Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ara Ẹ Ṣe Lè Mọlé Nínú Ìjọ Tuntun

Bí Ara Ẹ Ṣe Lè Mọlé Nínú Ìjọ Tuntun

ṢÉ O ti kúrò nínú ìjọ kan lọ sí ìjọ míì rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá gba ohun tí Jean-Charles sọ, ó ní: “Tó o bá kó lọ síjọ tuntun pẹ̀lú ìdílé ẹ, kì í rọrùn kára èèyàn tó lè mọlé, kì í sì í rọrùn láti jẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín ìdílé náà àti Jèhófà túbọ̀ lágbára.” Yàtọ̀ sí pé wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ sí í wá iṣẹ́, ilé tí wọ́n máa gbé àti ilé ìwé táwọn ọmọ wọn á máa lọ, ohun míì tó lè mú kí nǹkan nira ni ojú ọjọ́ tí ò bára dé, àṣà ìbílẹ̀ tó yàtọ̀ sí tiwọn àti ìpínlẹ̀ ìwàásù tuntun.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Nicolas àti Céline ní tiwọn yàtọ̀. Ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Faransé gbéṣẹ́ kan fún wọn, wọ́n gbà láti ṣe é, ìyẹn sì máa gba pé kí wọ́n kó lọ sí ìjọ míì. Wọ́n sọ pé: “Inú wa dùn nígbà tá a gbaṣẹ́ yẹn, àmọ́ lẹ́yìn tá a kó lọ sí ìjọ tuntun, àárò àwọn ọ̀rẹ́ wa bẹ̀rẹ̀ sí í sọ wá, a ò sì tíì fi bẹ́ẹ̀ mọwọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa níjọ tuntun yẹn.” a Àwọn nǹkan tá a ti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ yìí ò rọrùn, torí náà báwo lo ṣe lè ṣàṣeyọrí tó o bá kó lọ sí ìjọ míì? Báwo làwọn ará ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́? Báwo lo ṣe lè gbé àwọn ará ró níjọ tuntun tó o wà, kíwọ náà sì rí ìṣírí gbà?

ÌLÀNÀ MẸ́RIN TÓ MÁA RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́ KÁRA Ẹ LÈ MỌLÉ

Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà

1. Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Sm. 37:5) Arábìnrin Kazumi tó ń gbé orílẹ̀-èdè Japan fi ìjọ tó ti wà láti ogún (20) ọdún sílẹ̀ nígbà tí iṣẹ́ gbé ọkọ ẹ̀ lọ sí ibòmíì. Báwo ló ṣe “fi ọ̀nà [ẹ̀] lé Jèhófà lọ́wọ́”? Ó sọ pé: “Mo sọ fún Jèhófà nípa àwọn nǹkan tó ń bà mí lẹ́rù, tó ń jẹ́ kí n máa rò pé mo dá nìkan wà àtàwọn nǹkan tó ń kó mi lọ́kàn sókè. Gbogbo ìgbà tí mo bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà máa ń fún mi lókun.”

Báwo lo ṣe lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? Bí ewéko ṣe nílò omi àtàwọn èròjà míì látinú ilẹ̀ kó lè dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára. Nicolas tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan rí i pé nígbà tóun ṣàṣàrò nípa bí Ábúráhámù, Jésù àti Pọ́ọ̀lù ṣe yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ó jẹ́ kóun túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Torí náà, tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, á jẹ́ kó o lè máa fara da àyípadà tó bá wáyé nígbèésí ayé ẹ, á sì tún jẹ́ kó o lè fi àwọn nǹkan tó o ti kọ́ ran àwọn ará lọ́wọ́ nínú ìjọ tuntun tó o wà.

Má fi ìjọ tuntun wé ti tẹ́lẹ̀

2. Má fi ìjọ tuntun wé ti tẹ́lẹ̀. (Oníw. 7:10) Nígbà tí Jules fi orílẹ̀-èdè Benin sílẹ̀ lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó rí i pé àṣà ìbílẹ̀ òun yàtọ̀ pátápátá sí tibẹ̀. Ó sọ pé: “Ó máa ń ṣe mí bíi pé tí mo bá ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdé ẹnì kan kí n sọ àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi fún un.” Torí pé bí nǹkan ṣe rí níbi tó wà báyìí yàtọ̀ sí bó ṣe rí níbi tó ti wá, ó bèrẹ̀ sí i yẹra fáwọn ará ìjọ. Àmọ́ nígbà tó sún mọ́ àwọn ará dáadáa, wọ́n wá mọwọ́ ara wọn, ìyẹn sì jẹ́ kára tù ú. Ó wá sọ pé: “Mo gbà pé ibi yòówù ká wà láyé, ọ̀kan náà ni gbogbo wa. Ó kàn jẹ́ pé bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ àti bá a ṣe ń ṣe nǹkan ló yàtọ̀ síra. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká gba àwọn èèyàn bí wọ́n bá ṣe rí.” Torí náà, má fi àwọn ará ìjọ tuntun tó o wà wé ìjọ ti tẹ́lẹ̀. Nígbà tí arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Anne-Lise ń sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí, ó ní: “Ìdí tí mo fi kó lọ sí ibòmíì ni pé mo fẹ́ mọ àwọn nǹkan tuntun, kì í ṣe torí kí n lè ní àwọn nǹkan tí mo ti fi sílẹ̀ níbi tí mo wà tẹ́lẹ̀.”

