Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn tó ń ṣe fíìmù máa ń gbé fíìmù ẹ̀mí òkùnkùn jáde lọ́nà téèyàn á fi gbádùn ẹ̀, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra torí ó léwu

Kókó Iwájú Ìwé | Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Agbára Abàmì

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ẹ̀mí Òkùnkùn?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ẹ̀mí Òkùnkùn?

Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló ń ṣiyèméjì nípa àwọn agbára abàmì tàbí ẹ̀mí òkùnkùn. Àwọn kan ronú pé ẹ̀tàn lásán ni, pé àwọn tó ń ṣe fíìmù ló kàn ń fi ṣeré. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ bó ṣe jẹ́ gan-an. Bíbélì fún wa ní àwọn ìkìlọ̀ tó ṣe kedere nípa lílọ́wọ́ sí iṣẹ́ òkùnkùn. Bí àpẹẹrẹ Diutarónómì 18:​10-13 sọ pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ ẹnikẹ́ni tí ń . . . woṣẹ́, pidánpidán kan tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí oníṣẹ́ oṣó, tàbí ẹni tí ń fi èèdì di àwọn ẹlòmíràn tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ẹnikẹ́ni tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú.” Kí nìdí? Ìwé Mímọ́ sọ síwájú sí i pé: “Nítorí gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà . . . Kí o fi ara rẹ hàn ní aláìní-àléébù lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.”

Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé gbogbo iṣẹ́ òkùnkùn kò dáa?

IBI TÓ TI WÁ

Bíbélì sọ fún wa pé kí Ọlọ́run tó dá ayé yìí rárá ló ti dá omilẹgbẹ ańgẹ́lì sókè ọ̀run. (Jóòbù 38:​4, 7; Ìṣípayá 5:11) Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ańgẹ́lì ni Ọlọ́run fún ní òmìnira láti yan ohun tó bá wù wọ́n, ìyẹn ni pé wọ́n lè pinnu láti ṣe rere tàbí búburú. Àwọn kan lára wọn yàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n fi ipò tí Ọlọ́run fi wọ́n sí lọ́run sílẹ̀, wọ́n sì dá wàhálà sínú ayé. Èyí ló mú kí ilẹ̀ ayé “kún fún ìwà ipá.”​—Jẹ́nẹ́sísì 6:​2-5, 11; Júúdà 6.

Bíbélì sọ pé àwọn ańgẹ́lì burúkú yìí máa ń mú káwọn èèyàn hùwà búburú, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣi ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ́nà. (Ìṣípayá 12:9) Wọ́n sì tún máa ń tan àwa èèyàn jẹ torí pé a máa ń fẹ́ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.​—1 Sámúẹ́lì 28:​5, 7; 1 Tímótì 4:1.

Lóòótọ́ àwọn agbára òkùnkùn kan wà tó dà bíi pé wọ́n fi ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. (2 Kọ́ríńtì 11:14) Àmọ́ ká sòótọ́, ńṣe làwọn ańgẹ́lì burúkú yìí ń fẹ́ fọ́ ojú inú àwọn èèyàn kí wọ́n má bàa ríran rí òtítọ́ nípa Ọlọ́run.​—2 Kọ́ríńtì 4:4.

Torí náà, Bíbélì fi hàn pé ewu ńlá wà nínú kéèyàn máa bá àwọn ẹ̀mí òkùnkùn da nǹkan pọ̀. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí àwọn tó fẹ́ di ọmọlẹ́yìn Jésù kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa àṣà yìí ńṣe ni “àwọn tí wọ́n fi idán pípa ṣiṣẹ́ ṣe, kó àwọn ìwé wọn pa pọ̀, wọ́n sì dáná sun wọ́n,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó ńlá ni wọ́n fi rà wọ́n.​—Ìṣe 19:19.

“Àwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n, fíìmù àtàwọn ìwé máa ń ṣàfihàn àwọn emèrè lọ́nà tó ń fani mọ́ra, tó sì rẹwà, èyí ló fàá tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́bìnrin fi ń fẹ́ láti ní agbára ẹ̀mí òkùnkùn yìí.” ​—Gallup Youth Survey, 2014

Bíi tàwọn èèyàn yẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ti pinnu pé àwọn ò ní lọ́wọ́ sí iṣẹ́ òkùnkùn, wọn ò sì ní máa wo àwọn fíìmù tó dá lórí agbára abàmì. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Maria * wà lọ́mọ ọdún méjìlá [12], ó jọ pé ó lágbára láti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la tàbí jàǹbá tó máa ṣẹlẹ̀. Ó máa ń woṣẹ́ fún àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀, ohun tó bá sì sọ máa ń ṣẹ, torí náà ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀mí òkùnkùn.

Èrò Maria ni pé Ọlọ́run ló fún òun lẹ́bùn tí òun fi ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Àmọ́ ó sọ pé: “Nǹkan kan ń jà gùdù lọ́kàn mi. Mo máa ń rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹlòmíì. Àmọ́ mi ò lè rí ọjọ́ iwájú tèmi, bó tilẹ̀ jẹ́ ó wù mí gan-an pé kí n mọ̀ ọ́n.”

Gbogbo èyí mú kí nǹkan tojú sú Maria, torí náà ó gbàdúrà sí Ọlọ́run. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wàásù fún un, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Maria kẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì pé kì í ṣe Ọlọ́run ló fún òun lágbára tí òun fi ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la. Ó tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ẹni tó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ kó ohunkóhun tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí òkùnkùn dànù. (1 Kọ́ríńtì 10:21) Kí ló wá yọrí sí? Maria kó gbogbo ìwé àtàwọn nǹkan míì tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ òkùnkùn dànù. Ní báyìí, òun náà ti ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó kọ́ látinú Bíbélì.

Nígbà tí Michael wà lọ́dọ̀ọ́, ó fẹ́ràn kó máa ka àwọn ìwé tó dá lórí àwọn agbára abàmì. Ó sọ pé: “Ó máa ń wù mí kí n máa ṣe bíi tàwọn ẹgbẹ́ mi tí wọ́n jẹ́ akọni tí mò ń kà nípa wọn nínú ìwé.” Díẹ̀díẹ̀, ó wá mọ́ Michael lára láti máa ka àwọn ìwé idán àtàwọn ìwé ẹ̀mí èṣù míì. Ó sọ pé: “Torí mo fẹ́ ṣe ojúmìító ni mo ṣe ń ka àwọn ìwé tí mo sì ń wo àwọn fíìmù tó dá lórí àwọn nǹkan yẹn.”

Àmọ́, ohun tí Michael kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ kó rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kó máa fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tó ń kà. Ó sọ pé: “Mo ṣàkọsílẹ̀ gbogbo nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí òkùnkùn, mo sì kó wọn sọnù. Èyí kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Nínú 1 Kọ́ríńtì 10:​31, Bíbélì sọ pé: ‘Máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.’ Torí náà, mo bi ara mi pé, ‘Ṣé ìwé tí mò ń kà yìí máa jẹ́ kí n lè fògo fún Ọlọ́run?’ Tí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, mi ò ní kà á rárá.”

Ńṣe ni Bíbélì dà bíi fìtílà. Ó máa ń là wá lóye, ó sì ti jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run kórìíra gbogbo iṣẹ́ òkùnkùn. (Sáàmù 119:105) Àmọ́, Bíbélì tún jẹ́ ká mọ nǹkan míì. Ìyẹn ni ìlérí àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa mú gbogbo agbára òkùnkùn kúrò nínú ayé. Àyípadà ńlá ni èyí máa jẹ́ fún aráyé. Bí àpẹẹrẹ Sáàmù 37:​10, 11 sọ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.””

^ ìpínrọ̀ 10 A ti yí àwọn orúkọ inú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.