Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn Àmì Wo Ló Fi Hàn Pé A Ti Wà Ní “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn,” Tàbí “Òpin Ayé”?

Àwọn Àmì Wo Ló Fi Hàn Pé A Ti Wà Ní “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn,” Tàbí “Òpin Ayé”?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bíbélì sọ nípa àwọn nǹkan táá máa ṣẹlẹ̀, bí nǹkan á ṣe rí àti ìwà táwọn èèyàn á máa hù táá jẹ́ ká mọ̀ pé a ti wà ní “ìparí ètò àwọn nǹkan [yìí],” tàbí “òpin ayé.” (Matthew 24:3; Bíbélì Mímọ́) Bíbélì pe àkókò wa yìí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” àti “àkókò òpin,” tàbí ‘ìgbà ìkẹyìn.’​—2 Tímótì 3:1; Dáníẹ́lì 8:19; Bíbélì Mímọ́.

Àwọn ohun tí Bíbélì sọ pé á máa ṣẹlẹ̀ ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn”?

 Bíbélì sọ nípa ọ̀pọ̀ nǹkan táá máa ṣẹlẹ̀ tó máa jẹ́ “àmì” pé a ti wà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. (Lúùkù 21:7) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀:

 Ogun á máa jà kárí ayé. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.” (Mátíù 24:7) Bákan náà, Ìfihàn 6:4 sọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ pé ẹlẹ́ṣin pupa kan tó dúró fún ogun máa “mú àlàáfíà kúrò ní ayé.”

 Àìtó oúnjẹ. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àìtó oúnjẹ . . . máa wà.” (Mátíù 24:7) Ìwé Ìfihàn tún ṣàpẹẹrẹ agẹṣin kan tó máa mú kí ìyàn wà kárí ayé.​—Ìfihàn 6:5, 6.

 Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára. Jésù sọ pé ‘ìmìtìtì ilẹ̀ máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.’ (Mátíù 24:7; Lúùkù 21:11) Àwọn ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé ń mú ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ, ó sì ń fa ipò òṣì ju ti ìgbàkígbà rí lọ.

 Àjàkálẹ̀ àrùn. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé “àjàkálẹ̀ àrùn” máa wà kárí ayé.​—Lúùkù 21:11.

 Ìwà ọ̀daràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń hùwà ọ̀daràn, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn “ìwà tí kò bófin mu máa pọ̀ sí i.”​—Mátíù 24:12.

 Àwọn èèyàn á máa ba ayé jẹ́. Ìfihàn 11:18 sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn á máa “run ayé.” Onírúurú ọ̀nà ni wọ́n á máa gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n á máa hùwà ipá àti ìwà ìbàjẹ́, wọ́n á sì tún máa ṣe ohun tó máa ba àyíká jẹ́.

 Ìwàkiwà. Nínú 2 Tímótì 3:1-4, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn níbi gbogbo máa jẹ́ “aláìmoore, aláìṣòótọ́, . . . kìígbọ́-kìígbà, abanijẹ́, ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu, ẹni tó burú gan-an, ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ ohun rere, ọ̀dàlẹ̀, alágídí, ajọra-ẹni-lójú.” Ìwà àwọn èèyàn lásìkò yìí máa burú débi pé Bíbèlì pe àkókò yìí ní “àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira.”

 Ìdílé á máa tú ká. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nínú 2 Tímótì 3:2, 3 pé ọ̀pọ̀ èèyàn á jẹ́ “ẹni tí kò ní ìfẹ́ àdámọ́ni” fún ìdílé wọn. Kò tán síbẹ̀ o, àwọn ọmọ náà á máa ‘ṣàìgbọràn sí òbí.’

 Ìfẹ́ táwọn èèyàn ní fún Ọlọ́run máa dín kù. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ máa tutù.” (Mátíù 24:12) Ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò ní fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run mọ́. Bákan náà, 2 Tímótì 3:4 sọ pé tó bá di ọjọ́ ìkẹyìn, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ “á fẹ́ràn ìgbádùn dípò Ọlọ́run.”

 Wọ́n á fi ẹ̀sìn bojú máa tan àwọn èèyàn. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nínú 2 Tímótì 3:5 pé àwọn èèyàn á máa ṣe bí ẹni tó ń sin Ọlọ́run, àmọ́ wọn ò ní tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀.

 Àwọn èèyàn á túbọ̀ lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Ìwé Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àkókò òpin,” ìmọ̀ Bíbélì táwọn èèyàn ní á túbọ̀ pọ̀ sí i, wọ́n á sì lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì.​—Dáníẹ́lì 12:4, àlàyé ìsàlẹ̀.

 Iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.”​—Mátíù 24:14.

 Àwọn èèyàn ò ní kíyè sára, wọ́n á sì máa ṣàríwísí. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn níbi gbogbo ò ní kíyè sí àwọn àmì tó ṣe kedere tó fi hàn pé òpin ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé. (Mátíù 24:37-39) Bákan náà, 2 Pétérù 3:3, 4 sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn kan á máa ṣàríwísí àwọn ẹ̀rí náà, wọ́n á sì fọwọ́ rọ́ ọ tì sẹ́yìn.

 Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ ló ṣẹ. Jésù sọ pé kì í ṣe díẹ̀ tàbí ọ̀pọ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí lá máa ṣẹ lásìkò yìí, kàkà bẹ́ẹ̀ ó jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo ẹ̀ pátápátá lá máa ṣẹlẹ̀ lásìkò kan náà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn.​—Mátíù 24:33.

Ṣé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí?

 Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé àti ìṣirò tá a ṣe nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé ọdún 1914 tí wọ́n ja Ogun Àgbáyé Kìíní làwọn ọjọ́ ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀. Kó o lè mọ bí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ṣe fi hàn pé a ti wà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, wo fídíò yìí:

 Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run lọ́dún 1914. Ohun àkọ́kọ́ tó sì ṣe ni pé ó lé Sátánì Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run, gbogbo ohun tí wọ́n sì lè ṣe ò kọjá ilẹ̀ ayé. (Ìfihàn 12:7-12) Bí ìwà àwọn èèyàn ṣe burú gan-an fi hàn pé Èṣù ló ń darí aráyé, ìyẹn ló sì mú kí ọjọ́ ìkẹyìn yìí jẹ́ “àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira.”​—2 Tímótì 3:1.

 Bí nǹkan ṣe le lákòókò yìí ń kó ìdààmú bá ọ̀pọ̀ èèyàn. Kódà, ọ̀pọ̀ ló ń bẹ̀rù pé bóyá làwọn èèyàn á lè gbé pa pọ̀ níṣọ̀kan mọ́. Ọkàn àwọn míì ò sì balẹ̀ nípa bí nǹkan ṣe máa rí fáwa èèyàn lọ́jọ́ iwájú.

 Àwọn kan wà tí wọ́n ní àwọn ìṣòro tí gbogbo èèyàn náà ní, síbẹ̀ wọ́n nírètí, ọkàn wọn sì balẹ̀. Ó dá wọn lójú pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó yanjú gbogbo ìṣòro aráyé. (Dáníẹ́lì 2:44; Ìfihàn 21:3, 4) Wọ́n ń fi sùúrù dúró de ìgbà tí Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ sì ń tù wọ́n nínú, pé: “Ẹni tó bá fara dà á dé òpin máa rí ìgbàlà.”​—Mátíù 24:13; Míkà 7:7.