Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ | ÌṢẸ́ ÀTI ÒṢÌ

Ipò ÒṢÌ

Ipò ÒṢÌ

Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló ṣì ń kojú ìṣòro àìríná-àìrílò láìka ìsapá táwọn kan ń ṣe láti yanjú ìṣòro yìí.

Báwo ni àwọn òtòṣì ṣe lè láyọ̀?

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé kí ẹnì kan tó lè láyọ̀ káyé rẹ̀ sì dùn, ó gbọ́dọ̀ rí towó ṣe. Wọ́n tún rò pé ẹni tó bá lówó lọ́wọ́ ló rí ayé wá. Wọ́n gbà pé àwọn mẹ̀kúnnù kò lè láyọ̀, torí pé wọn ò lè lọ ilé ìwé gidi, wọn ò lè rówó tọ́jú ara wọn, wọn ò sì lè gbé nǹkan gidi ṣe láyé wọn.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì kọ́ wa pé kì í ṣe bí ẹnì kan ṣe lówó tó ló ń pinnu bí ayọ̀ rẹ̀ ṣe máa pọ̀ tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sinmi lórí àjọṣe tí ẹni náà ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Láìka ipò téèyàn wà, àwọn tó bá ń ronú nípa àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run máa ń fẹ́ mọ èrò Ọlọ́run lórí nǹkan tí wọ́n bá fẹ́ ṣe, èyí sì máa ń mú kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òtítọ́ inú Bíbélì tó ń fúnni ní ìtùnú àti ìfọ̀kànbalẹ̀. Ohun tó ń fúnni láyọ̀ tó dénú gan-an nìyẹn.

Àwọn tó bá ń fi ohun tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì sílò máa mọ bí wọ́n ṣe lè kojú ìṣòro àìríná-àìrílò. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé ká yẹra fún àwọn àṣàkaṣà bí àmujù ọtí àti mímu sìgá. Àwọn àṣà yìí máa ń mú kéèyàn fowó ṣòfò, ó sì lè fa àwọn àìsàn táá máa gbọ́nni lówó lọ.—Òwe 20:1; 2 Kọ́ríńtì 7:1.

Bíbélì tún kì wá nílọ̀ pé ká má ṣe jẹ́ oníwọra àti olójúkòkòrò. (Máàkù 4:19; Éfésù 5:3) Irú àwọn ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń mú kéèyàn yẹra fún àwọn àṣà tó ń fa ìfowóṣòfò bíi tẹ́tẹ́ títa, kì í sì jẹ́ kéèyàn di ‘olùfẹ́ owó.’ Bíbélì sì sọ pé ìfẹ́ owó ni “gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo.” (1 Tímótì 6:10) Ìwé Mímọ́ kìlọ̀ pé: “Tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Kókó ibẹ̀ ni pé, kò sí bí owó ṣe pọ̀ tó, kò lè ra ẹ̀mí. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn tó bá ń fi àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì sílò máa gbádùn ìgbésí ayé wọn, wọ́n sì máa ní ayọ̀ tó dénú.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mẹ̀kúnnù ní láti sapá gan-an kí wọ́n tó lè rí oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé, síbẹ̀ wọ́n lè láyọ̀ tí wọ́n bá kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn, tí wọ́n sì gbájú mọ́ bí wọ́n ṣe máa múnú Ẹlẹ́dàá wọn dùn. Wọ́n gbà pé òótọ́ ni ìlérí Bíbélì tó sọ pé “ìbùkún Jèhófà, èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”—Òwe 10:22.

FI ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ YÌÍ SỌ́KÀN: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”Mátíù 5:3.

Ṣé ìṣẹ́ àti òṣì máa dópin?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ìsapá àwọn èèyàn láti fòpin sí ìṣòro yìí ti já sí pàbó. Àmọ́ tó bá tó àkókò, Ọlọ́run máa ṣàtúnṣe sí ohun tó fa ìṣòro yìí, ìyẹn ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan àwọn èèyàn àti ìjọba jẹgúdújẹrá tó jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀. (Oníwàásù 8:9) Ẹlẹ́dàá wa máa fi Ìjọba tirẹ̀ rọ́pò ìjọba jẹgúdújẹrá táwọn èèyàn ń ṣe. Ìjọba Ọlọ́run máa wá pèsè gbogbo nǹkan tí àwa èèyàn nílò láìsí ojúsàájú. Bíbélì sọ ní kedere pé Alákòóso Ìjọba Ọlọ́run máa fojú àánú hàn sí àwọn òtòṣì. Ó ní: “Nítorí tí òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè . . . Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.”—Sáàmù 72:12-14.

Ayé á di Párádísè, ilé àti oúnjẹ máa wà lọ́pọ̀ yanturu, àìríná-àìrílò á sì di ohun ìgbàgbé. Nínú ìwé Aísáyà, Ọlọ́run ṣèlérí pé àwọn èèyàn òun máa ‘kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.’ (Aísáyà 65: 21, 22) Dípò tí àá fi máa làkàkà ká tó jẹun, gbogbo èèyàn máa gbádùn “àkànṣe àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ tí a fi òróró dùn” àti àwọn nǹkan rere míì tí Jèhófà máa pèsè.—Aísáyà 25:6.

KÍ NÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ?

Ríronú nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa fòpin sí àìríná-àìrílò máa ń fọkàn àwọn òtòṣì balẹ̀. Ó sì máa ń mú un dá wọn lójú pé Ọlọ́run ò gbà gbé wọn àti pé gbogbo làálàá wọn máa dópin láìpẹ́. Fífi ìlérí yìí sọ́kàn lè fún èèyàn lókun láti fara da ìṣẹ́ àti òṣì nísinsìnyí.

FI ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ YÌÍ SỌ́KÀN: “Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè . . . Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.” Sáàmù 72:12, 13.