Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Irú Ẹni Wo Ni Ọlọ́run?

Irú Ẹni Wo Ni Ọlọ́run?

Bá a bá ṣe ń mọ ìwà ẹnì kan sí i, èyí á jẹ́ ká túbọ̀ máa mọ ẹni náà, àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ á sì máa jinlẹ̀ sí i. Lọ́nà kan náà, bá a bá ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ìwà àti ànímọ́ Jèhófà, èyí á jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́, àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ á sì máa jinlẹ̀ sí i. Nínú gbogbo àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, mẹ́rin ló ta yọ jù, àwọn ni agbára, ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo àti ìfẹ́.

ỌLỌ́RUN LÁGBÁRA

“Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Kíyè sí i, ìwọ fúnra rẹ ni ó ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé nípa agbára ńlá rẹ.”​JEREMÁYÀ 32:17.

Ọ̀pọ̀ nǹkan là ń rí nínú ìṣẹ̀dá tó jẹ́rìí sí i pé Ọlọ́run lágbára. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá jáde síta nígbà tí oòrùn bá ràn, báwo ni ara rẹ ṣe máa ń rí? Ó dájú pé ńṣe ni oòrùn yẹn á máa rà ẹ́ lára fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Ṣùgbọ́n tá a bá fẹ́ sọ ọ́ bó ṣe jẹ́ ní pàtó, ẹ̀rí agbára Ọlọ́run lò ń rí lára ẹ yẹn. Báwo tiẹ̀ ni oòrùn ṣe lágbára tó? Ìwádìí fi hàn pé inú oòrùn lọ́hùn-ún máa ń  gbóná tó ìpele mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000,000) lórí òṣùwọ̀n Celsius. Ní ìṣẹ́jú àáyá kan, iná tó ń bù yẹ̀rì jáde láti ara oòrùn dà bí ìgbà tí ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù bọ́ǹbù runlérùnnà bá bú gbàù lẹ́ẹ̀kan náà.

Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kékeré ni oòrùn jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àìmọye mílíọ̀nù ìràwọ̀ míràn tó kún inú ọ̀run lọ́hùn-ún. Ọ̀kan lára irú àwọn ìràwọ̀ bẹ́ẹ̀ ni UY Scuti. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì sọ pé ìràwọ̀ yìí tóbi ju oòrùn lọ ní 1,700 ìgbà. UY Scuti tóbi débi pé ká sọ pé òun ló wà níbi tí oòrùn wà, ó máa gba gbogbo ayé yìí, á tiẹ̀ tún dé ibi tí pílánẹ́ẹ̀tì Jupiter wà. Ó ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tí Jeremáyà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni ó ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé nípa agbára ńlá rẹ̀.

Báwo la ṣe ń jàǹfààní agbára Ọlọ́run? Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá ló ń gbé ẹ̀mí wa ró. Lára wọn ni oòrùn àtàwọn ohun àmúṣọrọ̀ tó kù tí Ọlọ́run dá sáyé. Láfikún sí ìyẹn, Ọlọ́run tún máa ń lo agbára rẹ̀ láti ṣe wá lóore lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Lọ́nà wo? Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, Ọlọ́run fún Jésù lágbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó kàmàmà. Bíbélì sọ pé: “Àwọn afọ́jú ń padà ríran, àwọn arọ sì ń rìn káàkiri, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití sì ń gbọ́ràn, a sì ń gbé àwọn òkú dìde.” (Mátíù 11:5) Lónìí ńkọ́? Bíbélì sọ pé: “Ó ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀, àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà.” (Aísáyà 40:​29, 31) Ìyẹn ni pé Ọlọ́run lè fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” ká lè kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé ká sì lè fara dà á. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Ó dájú pé ó máa wù ẹ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run tó lè fi ìfẹ́ lo agbára ńlá rẹ̀ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀.

ỌLỌ́RUN GBỌ́N

“Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe.”​SÁÀMÙ 104:24.

Bá a bá ṣe ń mọ̀ sí i nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, bẹ́ẹ̀ ni ẹnu á máa yà wá tí àá sì rí i pé ọgbọ́n Ọlọ́run kò láfiwé. Àpẹẹrẹ kan ni ti ẹ̀ka ìwádìí tí wọ́n ń pè ní biomimetics tàbí biomimicry, ìyẹn bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá tí wọ́n á sì lo ọgbọ́n inú rẹ̀ láti ṣe oríṣiríṣi nǹkan, títí kan ọkọ̀ òfuurufú.

