Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Ibùdókọ̀ ojú irin táwọn èèyàn kún fọ́fọ́ ní Lviv. Ilé arákùnrin kan tí bọ́ǹbù bà ń jó. Àwọn alàgbà ń wá àwọn ará kiri ní Mariupol, èyí sì gba ìgboyà gan-an

APRIL 1, 2022
UKRAINE

ÌRÒYÌN #5 | Àwọn Ará Ń Fìfẹ́ Hàn Síra Wọn Láìka Ogun Tó Ń Jà ní Ukraine Sí

ÌRÒYÌN #5 | Àwọn Ará Ń Fìfẹ́ Hàn Síra Wọn Láìka Ogun Tó Ń Jà ní Ukraine Sí

Títí di March 29, 2022, ó bani nínú jẹ́ pé méje lára àwọn ará wa míì ló tún ti kú ní ìlú Mariupol. Lápapọ̀, àwọn ará wa mẹ́tàdínlógún (17) ló ti kú lórílẹ̀-èdè Ukraine.

Àwọn Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù (ìyẹn DRC) ní Ukraine ń ṣiṣẹ́ gan-an láti pèsè ìrànwọ́, wọ́n sì tún ń fẹ̀mí wọn wewu láti wá àwọn ará láwọn ibi tí ogun ti le.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ nínú ìgbìmọ̀ DRC yìí ń ṣiṣẹ́ kára gan-an láti rí i pé àwọn gbé oúnjẹ, oògùn àtàwọn ohun kòṣeémánìí lọ fún àwọn ará wa láwọn agbègbè tí ogun ti le gan-an bíi Kharkiv, Kramatorsk àti Mariupol. Ọ̀kan lára àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ DRC máa ń rìnrìn àjò tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) kìlómítà lójúmọ́ gba ọ̀pọ̀ ibi tí àwọn ọmọ ogun wà kọjá, kó lè gbé oúnjẹ àti oògùn lọ fáwọn akéde tó tó ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún méje (2,700).

Ìgbìmọ̀ yìí tún ṣètò ọkọ̀ láti kó àwọn ará kúrò láwọn agbègbè tógun ti ń jà. Ọ̀kan lára àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ DRC ní Chernihiv sọ pé: “Nígbà táwọn ọmọ ogun bẹ̀rẹ̀ sí í ju bọ́ǹbù, iná mànàmáná àti Íńtánẹ́ẹ́tì kò ṣiṣẹ mọ́, a wá rí i pé ó léwu gan-an láti dúró sílùú. Torí náà, àwọn alàgbà lọ sọ fáwọn ará tó fara pa mọ́ sí àjà ilẹ̀ pé ọkọ̀ ti wà láti kó wọn kúrò nílùú.”

Ọkùnrin kan tó máa ń fi ọkọ̀ kó èrò gbà láti ràn wá lọ́wọ́. Bó ṣe ń lọ, bẹ́è ló ń bọ̀, kódà ẹ̀ẹ̀mẹsàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló pààrà títí tó fi kó àwọn ará tó lé ní ọgọ́rùn-ún méjì ààbọ̀ (254) kúrò nílùú Chernihiv. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó fi katakata tún ọ̀nà ṣe kí àwọn ọkọ̀ ẹ̀ lè kọjá. Inú àwọn ará dùn gan-an sóhun tọ́kùnrin yẹn ṣe, wọ́n sì dúpẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀.

A bá àwọn táwọn èèyàn wọn kú nínú ogun yìí kẹ́dùn gan-an. Ohun kan tó dájú ni pé, láìpẹ́ ìlérí Ọlọ́run máa ṣẹ pé, kò ní sí ikú àti ọ̀fọ̀ mọ́.​—Ìfihàn 21:​3, 4.

Wọ́n ń kí àwọn ará tí wọ́n tó ogójì (40) káàbọ̀ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ibi tógun ti ń jà ní Chernihiv ni wọ́n ti kó wọn kúrò

Títí di March 29, 2022, àwọn ìròyìn tá a gbọ́ láti Ukraine ló wà nísàlẹ̀ yìí. Ó ṣeé ṣe kí àròpọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ jù àwọn ìsọfúnni tá a rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wa, torí kò rọrùn láti kàn sáwọn ará wa káàkiri orílẹ̀-èdè náà.

Ìpalára Tó Ṣe Fáwọn Ará Wa

  • Akéde mẹ́tàdínlógún (17) ló ti kú

  • Akéde márùndínlógójì (35) ló fara pa

  • Àwọn akéde tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì àti ààbọ̀ (36,313) ló fi ilé wọn sílẹ̀ lọ síbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu lórílẹ̀-èdè náà

  • Ilé mẹ́rìnléláàdọ́fà (114) ló bà jẹ́ pátápátá

  • Ilé mẹ́rìnlélógóje (144) ló bà jẹ́ gan-an

  • Ilé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé méjìlá (612) ló bà jẹ́ díẹ̀

  • Gbọ̀ngàn Ìjọba kan bà jẹ́ pátápátá

  • Gbọ̀ngàn Ìjọba méje bà jẹ́ gan-an

  • Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́tàlélógún (23) ló bà jẹ́ díẹ̀

Bá A Ṣe Ṣètò Ìrànwọ́

  • Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù (DRC) mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) ló wà ní Ukraine

  • Àwọn akéde tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì (34,739) ni àwọn ìgbìmọ̀ DRC wá ilé fún, kí wọ́n lè rí ibi tí wọ́n á máa gbé láìséwu

  • Àwọn ará ń ṣèrànwọ́ fáwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún (16,175) tó sá lọ sórílẹ̀-èdè míì