Kò yẹ káwọn alàgbà máa fi ìjọ tuntun tí wọ́n wà wé ìjọ ti tẹ́lẹ̀. Táwọn ará ìjọ tuntun tó o wà bá ń ṣe nǹkan lọ́nà tó yàtọ̀ sí ti ìjọ tó o wà tẹ́lẹ̀, ìyẹn ò sọ pé ohun tí wọ́n ń ṣe ò tọ́. Ó máa bọ́gbọ́n mu kó o mọ bí nǹkan ṣe rí ní agbègbè tuntun yẹn kó o tó dábàá pé kí wọ́n yí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe nǹkan pa dà. (Oníw. 3:1, 7b) Torí náà, á dáa kó o fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ará ìjọ yẹn dípò kó o máa fipá mú wọn láti ṣe ohun tó o fẹ́.—2 Kọ́r. 1:24.

Máa bá àwọn ará ìjọ ṣe nǹkan pọ̀

3. Máa bá àwọn ará ìjọ ṣe nǹkan pọ̀. (Fílí. 1:27) Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni kéèyàn kó lati ibì kan lọ síbòmíì, ó sì máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò, àmọ́ ó ṣe pàtàkì kó o máa lọ sípàdé lójúkojú ní gbàrà tó o bá ti débẹ̀. Táwọn ará ìjọ tuntun tó o wà ò bá mọ̀ ẹ́ tàbí tí wọn kì í rí ẹ déédéé, báwo ni wọ́n ṣe fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́? Arábìnrin Lucinda tóun àtàwọn ọmọbìnrin ẹ̀ méjì kó lọ sí ìlù ńlá kan lórílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ mi gbà mí nímọ̀ràn pé kí n sún mọ́ àwọn ará ìjọ tuntun tí mo wà dáadáa, ká jọ máa wàásù déédéé, kí n sì máa dáhùn nípàdé. Yàtọ̀ síyẹn, a tún yọ̀ǹda ilé wa káwọn ará ìjọ lè máa ṣèpàdé ìṣẹ́ ìwàásù níbẹ̀.”

Tí ìwọ àtàwọn ará inú ìjọ tuntun tó o wà bá “jọ ń sapá” lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ẹ̀ẹ́ túbọ̀ ní “ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere.” Àwọn alàgbà ìjọ Arábìnrin Anne-Lise tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan gbà á nímọ̀ràn pé kó máa bá àwọn ará ṣiṣẹ́ lọ́kọ̀ọ̀kan nígbà tí wọ́n bá ń wàásù. Àǹfààní wo ló rí? Ó sọ pé: “Mo wá rí i pé ọ̀nà tó dáa jù nìyẹn láti tètè jẹ́ kí ara mi mọlé.” Bákan náà, tó o bá ń yọ̀ǹda ara ẹ láti máa ṣe ìmọ́tótó tàbí ṣàtúnṣe Ilé Ìpàdé ní ìjọ tuntun tó o wà, àwọn ará máa mọ̀ pé ara ti mọlé níjọ yẹn. Tó o bá tètè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan yìí pẹ̀lú àwọn ará ìjọ ẹ, kò ní pẹ́ tí ẹ̀ẹ́ fi mọwọ́ ara yín, ọkàn ẹ á sì balẹ̀ nínú ìjọ.

Ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun

4. Ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun. (2 Kọ́r. 6:11-13) Tó o bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, á rọrùn fún ẹ láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun. Bó o ṣe lè ṣe é ni pé kó o máa tètè dé sípàdé, má sì tètè kúrò kó o lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ kó o sì túbọ̀ mọ̀ wọ́n. Sapá gan-an kó o lè mọ orúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Tó o bá ń rántí orúkọ àwọn èèyàn, tára ẹ sì yá mọ́ọ̀yàn, àwọn èèyàn á sún mọ́ ẹ, wàá sì láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà.

Dípò kó o máa díbọ́n káwọn ará lè gba tìẹ, ńṣe ni kó o jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an. Ìwọ náà lè ṣe ohun tí Lucinda ṣe, ó ní: “A ti láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà báyìí torí a máa ń pe àwọn ará wá sílé wa.”

