Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Apá òsì: Àwọn ará ní Stuttgart, Jámánì ń kí arábìnrin kan láti Ukraine káàbọ̀. Apá ọ̀tún lókè: Àwọn ará ní Poland ń ran àwọn ará ní Ukraine lọ́wọ́. Ìsàlẹ̀ lápá ọ̀tún: Àwọn ilé tí Bọ́ǹbù ti bà jẹ́

MARCH 16, 2022
UKRAINE

ÌRÒYÌN#3 | Àwọn Ará Ń Fìfẹ́ Hàn Síra Wọn Láìka Ogun Tí Wọ́n Ń Jà ní Ukraine Sí

ÌRÒYÌN#3 | Àwọn Ará Ń Fìfẹ́ Hàn Síra Wọn Láìka Ogun Tí Wọ́n Ń Jà ní Ukraine Sí

Ó dùn wá gan-an láti sọ fún yín pé àwọn arábìnrin wa méjì ló kú nígbà tí wọ́n ju bọ́ǹbù sí ìlú Mariupol. Títí di báyìí, ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) lára àwọn ará wa ni ò ṣeé ṣe fún láti sá kúrò nílùú torí bí ìjà náà ṣe lágbára tó. Láwọn ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn, nǹkan bí àádọ́jọ (150) lára àwọn ará wa ló ráyè sá kúrò nílùú náà. Àwọn ará tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù gbìyànjú láti kó ohun táwọn ará nílò wá sí ìlú Mariupol, ṣùgbọ́n ṣe ni wọ́n gbéjà kò àwọn àtàwọn àjọ míì tí wọ́n jọ ń bọ̀, èyí sì mú kí wọ́n pa dà. Bọ́ǹbù kan bú gbàù nínú ọgbà kan tí Gbọ̀ngàn Ìjọ̀ba àti Gbọ̀gàn Àpéjọ wà. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì (200) lára àwọn ará wa ló sì fara pa mọ́ sínú àjà ilẹ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà lásìkò yẹn. A dúpẹ́ pé kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó ṣèṣe, ṣùgbọ́n ọkọ̀ wọ́n bà jẹ́, ìyẹn sì mú kó túbọ̀ ṣòro láti sá kúrò nílùú náà.

Alàgbà kan (tí àwòrán ẹ̀ wà nísàlẹ̀) tóun àti ìdílé ẹ̀ ráyè sá kúrò nílùú Mariupol sọ pé: “A pàdánù ilé àti iṣẹ́ wa, a ò sì rí àwọn ọ̀rẹ́ wa pè. Ọjọ́ mẹ́fà gbáko la fi rin ìrìn àjò tó yẹ ká fọjọ́ kan péré rìn. Bá a ṣe ń wakọ̀ jádé nínú ìlú, à ń rí bí èéfín ṣe ń rú jáde látinú àwọn bọ́ǹbù tí ò tíì bú gbàù lójú ọ̀nà. Ní gbogbo ìgbà tá a fi rin ìrìn àjò yìí, àwọn ará ló ń fún wa lóúnjẹ, wọ́n sì ń ṣètò ibi tá a máa sùn. Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé Jèhófà Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì ń bójú tó wa . . . Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí ti jẹ́ ká pinnu pé, bíná ń jó bí ìjì ń jà, Jèhófà la máa gbẹ́kẹ̀ lé.”

Apá òsì: Tọkọtaya kan tó sá kúrò ní Mariupol. Apá ọ̀tún: Apá kan lára àjà ilẹ̀ ilé wọn tí wọ́n fara pa mọ́ sí fún ọjọ́ mẹ́jọ

Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ti sá kúrò lórílẹ̀-èdè Ukraine lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè míì nílẹ̀ Yúróòpù. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ìyàwó ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún méje (7), mọ́kànlá (11) àti mẹ́rìndínlógún (16) rin ìrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè Portugal níbi tí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé. Wákàtí mọ́kànlá ni wọ́n fi dúró ní ẹnubodè kí wọ́n tó lè sọdá, lẹ́yìn náà, wọ́n rin ìrìn àjò ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) kìlómítà fún ọjọ́ mẹ́rin kí wọ́n tó dé ibi tí wọ́n ń lọ. Ó kù díẹ̀ kí ìpàdé bẹ̀rẹ̀ ni wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò gbọ́ èdè Potogí, wọ́n dara pọ̀ mọ́ ìpàdé náà. Nígbà tí àwọn ará ìjọ yẹn rí bí inú ìdílé yìí ṣe ń dùn láìka ohun tójú wọn ti rí, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an.

Ìdílé kan tó fi ọjọ́ mẹ́rin rìnrìn àjò ẹgbẹ̀rún mẹ́rin kìlómítà láti Ukraine sí Portugal ń ya fọ́tò lẹ́yìn tí ìpàdé parí

Arábìnrin tí òun àti ìdílé ẹ̀ sá lọ sílẹ̀ Jámánì sọ pé: “Bá a ṣe ń ka Bíbélì, tá à ń ronú lórí àwọn nǹkan tó dáa tó ti ṣẹlẹ̀ sí wà, tá a sì ń ronú lórí ìrètí ọjọ́ iwájú tá a ní, ṣe ni ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. . . . Jèhófà ti lo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láti ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro wa. Wọ́n tẹ́wọ́ gbà wá, wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè Ukraine, ní Hungary, àti ní báyìí nílẹ̀ Jámánì!”

Kò sí àní àní pe Jèhófà ò fi gbogbo àwọn ará wa tó wà ní Ukraine sílẹ̀.​—Sáàmù 145:14.

Títí di March 16, 2022, àwọn ìròyìn tá a gbọ́ láti Ukraine ló wà nísàlẹ̀ yìí. Àwọn arákùnrin tó wà ní Ukraine ló fún wa láwọn ìròyìn yìí. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kí iye àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí ju báyìí lọ torí pé kò rọrùn láti mọ bí nǹkan ṣe ń lọ láwọn agbègbè kan lórílẹ̀-èdè náà:

Ìpalára Tó Ti Ṣe Fáwọn Wọn Ará Wá

  • Akéde mẹ́rin ti kú

  • Akede mọ́kàndínlógún (19) ló ti ṣèṣe

  • Akéde tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ́n (29,789) ti sá kúrò nílé wọn lọ síbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu lórílẹ̀-èdè naa

  • Ilé márùndínláàádọ́ta (45) ló ti bà jẹ́ pátápátá

  • Ilé mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (84) ló ti bà jẹ́ gan-an

  • Ilé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti mẹ́rìndínláàádọ́rin (366) ló bà jẹ́ díẹ̀

  • Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́rìndínlógún (16) ló bà jẹ́

Bá A Ṣe Ran Àwọn Ará Wa Lọ́wọ́

  • Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) ni wọ́n ṣètò ní Ukraine

  • Ìgbìmọ̀ yìí ti bá àwọn akéde tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà mọ́kànlélógún (20,981) wá ibi tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu tí wọ́n lè máa gbé

  • Àwọn akéde tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rùn lọ́nà méjìlá (11,973) tó sá lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì ni àwọn ará ràn lọ́wọ́