Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Eyin Oko—E Mu Ki Ile Yin Tura

Eyin Oko—E Mu Ki Ile Yin Tura

ÀWỌN nǹkan wo ló yẹ kí ọkọ máa pèsè fún ìyàwó rẹ̀? Ọ̀pọ̀ ló rò pé tí ọkọ bá ti ń pèsè jíjẹ àti mímú, tó sì ń rí owó mú wálé, àbùṣe bù ṣe. Àwọn ìyàwó míì wà tó ní gbogbo nǹkan yìí àmọ́ tí wọ́n ṣì nímọ̀lára pé ọkọ àwọn ò tọ́jú àwọn tó. Obìnrin ará Sípéènì kan tó ń jẹ́ Rosa sọ pé, “Adára-níta-máà-dára-nílé ni ọkọ mi.” Obìnrin míì tó ń jẹ́ Joy láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ pé, “Mi ò gbọ́dọ̀ sọ ohun tó yàtọ̀ sí ti ọkọ mi, ńṣe lọ́ máa ké mọ́ mi pé, ‘Gbogbo ohun tí mo bá sọ lo gbọ́dọ̀ gbà torí pé èmi ni ọkọ ẹ.’”

Báwo ni ọkọ kan ṣe lè fìfẹ́ bójú tó ilé rẹ̀? Kí ló yẹ kí ọkọ máa ṣe bó bá fẹ́ kí ilé rẹ̀ tura tàbí kó jẹ́ “ibi ìsinmi” fún ìyàwó rẹ̀?—Rúùtù 1:9.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ NÍPA IPÒ ỌKỌ NÍNÚ ILÉ

Bó tílẹ̀ jẹ́ pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ọkọ náà ló fi ń wo aya, síbẹ̀, Bíbélì sọ pé ipò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni kálukú wọn wà nínú ìdílé. Ìwé Róòmù 7:2 sọ pé obìnrin ti a gbé níyàwó wà lábẹ́ “òfin ọkọ rẹ̀.” Bí iléeṣẹ́ kan ṣe máa ń yan ẹnì kan láti jẹ́ olùdarí, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run ṣe yan ọkọ láti jẹ́ orí aya rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Fún ìdí yìí, ọkọ ló gbọ́dọ̀ máa mú ipò iwájú nínú ìdílé.

Báwo ló ṣe yẹ kí ọkọ kan lo ọlá-àṣẹ tí Ọlọ́run fún un yìí? Bíbélì fún àwọn ọkọ nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ.” (Éfésù 5:25) Bó tílẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò gbéyàwó, àpẹẹrẹ rẹ̀ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ ọkọ rere. Jẹ́ ká wo díẹ̀ nínú àwọn àpẹẹrẹ náà.

JÉSÙ NI ÀWÒKỌ́ṢE TÓ DÁRA JÙ FÚN ÀWỌN ỌKỌ

Jésù máa ń tu àwọn èèyàn lára, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Jésù sọ fún àwọn tí làálàá àti ìṣòro ìgbésí ayé ti wọ̀ lọ́rùn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, . . . èmi yóò sì tù yín lára.” (Mátíù 11:28, 29) Jésù sábà máa ń wo àwọn aláìsàn sàn, ó sì máa ń kọ́ wọn nípa Ọlọ́run. Èyí mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ràn rẹ̀ torí pé ó máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́.

Bí àwọn ọkọ ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Ẹ máa ran àwọn aya yín lọ́wọ́ nínu ilé. Rosa tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ńṣe ni ọkọ mi máa ń hùwà sí mi bíi pé ẹrú ni mí.” Ọ̀pọ̀ àwọn aya ló máa ń ní irú ìmọ̀lára yìí. Àmọ́ àwọn ọkọ míì kì í ṣe bẹ́ẹ̀, bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Kweku sọ pé: “Mo sábà máa ń bi ìyàwó mi pé kí ni mo lè bá a ṣe. Mo sì máa ń ràn án lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ilé torí mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an.”