“Ẹ TẸ́WỌ́ GBA ARA YÍN”

Ẹ̀rù máa ń ba àwọn kan tí wọ́n bá wọnú Ilé Ìpàdé wa tí wọn ò sì mọ ẹnì kankan rí. Torí náà, kí la lè ṣe kára lè tu àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí ìjọ wa? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé: “Ẹ tẹ́wọ́ gba ara yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ṣe tẹ́wọ́ gbà yín.” (Róòmù 15:7) Táwọn alàgbà bá ń fara wé Kristi, wọ́n á ran àwọn ará tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé síjọ lọ́wọ́ kára wọn lè mọlé. (Wo àpótí náà “ Ohun Tó Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí Tó O Bá Ń Kó Lọ Síjọ Tuntun.”) Àmọ́ o, gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ, títí kan àwọn ọmọdé ló yẹ kó ṣe ipa tiwọn láti mára tu àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sínú ìjọ.

Ara ohun tó fi hàn pé a tẹ́wọ́ gba àwọn ará ni pé ká máa pè wọ́n wá sílé wa, àmọ́ a tún lè ṣe àwọn nǹkan míì láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan wáyè láti mú arábìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé síjọ káàkiri ìlú, ó sì ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ń wọkọ̀ fún un. Ohun tí arábìnrin yẹn ṣe wú arábìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lórí gan-an, ó sì jẹ́ kára ẹ̀ mọlé.

ÌJỌ TUNTUN MÁA JẸ́ KÓ O TẸ̀ SÍWÁJÚ

Bí eéṣú kan bá ṣe ń dàgbà, ó máa ń bọ́ awọ ara ẹ̀ sílẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà kó tó lè fò. Lọ́nà kan náà, tó o bá kó lọ sí ìjọ tuntun, rí i pé ó borí àwọn ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù, kó o lè máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ẹ gbọ́ ohun tí Nicolas àti Céline sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ní: “Ẹ̀kọ́ ńlá lèèyàn máa ń kọ́ tó bá kó lọ síbòmíì. Bá a ṣe ń ṣe nǹkan pẹ̀lú àwọn ará, bẹ́ẹ̀ la túbọ̀ ń mọwọ́ ara wa tára wa sì ń mọlé, ìyẹn jẹ́ ká láwọn ànímọ́ tá ò ní tẹ́lẹ̀.” Jean-Charles tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ sọ àǹfààní tí ìdílé ẹ̀ rí, ó ní: “Ìjọ tuntun tá a kó lọ ti jẹ́ kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ nínú àwọn ọmọ wa, wọ́n sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀ tá a débẹ̀, omọbìnrin wa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ nípàdé àárín ọ̀sẹ̀, ọmọkùnrin wa sì di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.”

Tí ò bá rọrùn fún ẹ láti kó lọ síjọ tí wọ́n ti nílò ìrànlọ́wọ́ ńkọ́, kí lo lè ṣe? O ò ṣe fi àwọn àbá tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí sílò nínú ìjọ tó o wà báyìí? Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, máa bá àwọn ará ṣiṣẹ́ lọ́kọ̀ọ̀kan nígbà tẹ́ ẹ bá ń wàásù, máa láwọn ọ̀rẹ́ tuntun, kó o sì jẹ́ kí àárín ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ tó o ní tẹ́lẹ̀ túbọ̀ gún. Ṣé o lè lọ kí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé síjọ yín tàbí kó o kíyè sí àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́, kó o lè mọ bó o ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́? Ó ṣe tán, ìfẹ́ la fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀, torí náà tó o bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará, wàá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Jòh. 13:35) Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ó dájú pé “inú Ọlọ́run máa ń dùn gan-an sí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀.”—Héb. 13:16.

Òótọ́ ni pé kò rọrùn fáwọn ará wa kan nígbà tí wọ́n kó lọ síjọ míì, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ lára wọn ló ṣàṣeyọrí. Ìwọ náà lè ṣàṣeyọrí! Arábìnrin Anne-Lise sọ pé: “Bí mo ṣe kó lọ síjọ míì jẹ́ kí n láwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀ sí i.” Arábìnrin Kazumi ti wá gbà báyìí pé tó o bá kó lọ síjọ míì, “wàá rí i pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lọ́nà tó ò lérò.” Arákùnrin Jules ní tiẹ̀ sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ tuntun tí mo ní báyìí ti jẹ́ kára mi mọlé. Èmi àtàwọn ará ìjọ tuntun tí mo wà báyìí ti wá mọwọ́ ara wa débi pé kò ní rọrùn fún mi láti fibẹ̀ sílẹ̀.”

a Kó o lè mọ ohun tó o máa ṣe tí àárò ilé bá ń sọ ẹ́, wo àpilẹ̀kọ náà “Kíkojú Àárò Ilé Lẹ́nu Iṣẹ́-Ìsìn Ọlọrun” nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 1994.