẹ́ ìkà, tí kò mọ̀ ju tara rẹ̀ lọ. Ọlọ́run ṣèlérí nípa àkóso Jésù pé: “Yóò ṣàánú aláìní àti tálákà . . . Yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá.”​—Sáàmù 72:13, 14.

  • Ọlọ́run kò lè parọ́. Bíbélì sọ ní kedere pé: ‘Ọlọ́run ò lè parọ́.’ (Hébérù 6:18) Tí Jèhófà bá ṣèlérí pé òun máa ṣe nǹkan kan, bíi pé ó ti ṣe é tán ló máa ń rí! (Àìsáyà 55:10, 11) “A máa lé alákòóso ayé yìí jáde.”​—Jòhánù 12:31.

RÒ Ó WÒ NÁ

Tí ẹni tó ń ṣàkóso ayé yìí bá kúrò, báwo ni nǹkan ṣe máa rí?

Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé SÁÀMÙ 37:10, 11 àti ÌFIHÀN 21:3, 4.