Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Táá Mú Kí Ìdílé Rẹ Láyọ̀

Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Táá Mú Kí Ìdílé Rẹ Láyọ̀

Ẹ̀bùn pàtàkì ni ìgbéyàwó àti ọmọ jẹ́. Ẹlẹ́dàá wa ló sì fún wa. Ó fẹ́ kí ìdílé wa láyọ̀. Ìdí nìyẹn tó fi fún wa ní ìwé àtayébáyé kan, ó sì ní ká máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú ẹ̀ kí ìdílé wa lè láyọ̀. Wo àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n yìí.

Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ Máa Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Aya Yín

“Kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn bí ara wọn. Ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, torí pé kò sí èèyàn kankan tó jẹ́ kórìíra ara rẹ̀, àmọ́ á máa bọ́ ara rẹ̀, á sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.”​—ÉFÉSÙ 5:28, 29.

Ọkọ ni olórí ìdílé. (Éfésù 5:23) Àmọ́, ọkọ rere kì í le koko mọ́ àwọn ará ilé ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í kanra mọ́ wọn. Ó mọyì ìyàwó rẹ̀ gan-an, ó máa ń pèsè àwọn ohun tó nílò, ó sì máa ń ṣìkẹ́ rẹ̀. Ó máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti múnú ẹ̀ dùn, ó sì máa ń gba tiẹ̀ rò. (Fílípì 2:4) Ó máa ń sọ tinú ẹ̀ fún ìyàwó ẹ̀, ó sì máa ń tẹ́tí sílẹ̀ tí ìyàwó ẹ̀ bá ń sọ̀rọ̀. Kì í ‘bínú sí i lọ́nà òdì,’ kì í sì í lù ú tàbí kó máa sọ̀rọ̀ burúkú gbá a lórí.​—Kólósè 3:19.

Ẹ̀yin Aya, Ẹ Máa Bọ̀wọ̀ fún Àwọn Ọkọ Yín

“Kí aya ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”​—ÉFÉSÙ 5:33.

Tí aya bá ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ ẹ̀, tó sì ń tì í lẹ́yìn, ilé á tòrò. Bí ọkọ ẹ̀ bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe, kò ní kàn án lábùkù, àmọ́ á ṣì máa fi sùúrù bá a sọ̀rọ̀, á sì máa bọ̀wọ̀ fún un. (1 Pétérù 3:4) Tó bá fẹ́ bá a sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan, á wá àkókò tó dáa jù láti ṣe bẹ́ẹ̀, á sì bá a sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.​—Oníwàásù 3:7.

Jẹ́ Olóòótọ́ sí Ọkọ tàbí Aya Rẹ

“Ọkùnrin á . . . fà mọ́ ìyàwó rẹ̀, wọ́n á sì di ara kan.”​—JẸ́NẸ́SÍSÌ 2:24.

Bí ọkùnrin àti obìnrin bá ṣègbéyàwó, àjọṣe tímọ́tímọ́ ti wà láàárín wọn nìyẹn, wọ́n ti di tọkọtaya. Torí náà, ó yẹ kí tọkọtaya máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kí ìgbéyàwó wọn wà níṣọ̀kan, kí wọ́n máa bára wọn sọ̀rọ̀ látọkàn wá, kí wọ́n sì máa ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà gbogbo, kódà nínú àwọn nǹkan tó dà bíi pé kò tó nǹkan. Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn, kí wọ́n má ṣe ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì àfi ọkọ tàbí aya wọn nìkan. Ìbànújẹ́ ńlá gbáà lẹni tó bá lójú síta máa fà fún ọkọ tàbí aya rẹ̀. Kò ní jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán ara wọn mọ́, ó sì lè tú ìdílé ká.​—Hébérù 13:4.

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Máa Tọ́ Àwọn Ọmọ Yín

“Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀; kódà tó bá dàgbà, kò ní kúrò nínú rẹ̀.”​—ÒWE 22:6.

Ọlọ́run gbé iṣẹ́ kan lé àwọn òbí lọ́wọ́. Ó ní kí wọ́n kọ́ àwọn ọmọ wọn. Ìyẹn sì máa gba pé kí wọ́n kọ́ wọn béèyàn ṣe ń hùwà, káwọn òbí pàápàá sì fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn. (Diutarónómì 6:6, 7) Bọ́mọ kan bá tiẹ̀ ṣìwà hù, òbí tó gbọ́n ò ní bínú kọjá bó ṣe yẹ. Irú òbí bẹ́ẹ̀ á ‘yára láti gbọ́rọ̀, á lọ́ra láti sọ̀rọ̀, kò sì ní tètè máa bínú.’ (Jémíìsì 1:19) Bí òbí náà bá tiẹ̀ wá rí i pé ó yẹ kóun bá ọmọ náà wí, ìfẹ́ ló máa fi bá a wí, kì í ṣe pẹ̀lú ìbínú.

Ẹ̀yin Ọmọ, Ẹ Máa Gbọ́ràn Sí Àwọn Òbí Yín Lẹ́nu

“Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu . . . ‘Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ.’”​—ÉFÉSÙ 6:1, 2.

Ó yẹ káwọn ọmọ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn lẹ́nu, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Táwọn ọmọ bá ń bọlá fáwọn òbí wọn, á mú kí ayọ̀ wà nínú ilé, á mú kí àlàáfíà jọba, á sì mú kí ìdílé wà níṣọ̀kan. Àwọn ọmọ tó ti dàgbà náà ṣì gbọ́dọ̀ máa bọlá fáwọn òbí wọn, kí wọ́n rí i dájú pé wọ́n ń tọ́jú àwọn òbí wọn dáadáa. Ìyẹn lè gba pé kí wọ́n máa bá wọn tún ilé ṣe tàbí kí wọ́n fún wọn lówó tí wọ́n lè fi bójú tó ara wọn.​—1 Tímótì 5:3, 4.