Ohun àgbàyanu gbáà ni ojú àwa èèyàn jẹ́ nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá

Ọ̀kan lára ibi tá a ti lè rí ọgbọ́n Ọlọ́run lọ́nà tó kàmàmà ni ara àwa èèyàn. Àpẹẹrẹ kan ni bí àwọn sẹ́ẹ̀lì kéékèèké ṣe máa ń di ọmọ inú oyún. Sẹ́ẹ̀lì kan ṣoṣo ló máa ń di ọmọ, á sì ní gbogbo ìsọfúnni tó máa wà nínú àpilẹ̀ àbùdá ọmọ náà. Sẹ́ẹ̀lì yìí á wá bẹ̀rẹ̀ sí í bí ọ̀pọ̀ sẹ́ẹ̀lì míì tó jọra wọn. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn sẹ́ẹ̀lì náà á bẹ̀rẹ̀ sí í pín sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn kan á di sẹ́ẹ̀lì inú ẹ̀jẹ̀, àwọn míì á di sẹ́ẹ̀lì inú ọpọlọ àti sẹ́ẹ̀lì inú egungun. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí á para pọ̀ di ẹ̀yà ara, wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́. Láàárín oṣù mẹ́sàn-án, sẹ́ẹ̀lì kékeré ọjọ́sí ti di ọmọ làǹtìlanti. Ẹ ò rí i bí èyí ṣe gbé ọgbọ́n Ọlọ́run yọ lọ́nà àrà. Èyí mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé òótọ́ ni ohun tí òǹkọ̀wé Bíbélì kan sọ pé: “Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.”​—Sáàmù 139:14.

Báwo la ṣe ń jàǹfààní nínú ọgbọ́n Ọlọ́run? Ẹlẹ́dàá wa mọ àwọn nǹkan tá a nílò ká lè láyọ̀. Ìmọ̀ àti òye rẹ̀ kò lópin, torí náà ó máa ń fún wa ní ìmọ̀ràn ọgbọ́n láti inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó rọ̀ wá pé: “Ẹ máa . . . dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì.” (Kólósè 3:13) Ṣé o rò pé ìmọ̀ràn yẹn bọ́gbọ́n mu? Bẹ́ẹ̀ ni. Ìwádìí fi hàn pé téèyàn bá ń dárí jini, èèyàn á máa rí oorun sùn dáadáa, ó sì máa ń dín ẹ̀jẹ̀ ríru kù. Bákan náà, ó tún máa ń dín ìdààmú ọkàn àtàwọn àìsàn míì kù. Ọlọ́run dà bí ọ̀rẹ́ kan tó máa ń fúnni ní ìmọ̀ràn ọgbọ́n nígbà gbogbo. (2 Tímótì 3:​16, 17) Ṣé ó wù ẹ́ kó o ní irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀?

ỌLỌ́RUN JẸ́ ONÍDÀÁJỌ́ ÒDODO

“Olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà.”​SÁÀMÙ 37:28.

Gbogbo ìgbà ni Ọlọ́run máa ń ṣe ohun tí ó tọ́. Kódà, Bíbélì sọ pé: “Kí a má rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò hùwà burúkú àti pé kí Olódùmarè hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu!” (Jóòbù 34:10) Àwọn ìdájọ́ Jèhófà tọ́, ìdí nìyẹn tí onísáàmù náà fi sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ yóò fi ìdúróṣánṣán ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.” (Sáàmù 67:4) Torí pé “Jèhófà ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́,” kò sẹ́ni tó lè tàn án jẹ. Ó lágbára láti mọ ohun tó jóòótọ́ kó sì ṣe ìdájọ́ tó yẹ. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Bákan náà, Ọlọ́run ń rí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ àti ìwà ìbàjẹ́ tó kún inú ayé, ó sì ṣèlérí pé láìpẹ́, òun máa pa àwọn ẹni burúkú run.​—Òwe 2:22.

Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run ò dà bí adájọ́ burúkú tí kò mọ ju kó kàn máa fìyà jẹni. Ọlọ́run máa ń fi àánú hàn sí wa nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́.” Kódà tí ẹni burúkú bá ronúpìwàdà, ó máa rí àánú Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ìyẹn kì í ṣe ìdájọ́ òdodo?​—Sáàmù 103:8; 2 Pétérù 3:9.

Báwo la ṣe ń jàǹfààní nínú ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run? Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:​34, 35) À ń jàǹfààní nínú ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run torí pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú. A lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀ láìka ẹ̀yà tá a ti wá, orílẹ̀-èdè tá a ti wá, bá a ṣe kàwé tó tàbí ipò wa láwùjọ.

Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àwa náà sì ń jàǹfààní ìyẹn láìka ẹ̀yà wa tàbí ipò wa láwùjọ sí

Torí pé Ọlọ́run fẹ́ ká túbọ̀ mọyì ìdájọ́ òdodo rẹ̀, ó fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní ẹ̀rí ọkàn. Ìwé Mímọ́ sọ pé ẹ̀rí ọkàn dà bí òfin tá a ‘kọ sínú ọkàn-àyà wa,’ tó máa ‘jẹ́ wa lẹ́rìí’ bóyá a ṣe ohun tó dára àbí a ṣe ohun tó burú. (Róòmù 2:15) Àǹfààní wo ni èyí ń ṣe fún wa? Tá a bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa dáadáa, ó lè kì wá nílọ̀ ká má bàa ṣe ohun tó léwu tàbí ohun tí kò bá òfin mu. Tá a bá ṣe àṣìṣe, ó lè mú ká ronú pìwà dà ká sì ṣe ohun tó tọ́. Bá a ṣe túbọ̀ ń lóye ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, ńṣe ló ń mú ká máa sún mọ́ ọn!

ỌLỌ́RUN JẸ́ ÌFẸ́

“Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.”​—1 JÒHÁNÙ 4:8.

Ọlọ́run máa ń fi agbára hàn, ó sì máa ń fi ọgbọ́n àti ìdájọ́ òdodo hàn. Àmọ́, Bíbélì kò sọ pé Ọlọ́run jẹ́ agbára, tàbí pé ó jẹ́ ọgbọ́n, kò sì sọ pé ó jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ohun tó sọ ni pé Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé Ọlọ́run lè lo agbára rẹ̀ láti ṣe ohun tó bá fẹ́, ìdájọ́ òdodo àti ọgbọ́n rẹ̀ ló sì ń darí àwọn ohun tó ń ṣe. Ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ló ń mú kó ṣe nǹkan. Ìfẹ́ rẹ̀ ń hàn nínú gbogbo ohun tó ń ṣe.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kò ṣàìní ohunkóhun, ìfẹ́ ló mú kó dá àwa èèyàn sórí ilẹ̀ ayé, tó sì dá àwọn áńgẹ́lì sọ́run, tí gbogbo wa sì ń gbádùn ìfẹ́ àti ìkẹ́ rẹ̀ títí dòní. Ó dá ayé lọ́nà tó tura fún àwa èèyàn láti gbé. Ó sì ń bá a nìṣó láti fi ìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn ní ti pé “ó ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.”​—Mátíù 5:45.

Yàtọ̀ síyẹn, “Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jákọ́bù 5:11) Ó máa ń fìfẹ́ hàn sí àwọn tó bá ń wá a tọkàntọkàn kí wọ́n lè sún mọ́ ọn. Ọlọ́run mọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Kódà, Bíbélì sọ pé ó ‘bìkítà fún ẹ.’​1 Pétérù 5:7.

Báwo la ṣe ń jàǹfààní nínú ìfẹ́ Ọlọ́run? A máa ń gbádùn bí ojú ọjọ́ ṣe máa ń rẹwà nígbà tí oòrùn bá ń wọ̀, a máa ń láyọ̀ bá a ṣe ń wojú ọmọ wa jòjòló tó ń rẹ́rìn-ín, a sì máa ń mọyì ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan inú ìdílé wa. A lè má fi bẹ́ẹ̀ ka àwọn nǹkan yìí sí bàbàrà, àmọ́ ńṣe ni wọ́n ń mú ká túbọ̀ gbádùn ayé wa.

Ọ̀nà míì tá a tún ń gbà jàǹfààní ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé a lè gbàdúrà sí i. Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” Baba onífẹ̀ẹ́ ni Ọlọ́run, ó fẹ́ ká máa béèrè ohunkóhun tá a bá fẹ́ lọ́wọ́ òun. Nítorí pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, ó ṣèlérí pé òun máa fún wa ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”​—Fílípì 4:​6, 7.

Ṣé àwọn nǹkan tá a ti sọ nípa agbára Ọlọ́run, ọgbọ́n rẹ̀, ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti ìfẹ́ rẹ̀ ti wá jẹ́ kó o mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́? Kó o lè túbọ̀ mọyì Ọlọ́run, a rọ̀ ẹ́ pé kó o kà nípa àwọn nǹkan tó ti gbé ṣe àti àwọn ohun tó ṣì máa ṣe fún ẹ lọ́jọ́ iwájú.

IRÚ ẸNI WO NI ỌLỌ́RUN? Jèhófà lágbára ju gbogbo alágbára lọ, òun ló gbọ́n jù lọ, ó sì tún jẹ́ onídàájọ́ òdodo. Àmọ́, ohun tó fà wá mọ́ra jù nípa rẹ̀ ni pé ó jẹ́ ìfẹ́