Jésù lẹ́mìí ìgbatẹnirò, ó sì máa ń fọ̀rọ̀ ro ara ẹ̀ wò. Obìnrin kan wà tí àìsàn burúkú kan ti hàn léèmọ̀ fún ọdún méjìlá. Nígbà tó gbọ́ pé Jésù máa ń ṣiṣẹ́ ìyanu, ‘ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé: “Bí mo bá fọwọ́ kan ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ lásán, ara mi yóò dá.”’ Obìnrin náà ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, ó sún mọ́ Jésù, ó sì fọwọ́ kan ìṣẹ́tí ẹ̀wù rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ara rẹ̀ yá. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan máa sọ pé ìwà ọ̀yájú ni obìnrin yẹn hù, àmọ́ Jésù rí i pé ara ti ni ín dé góńgó. * Jésù kò dójú ti obìnrin náà tàbí kó sọ̀rọ̀ burúkú sí i, ńṣe ló fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin, . . . Máa lọ ní àlàáfíà, kí o sì ní ìlera kúrò lọ́wọ́ àìsàn burúkú tí ń ṣe ọ́.” Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun lẹ́mìí ìgbatẹnirò.—Máàkù 5:25-34.

Bí àwọn ọkọ ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Gba ti ìyàwó rẹ rò tó o bá rí i pé ó rẹ̀ ẹ́, kó o sì ṣe sùúrù fún un. Tí ìyàwó rẹ bá hùwà bákan-bákan, fi ara rẹ sí ipò tó wà kó o lè lóye ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ricardo sọ pé: “Bí mo bá rí i pé ara ń kan ìyàwó mi, mo máa ń sapá kí n máa bàa sọ ohun tó máa dá kún ìbínú rẹ̀.”

Jésù máa ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀. Jésù kì í fi ohunkóhun pa mọ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Gbogbo nǹkan tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi ni mo ti sọ di mímọ̀ fún yín.” (Jòhánù 15:15) Àwọn ìgbà míì wà tí Jésù máa ń fẹ́ dá wà kó lè gbàdúrà. Síbẹ̀ ó máa ń wá àyè láti sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ní alẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn pẹ̀lú wọn, ó sọ fún wọn pé òun ní “ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi.” (Mátíù 26:38) Jésù kì í yé bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀, kódà, tí wọ́n bá ṣe ohun tó dùn ún pàápàá.—Mátíù 26:40, 41.

Àpẹẹrẹ Jésù lè ran ọkùnrin kan lọ́wọ́ láti jẹ́ ọkọ onífẹ̀ẹ́ àti bàbá rere

Bí àwọn ọkọ ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Máa sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún ìyàwó rẹ. Àwọn obìnrin kan máa ń ṣàròyé pé ọkọ àwọn máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa níta, àmọ́ tí wọ́n bá dé ilé, ńṣe ni gbogbo rẹ̀ á di wẹ́lo. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, obìnrin kan tó ń jẹ Ana sọ bí inú òun ṣe máa ń dùn tí ọkọ òun bá tú ọkàn rẹ̀ jáde, ó ní: “Ó máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé ọkọ mi nífẹ̀ẹ́ mi, èyí sì máa ń jẹ́ kí ọkàn mi túbọ̀ fà mọ́ ọn.”

Bí ìyàwó rẹ bá ṣẹ̀ ẹ́, má torí ìyẹn bá a yan odì. Obìnrin kan sọ pé: “Bí mo bá ṣẹ ọkọ mi pẹ́nrẹ́n, ńṣe ló máa pa mí tì, kò sì ní bá mi sọ̀rọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Èyí máa ń mú kí n dá ara mi lẹ́bi, ó sì máa ń jẹ́ kó dà bíi pé mi ò wúlò.” Àmọ́, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Edwin máa ń sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ó ní: “Bí inú bá bí mi, mo máa ń kọ́kọ́ ṣe sùúrù, màá sì wá àkókò tó wọ̀ fún èmi àti ìyàwó mi láti yanjú ohun tó ṣẹlẹ̀.”

Látìgbà tí ọkọ Joy tá a mẹ́nu bà lókè ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Joy ti ń rí ìyípadà nínú ìwà rẹ̀. Joy wá sọ pé: “Ìwà ọkọ mi ti yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀, ó sì ń sapá láti tẹ̀ lé apẹẹrẹ Jésù nípa fífi ìfẹ́ hàn sí mi dáadáa.” Ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya ló ń jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ Bíbélì. Bí ìwọ náà bá fẹ́ jàǹfààní yìí, sọ fún Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan pé kó wá kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.

^ ìpínrọ̀ 10 Níbàámu pẹ̀lú Òfin Mósè, àìsàn tí obìnrin yìí ní sọ ọ́ di aláìmọ́, ẹnikẹ́ni tó bá sì fọwọ́ kàn yóò di aláìmọ́.—Léfítíkù 15:19, 25.